Yorùbá jẹ́ Ẹ̀yà àti Ìran tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ iyì àti ẹ̀yẹ nínú ìṣẹ̀dá wọn. Èyí ni ó fi jẹ́ wípé, ní ibi gbogbo àti ní ìgbàkúgbà, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ wípé ní gbogbo àgbáyé ni a ti dá ìran Yorùbá mọ̀ gẹ́gẹ́bí ìran t’ó wu’yì l’ọpọ̀l’ọpọ̀!
Ọmọ Yorùbá ṣe oge dé’bi wípé àt’ọkùnrin àt’obìnrin ọmọ Yorùbá ni ó jẹ́ wípé, kí wọn t’ó já’de lọ kúrò nínú ilé, àyègbè ìwo’jú ti dá’ràn l’ọwọ́ k’á wo ‘ra ẹni k’á tún t’unwò, l’átàri wípé kí ìdúró wa kí ó lè gba’yì, kí ó wu’yì; kí inú wa kí ó dùn sí ara wa; ìgbàyí, pàápàá, ni a gbà wípé ẹ̀dá wa pàápàá ndun’nú sí wa.
Oríṣiríṣi aṣọ tí ó wu’yì ni a máa nwọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọn, l’oní, a fẹ́ sọ nípa aṣọ òkè wa.
Aṣọ òkè jẹ́ aṣọ tí ó wu’yì l’ọpọ̀l’ọpọ̀. Oríṣiríṣi aṣọ òkè ni a máa nwọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Aṣọ òkè gan-an ni èyí tí ó ní gbajúgbajà iyì l’ara ọmọ Yorùbá.
Ka Ìròyìn: Ẹrù ìjọ̀gbọ̀n ni ó nwọ’lé sí Ìlẹ̀ Yorùbá yío, Ẹ ṣọ́’ra Ka Ìròyìn: Ọmọ Yorùbá, Ẹ Ṣọ́’ra! àwọn ọmọ Ígbò ntú ní ọ̀pọ̀ yanturu wa sí ìlú Èkó |
Aṣọ Òkè pín sí ọ̀nà mẹ́ta gbòógì; bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé oríṣiríṣi ni àwọn àkópapọ̀ tí a lè ṣe pẹ̀lú wọn.
Oríṣi aṣọ òkè mẹ́ta yi ni: Àlàárì; Sányán; àti aṣọ Ẹtù.
Àlàárì ni èyítí a lè pe àwọ̀ rẹ̀ ní pupa, bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé kìí ṣe pupa bí ẹ̀jẹ̀. Bákannáà, Sányán ni a le pè ní “funfun” bí ó ti’lẹ̀ jẹ́ wípé kìí ṣe funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹtù jẹ́ dúdú, bí kò ti’lẹ̀ dà bí dúdú ti èédú!
Ẹtù yí jẹ́ aṣọ okè tí ó gba’yì l’ọpọ̀l’ọpọ̀. Ó jẹ́ aṣọ tí ó jẹ́ wípé, tí a bá wọ̀ọ́ s’ọrun, ti a sì fi fìlà ẹtù tí ó dára náà pẹ̀lú rẹ̀, àti bàtà tí ó gba’yì, ó máa nfún ni ní ìdúró ẹni tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àti amòye tí ó jin’lẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá. Irúfẹ́ iyì tí ó máa mbù lé’ni á jẹ́ kí àwọn ènìyàn wò wá gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó mọ iyì ara rẹ̀, tí kò sì fẹ́ ìdọ̀tí.
Aṣọ Sányán ní tirẹ̀ jẹ́ aṣọ òkè tí ènìyàn le wọ̀ l’ati lọ ṣe àwọn ayẹyẹ tí ó jẹ́ wípé ìba díẹ̀ ni ayẹyẹ tí a fẹ́ ṣe ọ̀ún, ṣùgbọ́n tí ó sì pàpà ṣe dandan wípé k’á kó’pa nínú ayẹyẹ ọ̀ún bákannáà.
A lè fi yẹ́ ẹni tí ó bá pè wá sí ayẹyẹ, kí á fi yẹ sí, nípa wíwọ sányán lọ sí’bẹ̀. Àti ọkùnrin àti obìnrin ni ó máa nwọ aṣọ òkè wọ̀nyí, ó sì wu’yì l’ara obìnrin l’ọpọ̀l’ọpọ̀.
Àlàárì ni olóri aṣọ ní ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ilẹ̀ Yorùbá. Àríyá tí ó bá kàn wá gbọ̀ngbọ̀n, tí ó sì jẹ́ wípé pẹ̀lú ọ̀pọ̀l’ọpọ̀ ọpẹ́ àti ìdùnnú ni a fi nṣe àríyá yi; aṣọ àlàárì sábà máa ngba’yì ní’rúfẹ́ àwùjọ bẹ́ẹ̀.
Èdùmàrè, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọmọ Yorùbá ó ní àròjin’lẹ̀ l’ati mọ̀ wípé ẹni iyì àti ẹ̀yẹ ni Olódùmarè dá ọmọ Yorùbá.