Arákùnrin òyìnbó kan tó njẹ Sinato Richards ti tú àṣírí àwọn olórí ìjọba àti àwọn àgbààgbà Áfríkà gégébí ìka, olè àti akótilétà ènìyàn. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Áfríkà ńsọ kiri lórí ẹ̀rọ ayélujára Tik-tok pé àwọn ará Yúrópù ló ńjí àwọn ohun àmúsọrọ ilẹ̀ Afrika lọ sí ọ̀dọ̀ wọn.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XÓ gbà bẹ́ẹ̀ pé lóòtọ́ nígbàkan rí, àwọn ará Yúrópù ńkó ohun àmúsọrọ Áfríkà láti lọ fi tún ìlú tiwọn ṣe, àti pé àwọn ohun àmúsọrọ náà ṣì pọ̀ ní Áfríkà, ṣùgbọ́n báyìí àwọn aṣíwájú orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ní Áfríkà ní akótilétà tó ńta ọrọ̀ àjọni wà fún àwọn òyìnbó náà tí wọn ń jí àwọn owó náà sí òkè òkun. Ó’ wá sọ pé àwọn gbajumọ Afrika ni olè tí njà awọn mẹ̀kúnnù lólè.
Ó tẹ̀síwájú pé, kí lódé tí Afrika kò fí ohun ìní wọn ṣe ohun tí wọ́n nílò, kíló fàá ti Kenya fi gbé iṣẹ́ kànga omi Ìgbàlódé rẹ̀ fún Mister Beast láti ṣe? Kenya lè ṣe iṣẹ́ yẹn, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti ṣé ni, Naijiria jẹ́ ìlú tí ó tóbi jù ní Áfríkà pẹlú okòólélúgba mílíọ̀nù ènìyàn, síbẹ̀ tí kò lè pèsè iná tí ó tó ìdámẹ́wa tí ìlú tí ènìyàn kò jù mílíọ̀nù mẹwa lọ. Ó fikun pé a mọ pé ẹ fẹ́ ìlọsíwájú, ṣugbọn ṣé àwa ará Yúrópù ló máa ṣeé fún yín?
Sínátọ̀ náà tẹ̀síwíjú pé àwọn tí àwọn jẹ ará Yúrópù náà níláti múra sílẹ fún ìdàgbàsókè àwọn Afrika nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ninu agbára láti jagun, nítorí náà ó ní wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí wo ọjọ́ iwájú, kí àwọn sì máa ronú sílẹ̀ bí Yúrópù yíò ṣe ṣẹ́gun Afrika tí ogun bá sẹlẹ̀, o ní àwọn mọ pé ogun máa ṣẹlẹ láàrín Afrika àti Yúrópù.
Àwọn àṣírí báyi tí màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ti mọ̀ ṣíwájú fihàn pé a níláti dúró ṣinṣin tí òmìnira wa ati awọn Adelé wa láti dẹ́kun ìwà yìí.
Ilẹ̀ Yoruba ló ńpàdánù nínú èyí tí àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí Naijiria ń jí, torí àwọn ohun àlùmọ́nì wa ló pọ̀jù nínú gbogbo ohun tí wọ́n ńjí tà, ìdí rèé tí àwon àgbà ìka ati àwọn ẹlẹrìí yíì kò fẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ìní wa. Ìyà náà dẹ̀ pọ̀ púpọ̀ lórí àwa ọmọ aládé.
Gêgẹ́bí arakunrin tó pín fọ̀nrán yen ti sọ́, a kò gbọdọ̀ dúró wòran mọ́, á ní láti gba ara wa tán lọ́wọ́ àwọn àgbà ìyá, àwọn gbajúmọ̀ elẹ́tẹ́ àti àwọn olórí búburú yìí tí wọ́n fẹ́ jẹ wá mọ́ ayé. Ẹnití ó bá dákẹ́ tí ara rẹ̀ á bá dákẹ́, ayanmọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ á sì kú pátápátá láìsí àtúnṣe
Ọmọ Yorùbá I.Y.P tí D.R.Y. àkókò ti tóò láti gba ara wa pátápátá lọ́wọ́ àwọn òyìnbó amúnisìn àti àwọn àgbàgbà ti wọ́n ún ba ilẹ̀ Yorùbá jẹ́, àkókò wa rèé, Ẹ Dìde.