Màmá wa Modupẹọla Onitiri Abiọla (Olóyè, Ìyá ààfin) bá àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá sọ̀rọ̀ láìpẹ́ yìí. Wọ́n jẹ́ ká mọ rírì òmìnira orílẹ̀ èdè wa fún ìrọ̀rùn àwa ọmọ aládé.
Lára àwọn èètò tí Olódùmarè jogún fún ìran Yorùbá nípasẹ̀ Màmá wa Modupẹọla Onitiri Abiọla (Olóyè, Ìyá ààfin) ni pé àwọn I.Y.P tó bá nífẹ sí òwò ṣíṣe ní ànfàní láti ọ̀dọ̀ àwọn alákóso orílẹ̀ èdè wa, D.R.Y, láti ní ìbùṣọ̀ láti tajà, tí ó bá wu wọ́n bẹ́ẹ̀, àti pẹ̀lú bí ìlànà gbígba ibùsọ̀ náà bá ṣe máa jẹ́. Bí ọjà tí a fẹ́ tà bá ṣe rí, ni ó máa sọ bíi títóbi ìbùṣọ̀ náà ṣe máa rí.
I.Y.P tó bá fẹ́ ìrànwọ́ owó láti ọ̀dọ̀ àwọn alákoso wa láti ṣe okoòwò tí a fẹ́, yíò ní ẹ̀tọ́ sí ẹ̀yáwó tí kò ní èlé, níwọ̀n ìgbà tí a bá jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, IYP.
Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ilé-ìtajà wa máa wà ní mímọ́ pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn olùtajà tó wà ní agbègbè kan náà, tí owó-sísan fún ìmọ́tótó agbègbè ìtajà á jẹ́ ọlọ́dọọdún; ẹni tí ó bá fẹ́ san-an lẹ́ẹ̀méjì, ní díẹ̀-díẹ̀, lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìmọ́tótó ìbùsọ̀ kọ̀ọ̀kan á wá jẹ́ iṣẹ́ ti ẹni tó ni ṣọ́ọ̀bù fúnrarẹ̀.
Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí ó máa yá iwájú ṣọ́ọ̀bù ẹlòmíì máa tajà tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹni tó nlé mọ́tò kiri ojú-pópó láti tajà. Orílẹ̀-èdè D.R.Y kò sì ní lajú sílẹ̀ kí I.Y.P kankan kó jìyà, torí ẹ̀tọ́ wà fún àwọn I.Y.P oníṣòwò.
Tí agbègbè ọjà wa bá wà ní mímọ́, tí a ṣì to àwọn ọjà wa ní ọ̀nà tí ó fanimọ́ra, a ò nílò láti máa ṣe òògùn àwúre kí á tó rí ọjà wa tà. Ìwà ọmọlúàbí wa l’ọba àwúre.
Ọmọ aládé yóò padà sínú ọlá, ọlà àti ọrọ̀ tí ẹlẹ́dàá jogún fún àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, I.Y.P, tí a bá tẹ̀lẹ́ àwọn àlàkalẹ̀ èètò fún ìran Yorùbá nípasẹ̀ Màmá wa, MOA.
Lẹ́hìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ á tàn