Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti dúró, yálà ọ̀tá fẹ́ tàbí wọ́n kọ̀.

Ó ti pẹ́ tí ìran Yorùbá ti ń j’ìyà lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, ṣé ti àwọn ọba ni ká sọ ni, àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní olóṣèlú tàbí àwọn  amúnisìn láti ìta. Ẹni gb’épo lájà kò jalè bí kò ṣe ẹni tó gbàá sílẹ̀.

Ṣèbí àwọn amúnisìn tí inú ilé tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba, aṣíwájú tàbí olóṣèlú ilẹ̀ Yorùbá gan-an ni wọ́n ń gbàbọ̀dè fún ìran Yorùbá. Àwọn amúnisìn ló ń yan ẹni tí wọ́n fẹ́ sípò. Wọn ò tẹ̀lé ìlànà tí àwọn babańlá wa ń gbà yan ọba mọ́.

Ẹnikẹ́ni tó bá ní àníyàn láti gba àwọn ènìyàn kúrò nínú òṣì, wọ́n á ní kí wọ́n lọ gba ẹ̀mí rẹ̀ lójijì. Ọmọ Aládé wá di ẹni tó ń ṣe ẹrú ní ilẹ̀ àjèjì nítorí àti rí ọwọ́ mú lọ s’ẹ́nu.

Wọ́n sọ àwọn ọmọ ológo di ìdàkudà, ìwà ọmọlúwàbí wá s’ọ̀wọ́n ní àwùjọ ọmọ Yorùbá. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó gbà wá lọ́wọ́ àwọn amúnisìn wọ̀nyí nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó fi iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá rán. 

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ẹ má jẹ̀ẹ́ kí a gba ẹnikẹ́ni tó lè dúró gẹ́gẹ́ bíi amúnisìn láàyè láàárín wa, lẹ́yìn tí a ti ṣe ìkéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún. Tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ń gbé ìgbésẹ̀ tó leè ṣe àkóbá fún ìran Yorùbá, ẹ má ṣe dágunlá sí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ fi tó ìjọba Adelé orìlẹ̀ èdè Yorùbá létí lórí:

,

Gbogbo ìwà ìmúnisìn ti parun ní ilẹ̀ Yorùbá,àwa ọmọ Aládé sì ti wọ inú ògo wa lọ.

Democratic Republic of the Yoruba