Ìṣètò Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) wà fún ìmójútó ará-ìlú. Èyí ni pé kò sí ìjìyà mọ́ fún ọmọ Yorùbá. Orílẹ̀-Èdè wa yíò mójútó gbogbo ohun tí a máa fi ní ìgbáyé-gbádùn, a ò sì ní máa sun ẹkún àìríjẹ, àìrímu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́bí Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, lọ́wọ́, òun ni ó jẹ orílẹ̀-èdè D.R.Y lógún! Ìmójútó ìrọ̀rùn-ará-ìlú jẹ́ Gbòógì Ànfààní orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

Nítorí èyí, láti àárọ̀-ṣú’lẹ̀, àṣáálẹ́ mọ́’jú òwúrọ̀, ní ìgbà-gbogbo, àti wákàtí gbogbo, ọmọ Yorùbá, Ìran Yorùbá àti Ilẹ̀ Yorùbá ti bọ́ sí Ìgbáyé-Gbádùn, nítorí ojúṣe Orílẹ̀-Èdè D.R.Y ni Mímójú-tó Ìṣe-rere, Ìrọ̀rùn, Àláfíà, Ààbo ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá ní orí-ilẹ̀ àwọn babanlá wa – tí eku yíò máa ké bí eku, ẹyẹ yíò máa ké bí ẹyẹ, ọmọ ènìyàn yíò máa fọ’hùn bí ọmọ-ènìyàn; aboyún yíò máa bí wẹ́rẹ́; ògo Olódùmarè yíò tàn-‘mọ́lẹ̀ káakiri Ilẹ̀-Àjogúnbá Yorùbá, ọkàn wa yíò sì balẹ̀; ẹnikẹ́ni kò níí leè dẹ́rùba Ọmọ Yorùbá, lórí ilẹ̀ Baba wa, tí a ó sì máa yọ̀, a óò sì máa dun’nú, gẹ́gẹ́bí Ìyá wa, MOA, Ìránṣẹ́-Olódùmarè ṣe máa nsọ, pé, kí a máṣe gbàgbé o, ohun rere Ńlá Ńlá tí Ọlọ́run Olódùmarè ti ṣe fún’wa yí, kí á sì máa yìn títí ayé, nítorí ìṣètò D.R.Y, ìṣètò tí ó nmójútó ìṣe-rere ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá ni.