Olódùmarè fi ọrọ̀ rẹpẹtẹ dá ilẹ̀ Yorùbá lọ́lá, Ó fún wa ní ilẹ̀ ọlọ́ràá tó nṣe àtìlẹyìn fún oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn láti so dáradára àti lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ìgbà òjò, ẹ̀rùn, ooru, òtútù ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀, nítorínáà, a ó ní ànító oúnjẹ àti àjẹṣẹ́kù. Ní àfikún, Olódùmarè fún wa ní àwọn ènìyàn tó pọ̀, tó sì ní agbára àti ọgbọ́n pẹ̀lù akínkanjú láti ṣiṣẹ́ di ọlọ́rọ̀.

Yàtọ̀ sí gbogbo èyí, àwọn ohun àlùmọ́nì àmúṣọrọ̀ oríṣiríṣi bí i wúrà, fàdákà, epo rọ̀bì àti àwọn òkúta iyebíye lóríṣiríṣi ni Ọlọ́run fi sí abẹ́ ilẹ̀ wa.

A tún ní omi òkun àti ọ̀sà pẹ̀lú àwọn odò nlánlá àti kékèké tí ó kún fún ohun àlùmọ́nì pẹ̀lú nkan abẹ̀mí lóríṣiríṣi, àwọn igbó kìjikìji ti ó kún fún àwọn igi àti ẹranko igbó lọ́pọ̀lọpọ̀ tí yíó mú owó wọlé nípa ohun àmúṣọrọ̀, ìrìn-àjò-afẹ́ pẹ̀lú àwọn ewé àti egbò fún iṣẹ́ ìtọjú aláìsàn pẹ̀lú ìwòsàn fún ọ̀pọ̀ àìsàn àti àrùn.

Àwọn ẹ̀bùn àdámọ́ Ọlọ́run Olódùmarè wọ̀nyi fún àwa ọmọ Aládé, mú kí ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ láti ìgbà ìwáṣẹ̀.

Àwọn ẹ̀bùn, iṣẹ́ ọwọ́, tálẹ́ntì àti ọgbọ́n àtinúdá tí Olódùmarè fún oníkálukú láti lò fún ìṣe rere, ni ìṣàkóso D.R.Y yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹni náà láti tayọ nípa ètò ẹ̀yáwó láì sí èlé lórí rẹ̀, láti dá iṣẹ́ sílẹ̀, yálà ilé iṣẹ́ nlá tàbí ní kéréje-kéréje.

Àwọn Aṣojú Ètò Ìmòjútó-Ìlú ní Democratic Republic of the Yoruba yíó tún ṣe ìrànlọ́wọ́ nípa ìpèsè àmójútó, ètò ọrọ̀ ajé tó dára àti ààbò tó dájú ní orílẹ̀ èdè wa.

Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá fi yé wa pé àrà ọtọ ni ètò ẹ̀kọ́ wa yíò jẹ́, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gboyè á lè dáwọ́ lé iṣẹ́ ti wọ́n kà’wé fún tàbí láti fi dá iṣé sílẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìṣàkóso.

Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ìkàwé-gboyé àkọ́kọ́ ní Fásitì. Gbogbo ẹnití ó bá sì yan iṣẹ́ oṣù láàyò, owó oṣù tó dára ní yíó máa gbà, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ní wọn á ma gba owó ọ̀yà wọn. 

Àwọn ètò àlàkalẹ fún ìdàgbàsókè yí kò lè jẹ́ ohun ìnira fún orílẹ̀-èdè wa nítorí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí Ọlọ́run fi ta wá lọ́rẹ, àti pé a ò ní kó owó àti ọrọ̀ wa lọ sí ibòmíràn. Aó ma lòó fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa ati  ìtọ́jú ará ìlú. Gbogbo àwọn ohun rere wọ̀nyí kò ní jẹ́ kí ìṣẹ́ àti òṣì rí àyè nínú ayé I.Y.P kankan.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀-Èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y

A kì í s’òótọ́ inú, kí ọ̀rọ̀ ẹni má d’ayọ̀,b’áyé ẹni bá dojúrú ìwà èèyàn ló yẹ ká wò