Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni Màmá wa, Ìyá-Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nsọ pé àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), kò ní kúrò nínú oko ẹrú kan bọ́ sí ómíràn.
Kíni ìtumọ̀ eléyi? Ní àìpẹ́ yí ni wọ́n tún mú ẹnu ba ọ̀rọ̀ náà, èyí tí ó fi di dandan kí á mu wá sí etí-ìgbọ́ I.Y.P ti D.R.Y.
Lọ́nà kíní, kíni Oko-Ẹrú? Nínú gbogbo ohun tí Màmá ti máa mbá wa sọ, a lè sọ pé oko-ẹrú pín sí Ọ̀nà Méjì gbòógì: èkíni ni oko-ẹrú lábẹ́ òyìnbó-amúnisìn.
Ẹ̀yí tí ó jẹ́ pé, àpapọ̀ ṣíṣe ẹrú lábẹ́ òyìnbó àti lábẹ́ olóṣèlú Nàìjíríà, a à ní kúrò lábẹ́ ìyẹn kí a tún lọ gbé’ra wa sọ́wọ́ òyìnbó padà! Ìkan nìyẹn; ìdí nìyẹn tí Màmá fi ntọ ipa ọ̀nà tí Olódùmarè nfi hàn wọ́n, láti ìgbà dé ìgbà, kí ó máṣe di pé nígbàtí a bá wọ inú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìjọba wa tán, òyìnbó kan á wá gba ògo pé ṣebí òun ni òun ràn wá lọ́wọ́ láti ri’ṣe, nítorí-náà ohun tí òun bá ti sọ ni a gbọ́dọ̀ ṣe! Rárá o!
A ò gbọdọ̀ fi àyè kankan sílẹ̀ kí irúfẹ́ èyí kí ó wáyé; tí ìbáá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé, èèwọ̀, ẹni yẹn ti kúrò nínú oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn nìyẹn! Ìdí nìyí tí a fi ní láti máa gbàdúrà fún Màmá pé, àwọn ibi tí Olódùmarè ti fún wọn ní ànfààní láti rìn sí àti láti rí nkan rere gbé ṣe fún ire Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, kí Olódùmarè ó máa ṣọ́ wọn níbẹ̀ láti la ojú wọn sí gbogbo nkan tí ó lè fa ìdíwọ́ sí òmìnira pátápátá.
Gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe sọ, wọ́n ní ó nya àwọn ti’ta lẹ́nu pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Orílẹ̀-Èdè kan máa gba òmìnira láìsí pé àwọn ti’ta náà ni ó ṣì máa máa darí wọn. Ti D.R.Y ni àkọ́kọ́. Ǹkan tí Màmá nsọ nìyẹn o, pé a ò ní kúrò nínú oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn – òmìnira ní òtítọ́ àti ní Òdodo ni òmìnira D.R.Y.
Èkèjì ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà ni pé, a ò ní kúrò nínú oko-ẹrú lábẹ́ Nàìjíríà, kí á tún wá bọ́ sí oko-ẹrú lábẹ́ àwọn olóṣèlú nàìjíríà tí ó jẹ́ pé ọmọ Yorùbá ni wọ́n ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ìwà-ìkónilẹ́rú tí wọ́n nhù ní Nàìjíríà ni wọ́n ṣì máa máa hù; tàbí àwọn tí ó pe ara wọn ní Ọba tí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ni alábọ̀dè fún Ìran Yorùbá; bẹ́ẹ̀ ni a ò ní gbé D.R.Y lé ọwọ́ àwọn tí wọ́n rò pé kò sí bí àwọn kò ṣe jẹ́, tí wọ́n nsọ pé àwọn ni ọ̀mọ̀wé, ‘elite,’ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Oko-ẹrú gbáà ni ó máa jẹ́ tí a bá gba irú ẹ̀mí tiwọn láàyè ní Orílẹ̀-Èdè D.R.Y.
Bẹ́ẹ̀ ni a ò gbọ́dọ̀ fi àyè sílẹ̀ fún àwọn tó jẹ́ pé ẹ̀mí jàgùdà, jàndùkú, ẹrú-ìkú, dàgboro-rú, ni ẹ̀mí tó wà lára wọn! A mọ̀ wọ́n, a sì mọ ìdíwọ́ tí wọ́n ti jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà tí a ti nrìn títí di àsìkò yí.
Ká má ṣe sọ pé ọmọ-Yorùbá ni àwọn náà, ká wá tìtorí ìyẹn fún wọn láàyè láti tẹ̀síwájú nínú ibi wọn. Rárá o.
Àti ọkùnrin àti obìnrin wọn, a ò gbọ́dọ̀ fún wọn ní àyè fún ìwà-burúkú wọn. Ẹni tí kò bá ti lè hu ìwà ọmọlúàbí, kò sí àyè fún irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ní D.R.Y. A ò ní kúrò nínú oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn.