Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) Olódùmarè fún wa ní ilẹ̀ ọlọ́ràá àti ojú ọjọ́ tó dára. Òjò ń rọ̀ ní àkókò rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni oòrùn ń ràn ní àkókò rẹ̀. Nítorí náà kò sí ìdíwọ̀ kankan fún àwọn àgbẹ̀́ ní orílẹ̀ èdè wa láti má ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn.

D.R.Y yóò ṣe ìrànwọ́ owó fún àwọn àgbẹ̣̀ wa láti ra àwọn ohun èlò ìgbàlódé fún iṣẹ́ ọ̀gbìn, láti leè pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu. Kò sí ìdíwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, nítorí pé ètò ti wà lorísìírísìí láti mú kí ó rọrùn fún gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P)

Kòsí ebi tàbí ìyàn ní ilẹ̀ Yorùbá, ohun rere gbogbo tí a nílò láti gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn ni Olódùmarè fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ.

Gbogbo àwọn tí wọ́n ń béèrè wípé, kíni a óò máa jẹ, ẹ jẹ́ kí ó yé wọn wípé àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, fún ìtọ́jú àwa ọmọ Yorùbá ni, kìí ṣe láti fi ìyà jẹ wá. Àjẹyó àti àjẹsẹ́kù ni a ó jẹ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, nítorí pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ ilẹ̀ wa. 

Kí a rántí wípé, kò sí àyè fún irúgbìn GMO ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, àwọn aṣojú wa kò fi ọwọ́ sí gbígbin irúgbìn ayédèrú tó lè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara wa, fún ilẹ̀, tàbí àkóbá fún àgbègbè, nítorí náà, ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Ẹni tó ní láti ìgbà tóun ti dáyé ìyà ò jẹ òun rí, ohun tí ìyà ńjẹ lẹ́nu ni ò tíì kúnná