Lára ànfààní Orílẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) fún gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti D.R.Y, tí a sì fẹ́rẹ̀ẹ́ le pè ní kònkarí ànfààní orílẹ̀-èdè wa, ni pé, Ìfọ̀kànbalẹ̀ wà fún gbogbo I.Y.P ní D.R.Y.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa ńsọ, Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ wọn, jẹ́ èyí tí, níwọ̀n-ìgbàtí a bá ti ńrìn nínú Àlàkalẹ̀ náà, gẹ́gẹ́bí a ṣe bá Olódùmarè dá májẹ̀mú, tí a ò yà sí ọ̀tún tàbí òsì, ire-ire ni ojú wa máa máa rí. Gbogbo àwọn ètò ìgbáyé-gbádùn tí ó wà fún wa ní D.R.Y jẹ́ àwọn ètò ìmúnilọ́kàn-balẹ̀.
Bí àpẹrẹ, kò sí ìfòyà láti bí’mọ, nígbàtí a mọ̀ pé kí á tó lóyún ọmọ, ni D.R.Y ti ní ètò ìtọ́jú tó péye fún aláboyún àti ọmọ-oyún-inú; bíbí tí a bá bí ọmọ náà, ìyà kò lè jẹẹ́, nítorí àwọn òbí rẹ̀ ní’ṣẹ́ lọ́wọ́ tí wọ́n sì ngba owó gidi tàbí wọ́n nṣe-òwò tí owó láti ṣòwò sì wà ní àrọ́wọ́to látàrí ètò ẹ̀yáwó tí kò ní èlé nínú.
Bí ọmọ bá ti bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé, títí dé àkọ́kọ́-gboyè ní fásitì, ọ̀fẹ́ ni; bí ó fẹ́ kà jùbẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yáwó tí kò ní èlé wà fun. Ibikíbi tí ènìyàn bá ńlọ ní ìgbà-kú’gbà, ààbò wa, nítorí a máa padà sí ohun ìgbé-ayé rere gbogbo èyí tí wọ́n fi jẹ́ri nígbà-náà lọ́hun pé kò sí olè ní àwùjọ wa. Oníkálùkù á rí ṣe, kò ní sí pé ẹnìkan ló fẹ́ fi ọmọ-ènìyàn ẹgbẹ́-rẹ̀ ṣe ohun aburú.
Kí ọmọ ó tó pé ọdún mọ́kànlélógún, ó ti mọ̀ pé ijọ́ tí òun bá pé iye-ọdún yẹn, ilẹ̀-ilé ti wà fún òun lọ́fẹ, tí kíkọ́ ilé náà á sì rọrùn nítorí ìrànlọ́wọ́ tí D.R.Y máa ràn-án lọ́wọ́, yàtọ̀ sí pé ọ̀fẹ́ ni ilẹ̀.
Arúgbó á ní ìtọ́jú nígbà gbogbo, kò sí ohunkóhun tí ó máa dẹ́rù-bani títí di ọjọ́ ìkẹyìn. Ìdí nìyí tí Màmá wa MOA fi sọ pé kí á ṣáà máa dúpẹ́ títí òpin ayé, lọ́wọ́ Olódùmarè. Láarọ̀, lọ́san, lálẹ́, ọkàn I.Y.P máa máa balẹ̀ ni lójoojúmọ́ ní D.R.Y, kò sí ìfòyà, a rí iṣẹ́ ṣe, a rí owó ná, ààbò tó péye wà, lórí ẹ̀mí àti lórí dúkìá.