ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, ÀWÁMÁRIDÍ, NÍSIÌYÍ, BA GBOGBO OHUN-IBI JẸ́, PÁTÁPÁTÁ; GBOGBO MÁJẸ̀MÚ ÌRÁNṢẸ́-ẸNI-IBI, ÀṢÌTÁÁNÌ, GBOGBO ÌLÉRÍ, ÈTÒ, ÈTE, ÀTI ÈRÒ TÍ Ó LÒDÌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ. NÍ AGBÁRA TÍ ỌLỌ́RUN FI NJẸ́ ÈMI-NI, KÍ ÌPARUN NÁÀ ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ YORÙBÁ WỌ̀NYÍ, LỌ́WỌ́LỌ́WỌ́ BÁYI

OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA, TÍ Ó NÍ IPÁ; OLÓDÙMARÈ TÍ Ó NÍ IPÁ LÓJÚ OGUN, ỌLỌ́RUN ÀWỌN ỌMỌ-OGUN, ṢE ÌPARUN PÁTÁPÁTÁ, NÍSIÌYÍ, FÚN ÀṢẸ, AGBÁRA ÀTI IPÒ TÍ WỌ́N NLÒ LÁTI JẸGÀBA LÓRÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ, ÌRAN YORÙBÁ, ILẸ̀ YORÙBÁ, ÌṢÈJỌBA YORÙBÁ, AGBÈGBÈ-ÀJOGÚNBÁ YORÙBÁ.

ṢE ÌPARUN FÚN GBOGBO ÌWÀ ÌDÚKOKÒ, ÌJẸGÀBA, DÍDẸ́RÙBANI, ÌHÀLẸ̀, ÌGBÓGUN-TINI, TÍ WỌ́N DOJÚKỌ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀-YORÙBÁ, TI ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA TIWANTIWA TI YORÙBÁ

Gbà ọ̀tun ti wọlé dé o gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y),gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ní kété tí àwọn ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń f’ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa bá ti kúrò pẹ̀lú ìtìjú àti ìpayínkeke,ní ohun gbogbo yóò gba àyípadà ọ̀tun, bẹ̀rẹ̀ láti  ìwa wa, ìjẹ́un wa, ìwọ’ṣọ wa, àti ìgbésí ayé wa lápapọ̀.

No to LGBTQ in Yorubaland | No to Vaccines in the Democratic Republic of the Yoruba

Gẹ́gẹ́ bí màmá wá Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, tí Olódùmarè lò fún òmìnira àwa ìran Yorùbá ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí bí àwa ìran Yorùbá ṣe jẹ́ gan-an láì sí àmúlùmálà rárá. Màmá sọ fún wa nípa ètò ìwòsàn wípé, a ó máa ló ìlànà àwọn babańlá wa láti ṣe ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn,ìmúra àti ìw’ọṣọ wa yóò jẹ́ ti ìlànà ìbílẹ̀ Yorùbá. 

Èdè Yorùbá ni a ó máa sọ ní ilé- ẹ̀kọ́, ní ilé – iṣẹ́ àti níbi gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, àwọn oúnjẹ wa tí ó ti di ohun ìgbàgbé a ó padà sí bí a tií ṣeé tẹ́lẹ̀, a óò padà sí ìwà ọmọlúwàbí wa bakanna, nítorí pé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè gbà ìwà tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ́ àti ìyà yóò di àfìsẹ́yìn tí eégún ńf’iṣọ.