Nínú fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti gbọ́ nípa bí àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe nlo àwọn Lárúbáwá láti wá kó góòlù ní ilẹ̀ Áfríkà, wọ́n ṣe àlàyé l’ẹ́kùnrẹ́rẹ́ nínú fọ́nrán náà wípé, àwọn ènìyàn máa ń wo ìlú Dubai ní ìlẹ̀ Lárúbáwá gẹ́gẹ́ bí ìlú tó ní góòlù jù lọ, ṣùgbọ́n irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni èyí nítorí ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ti wá ń jí góòlù ọ̀hún èyí tí àwọn aláwọ̀ funfun sì jẹ́ onígbọ̀wọ́ wọn.
A gbọ́ pé ní ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, góòlù tó lé ní irínwó àti márùndínlógójì tọ́ọ̀nù ni wọ́n kó jáde láti ilẹ̀ Áfríkà lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, èyí tí ó túmọ̀ sí pé tọ́ọ̀nù góòlù kan ní ọjọ́ kan ṣoṣo.
Kò wá mọ ní àwọn Lárúbáwá nìkan, nítorí pé wọ́n ní àtìlẹyìn àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun náà. Tí wọ́n bá ti wa àwọn góòlù yí tán ní ilẹ̀ Áfríkà, wọ́n ti ní àwọn ibùdó tí wọ́n ti máa ń fọ̀ọ́ tí wọ́n sì ti gbé ọ̀pá gba inú ilẹ̀ láti Áfríkà lọ sí Dubai ní ilẹ̀ Lárúbáwá níbẹ̀ ni wọn yíò ti máa fa góòlù tí wọ́n ti fọ̀ wọlé sí ọ̀dọ̀ wọn, èyí yíò mú kí wọ́n má leè san owó orí, láti ibẹ̀ ni wọn yíò ti ko lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláwọ̀ funfun.
Ẹ wo bí àwọn amúnisìn wọ̀nyí ṣe ń lo agbára lé wa lórí, tí wọ́n sì ń fi ìyà jẹ wá ní Áfríkà, pẹ̀lú gbogbo oríṣiríṣi àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè fi fún wa, ṣùgbọ́n wọ́n ń lo agbára lé wa lórí, nítorí pé wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn ní alákòóso ayé.
Àkókò nìyí fún wa láti jí lójú oorun wa, kí a sì gbé ìgbésẹ̀ akin láti já ara wa gbà lọ́wọ́ àwọn amúnisìn yí, kí a sì lè máa ṣe àkóso àwọn ohun tí Olódùmarè fún wa fún ara wa, kí àwa náà lè ma gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn, kí a má ṣe ẹrú mọ́,gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá kan tó sọ wípé ìkáwọ́ ò lásọ̀, tẹni-n-tẹni.
Nígbà tí Olódùmarè dá wa, kò dá wa láti jìyà rárá, pàápàá àwa ìran Yorùbá, ìdí nìyí tó fi kò oríṣiríṣi àwọn àlùmọ́ọ́nì wọ̀nyí sí ọ̀dọ̀ wa, tí kò sì sí irú rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n wá sọ ara wọn di alágbára ayé lónìí, ṣùgbọ́n nítorí ojú kòkòrò, àti ìwà àtẹnujẹ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní adarí wa ní ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà tí a ti kúrò, ni wọn fi kówa s’óko ẹrú, tí àwa ọmọ Aládé wá ń jìyà káàkiri àgbáyé.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ báyìí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó lo màmá wa, ìyá Àfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fún ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá ní àkókò yí, tí Ó sì tún ti ṣètò àlàkalẹ̀ ìṣèjọba àrà ọ̀tọ̀ tí yíò dá wa padà sí irú ẹni tí a jẹ́ gangan àti gẹ́gẹ́ bí Olódùmarè ṣe dá wa, Ó sì gbe lé màmá wa lọ́wọ́ tí kò sì ní sí àyè fún àwọn amúnisìn kankan mọ́, nítorí pé ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba wa, tí kò sì ní pẹ́ mọ́, àwa ni yíò máa ṣe àkóso àwọn àlùmọ́ọ́nì wa tí kò sì sí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó lè yíi padà láíláí.