Màmá wa, Olùgbàlà Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ pé gbogbo ọmọ Yorùbá tí aburú ti dé bá ìgbésí ayé wọn látàrí ìwàk’iwà, ni yíò rí kádàrá wọn gbà padà gẹ́gẹ́bí ọmọ ológo tí Olódùmarè fẹ́ kí wọ́n jẹ́.

Ìyá wa sọ pé inkan tó bá máa gbà ni a máa fun, kí ògo wọn lè búyọ.

L’ọnà kíní, ìtọ́jú tí ó péye máa wà fún wọn, láti mú ọkàn àti ìrònú wọn kúrò nínú ìgbé-ayé òṣì, kí wọ́n le mọ̀ pé ayé míràn tún wà, yàtọ̀ sí ayé rádaràda tí wọ́n ti ngbé tẹ́lẹ̀, kí iyè wọn lè ṣí láti ní ìfẹ́ sí àwọn ìgbé-ayé rere!

Ọ̀nà kéjì, ìtọ́jú-ìwòsàn máa wà fún wọn, láti lè mú gbogbo àgọ́-ara wọn padà bọ́ s’ipò, kúrò nínú oríṣiríṣi àìṣedéédé tí ìgbé-ayé búburú ti tẹ́lẹ̀ ti kó sí wọn l’ara.

Ẹ̀kẹ́ta, ìrànlọ́wọ́ nípa ohun-ti-ẹ̀mí, gẹ́gẹ́bí ìgbẹ́kẹ̀lé oníkálùkù wọn máa wà, títí tí wọ́n á fi di ènìyàn gidi padà, tí ògo wọn á búyọ!