Ìṣẹ̀dá àwa ọmọ Yorùbá yàtọ̀ gedegbe, ẹyínlójú Olódùmarè ni a jẹ́! 

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe máa ń sọ wípé, Olúwa ló ní kí a padà sí orísun wa, ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí.

Èyí  túmọ̀ sí pé kí a padà sí àwọn ohun tó bá ìṣẹ̀dá wa mu. Àkọ́kọ́, a ò gbọ́dọ̀ darapọ̀ mọ́ ẹ̀yà míràn láti ṣe ìjọba, torí orílẹ̀-èdè aṣẹ̀jọba ara ẹni ni wá.

Èkejì ni pé, a níláti padà sí èdè wa, èyí tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ báyìí. 

Bákannáà, àṣà wa, pàápàá jù lọ, àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí tó jẹ́ ti ìṣẹ̀dálẹ̀ wa, ìyẹn ló bá ara wa mu, tó máa ṣe ara wa ní àǹfààní. 

 Màmá wa MOA sọ fún wa pé àwọn tó bá ń ta oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá gbọ́dọ̀ ṣeé ní ọ̀nà tí àwọn ìyá wa ń gbà ṣe é ní ayé àtijọ́.

Pákò tí a fi ń fọ eyín wa, èyí pẹ̀lú ohun tí a máa gbé lárugẹ, ó ní àǹfààní tí ó ṣe fún eyín wa, tí àwọn ńkan tí a fi ń fọ eyín wa ní ayé òde òní kò leè ṣe. Nítorí èyí, àyè kò ní sí fún ẹnikẹ́ni láti bu ẹ́nu àtẹ́ lu ohun tí ó jẹ́ ti ìbílẹ̀ wa.

A ti mọ̀ pé kò sí àyè fún  oúnjẹ tàbí irúgbìn ayédèrú ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) bẹ́ẹ̀ náà ni a ó máa lo ewé àti egbò fún ìtọ́jú ara wa tí a ò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó ta àbùkù bá ohunkóhun tó jẹ́ ti ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá, nítorí wípé, ohun àmúyangan ni wọ́n jẹ́ fún wa.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.