Ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), ìrọ̀rùn ni àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ àti òntàjà yíó ma fi ṣiṣẹ́ wọn nítorí kò ní sí ìyọnu fún wọn.
Nínú àlàyé màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, (Olóyè Ìyá Ààfin) lórí àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso wa, D.R.Y kò ní fi àyè gba ẹgbẹ́ ọlọ́jà tàbí ti oníṣẹ́ ọwọ́ kankan, ṣe a mọ̀ pé àwọn olóṣèlú ma nlo àwọn olórí ẹgbẹ́ yìí láti kó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lẹ́rú ni.
Láfikún, oríṣiríṣi owó tí kò ní ìṣirò ní àwọn olórí yí tún máa ngbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí wọ́n á pèé ní orúkọ tí kò ní ìtumọ̀. Nkan bayìí ma nmú ìnira bá àwọn ará ìlú. Gbogbo ẹgbẹ́ yìí jẹ́ ìyànjẹ àti láti tẹ ẹ̀tọ́ ẹni lójú mọ́lẹ̀, nkan wọ̀nyí tún nṣokùfà àìní, òṣì àti ọ̀wọ́n gógó ọjà.
Màmá wa MOA tún fi kún àlàyé wọn pé, gbogbo oníṣẹ́ ọwọ́ tó kọ́’ṣẹ́ mọ’ṣẹ́ ni yíó forúkọsílẹ tí wọ́n á gba òntẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso D.R.Y, tí wọ́n á sì ní ànfàní ìdánilékòó tí yíó ma wáyé lórí ọ̀nà láti mú ìlọsíwájú bá iṣẹ́ náà àti ìmọ̀ nípa ìrìn-iṣẹ́ ìgbàlódé.
Nipa ti àwọn òntàjà, màmá MOA wípé ìsọ̀ máa wà, nínú àwọn ọjà, àwọn ṣọ́ọ̀bù náà yíó wà káàkiri orílẹ̀ èdè Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ni, kò ní sí ọjá títà ní ẹgbẹ́ ọ̀nà tàbí ní ojú pópó, àyè kò dẹ̀ ní sí fún kí ẹnikẹ́ni máa já tíkẹ́ẹ̀tì láti gba owó lọ́wọ́ ọlọ́jà tàbí oníṣẹ́ ọwọ́.
Màmá wa sì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀yáwó tó ma wà fún gbogbo ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) láti ṣe òwò tàbí iṣẹ́, tí wọ́n kò ní san èlé lórí ẹ̀. Ìfọ̀kànbalẹ̀ yíó wà fún òntàjà àti oníṣẹ́ ọwọ́ fun àtà jèrè àti àpamọ́wọ́ owó.
Ìgbádùn gidi rèé tí àwọn Adelé alákòóso wa bá ti wọlé sí oríkò ile iṣẹ́ ìṣàkóso wa ni kò pẹ́ kò pẹ́ nínú ọdún àjọyọ̀ wa yìí. Gbogbo ọmọ Aládé ẹ jẹ́ ká ma múra sílẹ̀.
Kokoko la nrọfá adití