Ilé tí a bá fi itọ́ mọ, ìrì ni yóò wóo. Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ní orí òtítọ́ ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) máa ń sọ wípé, ìpìlẹ̀ kẹta yí kò ní wó láéláé.

Nítorí náà, ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, àwọn ará ìlú ni yóò máa yan ẹni tó bá wù wọ́n sí ipò, kò sí ààyè fún ẹnikẹ́ni láti ná owó ṣáájú ìdìbò tàbí ní àkókò ìdìbò, nítorí tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ti ra ẹ̀rí ọkàn àwọn ará ìlú nìyẹn, wọn kò sì ní ní ẹnu ọ̀rọ̀ láti pe irú aṣojú bẹ́ẹ̀ ní’jà.

Kòsí ààyè fún bàbá ìsàlẹ̀ tàbí ìyá ìsàlẹ̀ láti gbé aṣojú kankan lé àwọn ará ìlú lórí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Fúnra àwọn ará ìlú ni wọn yóò yan ẹni tí wọ́n fẹ́. Ẹni náà sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí àwọn ará ìlú mọ̀ dáadáa ní agbègbè ibi tí ó ti fẹ́ ṣe aṣojú.

MOA sì ti jẹ́ kí ó yé wa wípé, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ètò ìdìbò ti wáyé ni èsì yóò ti jáde láìsí awúrúju  kankan. Gbogbo rẹ̀ ni yóò hàn kedere sí àwọn  ará ìlú.

A ò sì ní pe àwọn adarí orílẹ̀ èdè D.R.Y ní olóṣèlú, aṣojú ni a óò máa pè wọ́n. Èyí yóò jẹ́ kí ó wà ní oókan àyà wọn wípé àwọn wá sin ará ìlú ni, kìí ṣe láti rí ara wọn bíi wípé wọ́n ṣe pàtàkì ju àwọn ará ìlú lọ, nítorí àparò kan kò ga jù kan lọ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Gbogbo ìgbà ni MOA sì máa ń sọ wípé, èyíkéyìí nínú àwọn aṣojú wa tí ó bá da ọwọ́ rú, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni a óò da ẹsẹ̀ òun pàápàá rú. 

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún oore Rẹ̀ lórí ìran Yorùbá tí kò jẹ́ kí ìran wa ó parun, tó sì tún fún màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) ní kọ́kọ́rọ́ àṣeyọrí àti àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí yóò mú gbogbo wa gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. 

Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Òròmọadìyẹ ńbá àṣá ṣeré, ó rò pé ẹyẹ oko lásán ni