Orílẹ̀ èdè tó bá ti sọ èdè rẹ̀ nú yóò parun, ká dúpẹ́ fún Olódùmarè tí ò jẹ́ kí ìran Yorùbá parun. Títí láé ni àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán ẹni bí ọkàn Rẹ̀ sí wa, màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti mọ ìtúmọ̀ èdè tí ò lẹ́̀ kí ìran wa parun.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Yorùbá tó sọ pé odò tó bá gbàgbé orísun rẹ̀ gbígbẹ ní yóò gbẹ. Adúpẹ́ fún Ọlọ́run Olódùmarè tí kò jẹ́ kí Yorùbá di ohun ìtàn.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń ṣọ wípé, ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), èdè Yorùbá ni a óò máa sọ ní ilé iṣẹ́, ilé ẹ̀kọ́ àti gbogbo ibi ní ilẹ̀ Yorùbá.
Láti kékeré ni a óò tí máa kọ́ àwọn ọmọ wa ní èdè abínibí wa ní ohun gbogbo tí a bá ń kọ́ wọn. Ìgbọ́ra ẹni yé yóò wà láàrin àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nígbà tí a bá ń bá ara wa sọ̀rọ̀ ní èdè Yorùbá, èyí yóò fún èdè wa ní ìwúrí àti iyì káàkiri àgbáyé.
Tẹni-ń-tẹni, ohun aní là ńgbé lárugẹ. Ọmọ Yorùbá ṣe àpọ́nlé èdè re kí o sì gbe lárugẹ.
ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀
Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́. Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.
Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.