Kí Olódùmarè ó máa tẹ̀síwájú nígbà gbogbo láti máa kó wa yọ ni; kí àwa náa máṣe fi àyè sílẹ̀ fún ohun búburú kankan ní Orílẹ̀-Èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Ìdí tí ọ̀rọ̀ yí fi wáyé ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí a gbọ́ lórí ẹ̀rọ-ayélujára, èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní ibi tí ó fẹ̀gbẹ́ tì wá, èyíinì èto àwọn amúnisìn tí wọ́n npe ní Nàìjíríà, ibi tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè, tí kìí ṣe ìlú.

Lóotọ́ àti ní òdodo, kò sí ohun tí ó kàn wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nàìjíríà, ṣùgbọ́n jìjẹgàba tí wọ́n njẹgàba ni ó fi kàn wá, àti láti lè jẹ́ kí a máa kíyèsára. 

Ìròyìn náà sọ pé, ní agbègbè ìbílẹ̀ Silame, ní ìpínlẹ̀ Sokoto wọn lọ́hùn-ún, wọ́n ní bàlúù-àwọn-ológun ju àdó olóró sí àwọn agbègbè méjì kan níbẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé ó ṣèèṣì ni ò. Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn ológun nàìjíríà á sọ àdó olóró sí àárin àwọn ará nàìjíríà wọn, tí wọ́n á sì sọ pé ó ṣèèṣì ni.

Ìdí nìyí tí a fi sọ pé kí Olódùmarè máa fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ wa; a ò sí lára nàìjíríà mọ́; ṣùgbọ́n ìjẹgàba nàìjíríà ní orí ilẹ̀ wa ní àkókò yí, ó gba kí á fojú sílẹ̀ gidi, kí á máṣe gba ìgbàkugbà láàyè.

Ohun tí wọ́n sọ pé ó ṣèèṣì yí, ó níye ènìyàn tí ó kú síi. Gẹ́gẹ́bí a ṣe sọ, kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí nàìjíríà máa ju àdó olóró sí àárín àwọn ará nàìjíríà, tí wọ́n á sì sọ pé ó ṣèṣì ni.

Ìròyìn tí a ti ngbọ́ láti ìgbà-dé-ìgbà, fihàn, gbangba pé, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun tí wọ́n á sọ pé ó ṣèèṣì, irọ́ ni o! Èròǹgbà àwọn amúnisìn ni láti pa àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí a ti ṣe mọ̀, àwa ti bọ́ ní tiwa.

Ìròyìn náà sọ pé àwọn agbésùnmọ̀mí kan ni wọ́n fẹ́ sọ àdó olóró sí, tí ó wá ṣèèṣì ba ará-ìlú wọn lọ́hùn-ún. 

Olódùmarè ti yọ àwa ní tiwa, Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), kúrò nínú wàhálà nàìjíríà àti ti àwọn amúnisìn.

Ara àwọn oore tí Olódùmarè ṣe fún wa nìwọ̀nyí ó, a ti wà ní orílẹ̀-èdè tiwa, tí a sì ntẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún wa nípasẹ̀ Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin). A ò sí ní ètò-amúnisìn wọn mọ́, níbi tí wọ́n á ti máa ṣe ibi sí ará ìlú, tí wọ́n á wá sọ pé ó ṣèèṣì ni.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Bíbíire kò ṣeé fi owó rà