TÍ A BÁ NGBỌ́ PÉ ÈDÙMÀRÈ LÓ NRIN ÌRÌN TÍ Ó TI WÁ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÍSIÌYÍ, ÀTI PÉ ÒUN NI Ó NṢE IṢẸ́ ORÍLẸ̀-ÈDÈ WA, DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA (D.R.Y), òtítọ́ ni, ÌRÌN Ẹ̀MÍ NI, IṢẸ́ Ẹ̀MÍ SÌ NI, kò ṣe-é fi ara ṣe.

Ní àìpẹ́ yí ni Ìránṣẹ́ Olódùmarè sí àwa Ìran YORÙBÁ, Màmá wa, Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá MOA, sọ ọ̀rọ̀ ní wàrànṣeṣà síta, pé kí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), pé kí á fi ọkan balẹ̀ o, àti pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó súnmọ́ àwọn tí ó gbàbọ̀dè fún wọn tàbí tí ó le gbàbọ̀dè. MOA sọ, pàápàá pé, kò sí I.Y.P tó le gbàbọ̀dè fún àwọn.

Aṣọ ti wá ṣí, ní gidi, báyi, lójú eégún àwọn amòkùṣèkà tí ó wà ní ìdí irọ́-kàbìtì tí ó wáyé, èyí tí ó fa kí Màmá wá níláti ṣe àlàyé tí wọ́n ṣe ní ìgbà náà, èyí tí ó sì mú kí ọkàn ọmọ Yorùbá balẹ̀.

Bàbá wa, BLACK LION, ti jáde o, wọ́n sì ti tú aṣọ lójú eegún àwọn ẹni ibi náà, bẹ́ẹ̀ náà ni ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, bàbá MIKKY, tí a mọ̀ sí Mikky Babs, fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn onímàdàrú ọ̀ún pé kí wọ́n lọ so ewé agbéjẹ́ mọ́’wọ́, nígbàtí arábìrin Temmy Jay sì ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, pẹ̀lú ìtan-‘ná sí oun tí a níláti mọ̀ nípa ìnáwó tí D.R.Y ti ṣe lórí àwọn ènìyàn wa tí àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà mú, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Èkó, Ìbàdàn àti Ìṣàkóso-Ọ̀yọ́ ti Àtijọ́ (Old Oyo Empire) ní apá ibi tí kò-jẹ́-ìlú, kò-jẹ́-orílẹ̀-èdè ètò-àwọn-amúnisìn tí wọ́n npè ní nàìjíríà, ibi tí wọ́n pè ní kogí kí ó tó di pé a kúrò nínú nàìjíríà, ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún – gbogbo ìnáwó tí a ṣe lórí àwọn èèyàn wa tí àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà yí mú, lásìkò tí a ṣe ‘Bọ́-sí-‘pò-Ẹ̀tọ́-Rẹ’ (Occupation) àti Ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ (Radio Announcement) ní Ilé-Iṣẹ́ Amúludùn, àti bẹ́ẹ̀, gbogbo ìnáwó náà, pátá, ni arábìnrin Temmy Jay ṣe àlàyé rẹ̀, ní kọ́bọ̀, ní tọ́rọ́, ní sísì.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe àlàyé, ní tọ́rọ́, ní kọ́bọ̀, lórí ìnáwó tí ó ṣì nlọ lọ́wọ́ lórí àwọn àkọni wa tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà ṣe akọlù sí, tí wọ́n sì wá mú sí ìhámọ́ (POW) LẸ́YÌN tí a ti ṣe ìpolongo Ìṣàkóso-Ara-Ẹni wa, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe ọdún tí a wà yí, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, pẹ̀lú àlàyé pé, ìnáwó ti àwọn akọni wa tí nàìjíríà kọlù, tí wọ́n sì mú gẹ́gẹ́bí POW, ìyẹn ò ní owó-lọ́yà nínú o! torí a ti di orílẹ̀-èdè AṢÀKÓSO-ARA-ẸNI nígbàtí ìṣẹ̀lẹ̀ tìyẹn ṣẹlẹ̀.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Àwọn alàgbà, bàbá, Olúṣọlá Olúkòsì sọ Ọ̀rọ̀ nípa àwọn oní-ìkànnì (media) aládani, náà, nínú ètò ọ̀ún, èyí tí ó wáyé lórí ìkànnì ọmọ-ìbílẹ̀-Yorùbá, Green4god, ní àná-òde yí, ọjọ́ àbámẹ́ta, ogbọ̀n ọjọ́, oṣù bélú ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.

Àṣírí tí ó tú síta, lórí ètò náà, tí bàbá wa BLACK LION sọ fún gbogbo ọmọ Yorùbá, ni pé, àwọn ọ̀bàyéjẹ́, tí wọ́n pera wọn ní ọba, pẹ̀lú gbogbo àwọn alábaṣiṣẹ́-pọ̀ wọn ní agbésùnmọ̀mí nàìjíríà (àwọn ọ̀jẹ̀lú wọn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) ni wọ́n wà ní’dí irọ́ pé àwọn kan tí ó súnmọ́ Màmá fẹ́ gbàbọ̀dè àti pé wọ́n ti gba òwó, tí èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀.

Ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́bí bàbá BLACK LION ṣe sọ, ni pé, àwọn ọ̀bàyéjẹ́ wọ̀nyí ti ri pé ó ti bọ́ mọ́ àwọn lọ́wọ́ àti pé orílẹ̀-èdè D.R.Y ti dúró, wọ́n wá wo kíni àwọn lè ṣe, láti da nkan rú, kí àwọn wá gba àkóso (èyí tí kò lè ṣẹlẹ̀ láíláí, lágbára Èdùmarè).

Wọ́n wá wòó, pé kíni àwọn lè ṣe? ohun tí ọpọlọ òpònú wọn wá gbé sí wọn lórí ni pé kí wọ́n lo “agbé’bọn àìmọ̀” (unknown soldier) láti pa àwọn èèyàn tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ọ̀ún fúnra wọn máa rán láti lọ ṣe àkọlù sí ọgbà-ẹ̀wọ̀n tí agbésùnmọ̀mí nàìjíríà kó àwọn akọni wa sí.

Ẹ jẹ́ kí ó yé wa dáadáa. Àwọn ọ̀bàyéjẹ́ wọ̀nyí kọ́kọ́ mú àwọn kan tí ó pe ara wọn ní ọmọ Yorùbá, wọ́n mú wọn mọ́ra, wọ́n sọ fún wọn pé àwọn kan tí wọ́n súnmọ́ MOA fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ tí ó jẹ́ aburú (bẹ́ẹ̀ kẹ̀ àwọn fúnra wọn ni wọ́n fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ aburú yí).

Wọ́n wá sọ fún àwọn tí ó pera wọn ní ọmọ Yorùbá kan pé bàbá wa BLACK LION àti bàbá wa, pátápátá, OLORÍ-ADELÉ, ni wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ náa. Ìyẹn ni wọ́n fi rán àwọn kan síta, àti àwọn media kan, tí àwọn yẹn wá nsọ-ọ́ kiri pé àwọn kan tí ó súnmọ́ Màmá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kan, tí eléyí kò sì rí bẹ́ẹ̀.

Àwọn ọ̀bàyéjẹ́ tí ó rán àwọn wọ̀nyí kí wọ́n pa irọ́ yí, àwọn gan-an ni wọ́n nkó àwọn ọmọ Yorùbá kan jọ, tí àwọn ọmọ Yorùbá yí ò sì mọ̀ pé wọ́n fẹ́ fi wọ́n ṣòfò ni!

Wọ́n nkó wọn jọ pé kí wọ́n lọ ṣe àkọlù sí ọgbà-ẹ̀wọ̀n láti gba àwọn akọni wa tí ó wà níbẹ̀ sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀bàyéjẹ́ yí náà tí ṣètò bi àwọn “unknown gun-men” á ṣe pa àwọn náà, tí wọ́n á tilẹ̀ tún pa wọ́dà ọgbà-ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú, tí gbogbo ẹ̀ á wá di yánpọn-yánrin, láti bá ojú D.R.Y jẹ́ níwájú arayé, wọ́n á wá sọ pé ṣebí àwọn ti sọ pé àwọn tó súnmọ́ Màmá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kan, wọ́n á ní àwọn tó súnmọ́ Màmá wa ní ó rán àwọn tí ó lọ kọlu ọgbà-ẹ̀wọ̀n, tí àwọn náà wá bá tiwọn pàdé lọ́wọ́ “unknown gun-men.”

Wọ́n á wa sọ pé bàbá wa BLACK LION àti OLÓRÍ ADELÉ ni o rán àwọn tó lọ kọlu ọgbà-ẹ̀wọ̀n, tí unknown gun-men wá kọlú àwọn náà, ní irètí pé Màmá á wá rò pé nṣe ni àwọn tó súnmọ́ àwọn ni ó ṣe aburú yí, tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ yí rò pé ìyẹn á jẹ́ kí Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá lè wá máa bá àwọn sọ̀rọ̀, nírètí pé nípa bẹ́ẹ̀ àwọn á lè gba Blueprint lọ́wọ́ Màmá!

Nítorí náà, BLUEPRINT (àlàkalẹ̀) tó wà lọ́wọ́ Màmá, tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ wọ̀nyí rò pé àwọn le rí gbà, òun ló fa gbogbo eléyi o!

Wọ́n kọ́kọ́ rán àwọn èèyàn síta pé àwọn kan tó súnmọ́ Màmá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kan, bẹ́ẹ̀ àwọn fúnrawọn, àwọn ọ̀bàyéjẹ́, ni wọ́n fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ yẹn! kí á baa lè sọ pé, aa! wọ́n sì ti sọ bẹ́ẹ̀ o! kí Màmá wá bá wọn sọ̀rọ̀, kí Màmá rò pé àwọn tó súnmọ́ àwọn ni ó ṣe aburú!

Àṣìtáánì pátápátá gbáà ni àwọn ọ̀bàyéjẹ́ àti gbogbo àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà yí! 

Ọ̀rọ̀ wá jáde, lati ẹnu Mikky Babs pé kí gbogbo àwọn tí ó gbé irọ́ síta pé àwọn tó súnmọ́ Màmá ni wọ́n fẹ́ ṣe aburú, kí wọ́n máa retí ìdájọ́ wọn o!

Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ jáde pé, ọmọ Yorùbá, ẹ yé ṣe nkan tí kìí ṣe àṣẹ tí D.R.Y bá fún wa! Gbogbo ẹ̀yin tí wọ́n nkó jọ pé kí ẹ lọ ṣe àkọlù sí ọgbà-ẹ̀wọ̀n, bí wọn ìbá ṣe fi ẹ̀mí gbogbo yín ṣòfò nìyẹn!

Bàbá, Olúṣọla Olúkòsì wá tún rán gbogbo agbóhùnsáfẹ́fẹ́ (media) létí pé, a ò ní aládani kò lè ní media tiẹ̀, rárá o! ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè wa ní Àkọ́kọ́! THINK YORUBA FIRST! Wọ́n ní ìròyìn orí iypdry TV ni kí gbogbo wa gbé lárugẹ, kí ẹnikẹ́ni máṣe gbé ohun tí ó lòdì sí òtítọ́ bóṣenlọ, èyí tí iypdry TV ngbé síta!

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates