Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ni a ó ní iṣẹ́ lọ́wọ́ nítorí pé iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, ẹ̀dá tí kò bá sì ṣe iṣẹ́ ní àkókò tó yẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò padà ṣíṣẹ̀ẹ́.

Gbogbo ìgbà náà ni màmá wa, ìyá ìran Yorùbá ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla máa ń sọ wípé, a máa ṣe iṣẹ́ gidi nítorí pé kò sí ohunkóhun nílẹ̀ mọ́.

Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa tí wọ́n ti wà nílé fún àìmọye ọdún tí wọn ò rí iṣẹ́ ṣe, a kí yín kú oríire. Ìgbà ọ̀tun ti dé, kò sí àìríṣẹ́ mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Ẹ̀ka tí oníkálukú bá ti kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò ti ṣe iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí ojúṣàájú, gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ìrẹ́jẹ nínú ètò ìgbaniṣíṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Ní kété tí àwọn alámòójútó wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa, ní ìpínlẹ̀ méjèèje, oríṣiríṣi iṣẹ́ tí oníkálùkù wa yàn láàyò ni a ó ma ṣe. Fún àpẹẹrẹ, iṣẹ́ àgbẹ̀, apẹja, agbẹ́gilére, òwò ṣíṣe, onímọ̀ ẹ̀rọ, ẹ̀ṣọ́ aláábò, olùkọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Kò sí ìyà fún ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) mọ́, kí a máa gbádùn ló kù.

ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀

Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́. Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.