Ètò ti wà fún ohun gbogbo ni Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé 

fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, àwọn adelé wa sì ti ń mú’sẹ́ ṣe láti ríi dájú pé orílẹ̀ èdè D.R.Y di àpéwò tí àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé yóò sì máa wo àwòkọ́ọ̀ṣe wa.

Ìṣàkóso D.R.Y yóò ríi dájú pé gbogbo àwọn ojú pópó káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni ètò ìrìnnà ìgbàlódé yóò wà láti mú  kó rọrùn fún àwọn awakọ̀ àti àwọn tó ń rìn ní ojú pópó.

Àwọn àmì ìrìnnà ojú pópó náà yíò wà lóríṣiríṣi

Èyí yóò mú ìdènà bá ìjàǹbá ọkọ̀ ojú pópó àti súnkẹrẹ-fàkẹrẹ. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní ìwé àṣẹ ìwakọ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti wa ọkọ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso bá tẹ̀ yóò fi’mú k’áta òfin.