Màmá wa, ÌRÁNṢẸ́ OLÓDÙMARÈ sí ìran Yorùbá, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tú àṣírí àwọn afipá jẹgàba tó wà lórí ilẹ̀ wa, pẹ̀lú àwọn alábaṣiṣẹ́-pọ̀ wọn – àwọn ọ̀bàyéjẹ́ tí wọ́n pera wọn lọ́ba.
Màmá wa MOA jẹ́ kí á mọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wa sọ lórí amóhùnmáwòrán orílẹ̀-èdè wa, iypdry TV, pé àwọn ajẹgàba yí npète láti kó ìbọn fún àwọn kan, kí wọn lọ ṣe àkọlù sí ọgbà-ẹ̀wọ̀n tí wọ́n kó àwọn ọmọ I.Y.P àti àwọn ológun orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), sí! Wọ́n pète pèrò àti pa lára àwọn alámojútó-ọgbà-ẹ̀wọ̀n (wọ́dà) tí ó wà níbẹ̀, kí wọ́n sì tú àwọn tí ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọn náà sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ ṣe èyí láti purọ́ wípé orílẹ̀ èdè Yorùbá ni ó ṣe àkọlù náà.
Wọ́n npète pèrò láti lo ìgbésẹ̀ ibi náà láti da gbogbo nkan rú, kí àwọn aṣojú-ìṣakóso orílẹ̀ èdè wa má lè wọ inú Secretariat (oríkò-ilé-ìṣẹ́-ìṣàkóso) wa, èyí tí ó jẹ́ pé òfo ọjọ́ kejì ọjà ni.
MOA rán àwọn ẹni ibi yí létí pé, gbogbo àgbáyé ni ó mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ pé ọ̀nà àlááfíà ni MOA, ntọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀. Ẹni tí ó sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ pé ọ̀nà àlááfíà ni òun ntọ̀, tí òun á sì máa tọ̀, kò lè wá máa gbé ìgbésẹ̀ aburú láti lọ pa àwọn wọ́dà, tàbí láti ṣe àkọlù sí ọgbà-ẹ̀wọ̀n; nítorí èyí, wọ́n ti ṣìí.
Bẹ́ẹ̀ náà ni MOA fí ohùn ránṣẹ́ sí Ṣèyí Mákindé, ajẹgàba ìlú Ìbàdàn tí OLÓDÙMARÈ ti parí iṣẹ́ bí ó ṣe máa ṣí ìdí rẹ̀ kúrò ní’bi ohun-ìní ọmọ-Yorùbá ní àìpẹ́ yí: Màmá sọ fun pé ọ̀ràn tí ó ndá npọ̀-síi ní ojoojúmọ́, á sì kábamọ̀ pé wọ́n bí òun sáyé.
Bákan-náà ni MOA fi ohùn ránṣẹ́ sí Bọlá Ahmed Tinubú, ẹni tí àwọn tí wọ́n njẹgàba sí orílẹ̀ èdè D.R.Y gbójúlé, pé dídúró tí ó dúró ní ìgbà ti June 12, ni àwọn ṣì nwò mọ lára.
Bákan-náà, MOA fi ohùn ránṣẹ́ sí Àrẹ̀mú Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, pé kí ó mọ̀ pé òun náà kò ní lọ láì rí ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ si fún àbọ̀dè rẹ̀ lòdì sí Ìràn-Yorùbá.
Màmá ní àwọn ní láti ṣàlàyé ní kíákíá fún gbogbo àwa ọmọ I.Y.P ti D.R.Y, kí á le mọ̀ pé ohun tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ àti ajẹgàba wọ̀nyí npète rẹ̀ nìyí, Ṣùgbọ́n OLÓDÙMARÈ tó nṣe iṣẹ́ D.R.Y wà lójú iṣẹ́, àwọn ọ̀tá wọ̀nyí sí ti pòfo!