Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) kò sí àyè fún ìwà ìbàjẹ́, nítorí àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè fún màmá wa, ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá kò fi àyè sílẹ̀ fún ìwà ìbàjẹ́ kankan.
Àwọn ará ìlú yóò mọ kíni òfin sọ, èyí yóò mú kí oníkálukú mọ ẹ̀tọ́ àti ojúṣe rẹ̀ sí ìṣàkóso àti sí ọmọnìkejì, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣàkóso náà yóò b’ọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ará ìlú.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń ṣọ wípé, àparò kan kò ní ga jù’kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá, àti pé, ẹnikẹ́ni nínú ètò ìṣàkóso tó bá da ọwọ́ rú, aó da ẹsẹ̀ rẹ̀ rú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Èyí yóò mú kí oníkálukú mọ̀ pé àrà ọ̀tọ̀ ni ìṣàkóso orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá. Ẹnìkan kò ṣe pàtàkì ju ẹlòmíràn lọ, kò sí ojú sàájú, kò sí àyè fún rìbá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá.
Díẹ̀ díẹ̀ nimú ẹlẹ́dẹ̀ẹ́ fi ń wọgbà