Àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) tí Olódùmarè fún màmá wá, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, kò fi àyè sílẹ̀ fún rìbá tàbí owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ rárá, yálà ní ilé iṣẹ́, ní ilé ìwé, nínú ètò òṣèlú àti ní oríṣiríṣi ẹ̀ka.
Ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti ṣe lòdì sí àlàkalẹ̀ yí, ìjọba D.R.Y kò ní fi ojú’re wo irú ẹni bẹ́ẹ̀, nítorí pé ní orí ọ̀títọ́ ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé, ẹni tí ó bá sì ti di ipò kan tàbí òmíràn mú ní orílẹ̀ èdè wa gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ láì fi dúdú pe funfun fún ọmọ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba yí, kò sì irú rẹ̀ ní àgbáyé, àwọn nìkan ni Olódùmarè fún tì kò sì sí ẹ̀dà rẹ̀ ní ibikíbi.