Gbogbo èwe I.Y.P ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ni a kí kú oríre nítorí láti inú oyún ni wọn yóò ti máa jẹ ìgbádùn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé fún màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin). Èyí yóò jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ayé èwe I.Y.P.
Ètò ti wà nílẹ̀ lorísìírísìí fún ìgbá’yé gbádùn àwọn èwe D.R.Y. Bí wọ́n bá ti ń gbà ìtọ́jú ni ẹ̀ka ti ìlera, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò máa gbádùn àwọn ohun am’áyédẹrùn ti ìgbàlódé lọ́kan-ò-jọ̀kan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti tayọ nínú ẹ̀bùn àmútọ̀run wá wọn.
Gbogbo òbí ni yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn èwe wọn, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n bá nṣe, ni wọn yóò ma tayọ.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá.