Ní àìpẹ́ yí ni Màmá wa, Iyá Ìran YORÙBÁ , Ìyá Wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tún rán’wa léti pé, a ò gbọdọ̀ gbàgbé oore tí Olódùmarè ṣe fún Ìran wa – nítorí ohun ti ojú wa ti rí kò rú’jú mọ́, ní àkókò yí, pé ìfẹ́ àti ète àwọn ọ̀tá ni pé kí Ìran Yorùbá ó parun, kí a máṣe gbọ́ ohunkóhun tí ó ńjẹ́ Yorùbá mọ́ ní orí-ilẹ̀ ayé! Bí àwọn ọ̀tá tí ó wà ní òkè réré tí nfẹ́ eléyi, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn tí ó wà ní àyíká wa ṣe nfẹ́-ẹ bákan-náà: bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀tá-inú-ilé tí ó ńran àwọn tìta lọ́wọ́ náà wà níbẹ̀!

Ní ìwòyí ọdún méjì sẹ́yìn ni Màmá wa, MOA, sọ fún wa pé kí á tètè máa lọ, kí á tètè bẹ̀rẹ̀ ìṣètò orílẹ̀-èdè wa, àti pé ohun tí ó ńbọ̀ ní ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́talélógún, kìí ṣe ohun tó ṣe-é dúró wò, ṣùgbọ́n tí àwọn ọ̀dàlẹ̀ ọ̀bayéjẹ́ ńṣe lòdì sí ohun tí Màmá wa nsọ nígbà-náà lọ́hun! – àmọ́, gbogbo ohun tí Màmá sọ nígbà-náà lọ́hun mà ti wá sí ìmúṣẹ-ẹ̀! Jùbẹ́ẹ̀ lọ tún ti ṣẹlẹ̀ nínú ọdún tí a wà yí, ṣùgbọ́n Olódùmarè ṣe àánú fún wa, kìí ṣe pé a ṣe ìkéde Òmìnira wa nìkan, ṣùgbọ́n a tún ṣe ÌPOLONGO ÌṢÈTÒ-ARA-ẸNI wa, èyí tí a fi di orílẹ̀-èdè tuntun jùlọ ní Àgbáyé tí ó jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Aṣètò-Ara-Ẹni, ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí! Àṣeyọrí ńlá ni eléyi jẹ́-ẹ̀! Wípé àwa tí wọ́n ti dá’ná bí wọ́n ṣe máa sun wá jẹ, ni a ti di olómìnira báyi,.

tí a tún ti bẹ̀rẹ̀ ìṣètò ti wá! Ewu ńlá ni Olódùmarè mà kó wa yọ kúrò nínú rẹ̀ yíì! Màmá ní kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè títí ayé! Eléyi kò sì gbọdọ̀ dúró lọ́dọ̀ tiwa nìkan! Wọ́n ní kí á fi kọ́ àwọn ọmọ wa, kí àwọn náà fi kọ́ àwọn ọmọ tiwọn, títí òpin ìgbà, kí a sọ fún wọn oore tí Olódùmarè ṣe fún Ìran Yorùbá, ní gbígbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn kìnìún tí ó fẹ́ pa ìran wa run; tí Olódùmarè wá yọ wá kúrò nínú òkùnkùn ibi tí wọ́n pè ní Orílẹ̀-Èdè ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ àtọwọ́dá àwọn amúnisìn! Háà! ọpẹ́ ńlá mà ni ó yẹ kí á máa fún Olódùmarè títí ayé-è. 

Ẹ wá jẹ́ kí á sọ òtítọ́ fún ara wa o! Ohun tí ó ńṣẹlẹ̀ yí, Ìgbàlà ìran Yorùbá tí a ńrí yí, kìí ṣe ohun tí ó wáyé lásán! Olódùmarè fún’Ra Rẹ̀ ni ó ṣe Ìgbàlà yí fún wa! Òun ni Màmá ṣe máa ńsọ pé, Àánú ni a rí gbà! nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á gbọ́ràn sí ohun tí wọ́n sọ fún wa, pé, Títí láí, kí á fi yé àrọ́mọ-d’ọmọ wa ohun tí Ọlọ́run ṣe fún àwa Ìran Yorùbá, kí á sì tìtorí èyí máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè, kí á máa yìn-Í, kí á máa sìn-Í, kí á máa fi ògo fún Olódùmarè, kí á sì páyà Ẹlẹ́da wa; wọ́n ní kí a máṣe gbàgbé Oore Ìgbàlà, Ìdándè àti Ìtúsílẹ̀ tí Olódùmarè ṣe fún’wa yí.