Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) jẹ́ orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), tí ìṣe-rere gbogbo I.Y.P jẹ lógún.
Ìkan gbòógì lára ohun tí D.R.Y dúró lé, ni pé, láyé, ìyà kò tún jẹ ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá mọ́.
Olódùmarè kẹ́ ìran Yorùbá, púpọ̀púpọ̀, bí ó ṣe kẹ́ wa pẹ̀lú ilẹ̀ ọlọ́ra, ni ó kẹ́ wa pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àti oríṣiríṣi àlùmọ́nì ilẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni ó kẹ́ wa pẹ̀lú ohun-àmúṣọrọ̀ tó pọ̀ ní àyíká wa, yàtọ̀ sí ti inú-ilẹ̀. Pabambarì, ó wá ṣe Ìran Yorùbá ní Ọlọ́pọlọ-Pípé, oní-làákàyè, tí a ò sì ya ọlẹ.
A tilẹ̀ fẹ́ràn kí á máa dáwọ́lé ohun nlá-nlá ní rere, bẹ́ẹ̀ ni a jẹ́ akínkanjú nínú òwò-ṣíṣe àti ìdókòòwò lóríṣiríṣi.
Ìwọ̀nyí túmọ̀ sí pé orílẹ̀-èdè olọ́lá, ológo, tí ó sì ní ọrọ̀-púpọ̀ ni Olódùmarè dá wa. Láìsí àníàní, gẹ́gẹ́bí ìyá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ṣe máa nsọ, kò sí ìdí kankan tí ìyà, bí ó ti wù kí ó keré mọ, fi ní láti jẹ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y.
Lára ètò tí ó ti wà nílẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́-gbowó-iṣẹ́ ní D.R.Y ni pé, Ọ̀sẹ̀-méjì-méjì ni òṣìṣẹ́ yíò máa gba owó-iṣẹ́ wọn ní D.R.Y, tí owó ọ̀sẹ̀-méjì kọ̀ọ̀kan sì máa jẹ́ owó tí ọkàn ènìyàn dùn sí.
Eléyi kò wá tán síbẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ànfààní míràn tí I.Y.P máa máa jẹ, ìgbádùn àti ìfọkàn-balẹ̀, rẹpẹtẹ, ni owó ọ̀sẹ̀-méjì-méjì yí máa jẹ́, látàrí pé owó-gidi tún ni, kìí ṣe owó àrímọ́-l’ojú.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀-Èdè mi, D.R.Y; ìbùkún ni fún Ìyá Òmìnira wa, màmá wa, MOA.