Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tí a óò jẹ ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ni pé ibi tó bá wu oníkálukú ló le gbé ní ilẹ̀ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla bá wa sọ láìpẹ́ yí wípé, kò sí ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan ṣoṣo ni wá.
Ẹnìkan lè jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn, ó lè sọ pé ìpínlẹ̀ Oǹdó ni ó wu òun láti máa gbé. Kò sí ohun tó burú níbẹ̀, nítorí pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa. Kò sí ohun tó ń jẹ́ ọmọ Èkìtì tàbí ọmọ Ìjẹ̀bú, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), ọmọ Yorùbá ni wá.
Níwọ̀n ìgbà tí a ti jẹ́ Orílẹ̀ èdè, tí a ní èdè kan, àṣà kan, ìtàn kan àti ilẹ̀ àjogúnbá kan, gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ti so wá papọ̀ a sì ti di ìkan ṣoṣo.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán màmá wa MOA ìyá ìrọ̀rùn lóbádé láti gbà wá kúrò nínú oko ẹrú, tí wọ́n sì jẹ́ kí á mọ̀ wípé àwa ọmọ Yorùbá la ni ilẹ̀ Yorùbá.
Àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí yóò mú ìgbé ayé rọrùn fún wa ní Olódùmarè gbé fún Màmá wa. A kú oríire, gbogbo àwa ọmọ Yorùbá.