Àǹfàànií ńlá ló jẹ́ fún gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá pé ní déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí ni Ọlọ́run Olódùmarè lo Màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá fún ìran wa láti jẹ́ kí a dá ara wa mọ̀ gẹ́gẹ́bí 

ọmọ Yorùbà nípa ṣíṣí ojú wa sí àwọn ǹkan tí ó wà ní orílè èdè wa, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y). 

Màmá wa MOA jẹ́ kí ó yé wa wípé Ọmọ Yorùbà ló ni ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n sì fi oríṣiríṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan yé wa nípa ara wa gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá. Àṣa wa, Ẹ̀tọ́ wa, ojúṣe wa, èdè wa, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn wọ̀nyí wà fún ìgbé lárugẹ orílẹ̀ èdè wa.

Democratic Republic of the Yorùbá IypdryTV news updates.