Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ Yorùbá̀ (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ni yóò jẹ ìgbádùn lorísìírísìí nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé fún wa nípasẹ̀ Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin).
Gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ fún wa, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó. Gbogbo ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́́, ni wọn yóò máa gbà ní àsìkò, nítorí pé àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ọ̀rẹ́ ará ìlú ni wọ́n, wọn yóò máa ṣe ojúṣe wọn bí ó ṣe tọ́ àti bí ó ti yẹ láti ríi dájú pé ìyà kò jẹ ẹnikẹ́ni.
Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí ẹnìkọ́ọ̀kan wa gẹ́gẹ́ bíi I.Y.P ti D.R.Y máa sa ipá wa láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe pàápàá gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè D.R.Y, nítorí pé òtítọ́ níí gbé orílẹ̀-èdè lékè.
Ní ibi iṣẹ́ wa, kí a má ṣe rí I.Y.P tí yóò ṣe lòdì sí alakale D.R.Y tàbí gba àbọ̀dè fún orílẹ̀ èdè wa. Kí a má ṣe fi ojú kéré iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni ń ṣe tàbí kí a máa rí iṣẹ́ kan bíi iṣẹ́ ìdọ̀tí, kí a má sì ṣe ojúsàájú nítorí pé bákan náà ni gbogbo wa.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y)
Ẹni tí a ńwò kì í wò’ran