Káàkiri àgbáyé ni wọn yóò ti mọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè àrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ àwọn ohun àrà-meèrírí tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè wa.

Ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèje, ni a óò ti máa rí ìdàgbàsókè jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé,àwa ni ògo adúláwọ̀. Olódùmarè sì fún wa ní àwọn àlùmọ́ọ́nì lorísìírísìí tí orílẹ̀ èdè míràn ní àgbáyé kò ní ìdá kan rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ wípé, àwa ni a ó pèsè ohun tí a nílò, ohun tí a bá sì pèsè ni a óò máa lò.

Gbogbo ohun tí a nílò fún iná mọ̀nà-mọ́ná tí kò ní sẹ́’jú wà ní àrọ́wọ́tó wa, ọ̀nà tó já geere tí yóò sì wà fún àìmọye ọdún, ohun tí a ó fi ṣe, orí ilẹ̀ Yorùbá ló wà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Gbogbo àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèké ni yóò ní ìdàgbàsókè pẹ̀lú àwọn ohun am’áyédẹrùn ti ìgbàlódé. Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a fi ìmọ̀ ṣọ̀kan, ọ̀kan ṣoṣo ni wá, kí a ní ìfẹ́ ara wa, kí a sì máa fi òtítọ́ ṣe ohun gbogbo nítorí pé òtítọ́ níí gbé orílẹ̀ èdè lékè.