Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni kí àwa ìran Yorùbá padà sílé, ló sì gbé ìyá Aláàánú dìde fún wa,màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) láti gbé wa dé èbúté àṣeyọrí.
Ní báyìí, àyípadà ọ̀tun ti de bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé fún màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) láti ṣe àkóso ní orílẹ̀-èdè D.R.Y.
Lára àwọn ohun tí a óò jẹ ìgbádùn rẹ̀ ní gẹ́gẹ́ bíi I.Y.P ti D.R.Y ni ètò ẹ̀yáwó tí kò ní èlé lórí fún èyíkéyìí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá tó bá fẹ́ ṣòwò, níwọ̀n ìgbà tí o bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P, o ní ẹ̀tọ́ sí ètò ẹ̀yáwó tí a ń sọ yí, tó bá ṣáà ti jẹ́ wí pé fún okòwò ni. Iye tí ẹnìkọ́ọ̀kan bá gbà ni yóò sì san padà láìsí èlé kankan.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wa nípasẹ̀ wọn yí, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé. MOA nìkan ni Olódùmarè fún tí kò sì sí ẹ̀dà rẹ̀ ní ibikíbi.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí oníkálukú wa máa ronú ohun tí a fẹ ṣe ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèje tó wà ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí, gbogbo ìgbà náà ni màmá wa MOA máa ń sọ wípé a ò ní rìn rárá, a máa fò ni, nítorí kò sí nǹkankan nílẹ̀ mọ́.
Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn àwọn àlàkalẹ̀ ètò loríṣìíríṣìí tí Olódùmarè ní fún wa.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y)