Lára àwọn ànfààní tí a ma jẹ ní Orílẹ̀-Èdé Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ni pé àparò kan kò ní ga jù’kan lọ.

Ẹ̀tọ́ kan-náà ni gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá máa ní lábẹ́ òfin àfi ẹni tí ìdílé ẹ̀ bá ti dalẹ̀ ÌRAN YORÙBÁ.

Kò sí pé ẹnìkan ni ọmọ Olówó tàbí bọ̀rọ̀kìní, tí á wá tìtorí èyí rí àwọn ànfààní kan jẹ ju ẹlòmíràn lọ!

Irú nkan tí ó wà fún ẹnìkan náà ni ó wà fún ẹni-kéjì – ó wá kù bí olúkúlùkù ṣe fẹ́ẹ́ lo ànfààní tiẹ̀!

Ohunkóhun tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ni àyè wà fún láti rí ìrànlọ́wọ́ láti orílẹ̀-èdè wa – gẹ́gẹ́bí àpẹẹrẹ, ẹ̀yáwó tí kò ní èlé lórí, níwọ̀n-ìgbà tí o bá ti jẹ́ I.Y.P.

Kò níí sí ẹni tí kò ní rí-jẹ, tí kò bá ti ya ọ̀lẹ!

Ọmọ tó ní ẹ̀bun rere láti lò, kò ní sọ pé àìlówó-lọ́wọ́ bàbá òun ni kò jẹ́ kí òun rí ẹ̀bùn náà lò!

Àdáìdátán ni ọpẹ́ wa yíò máa jẹ́, níwájú OLÓDÙMARÈ, àti fún Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí Wọ́n yàn, tí àwọn náà sì jẹ́ iṣẹ́ Ìgbàlà Yí fún Ìran-Yorùbá!

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ẹyẹ tó fi ara rẹ̀ wé igún, ẹ̀yìn ààrò ló máa sùn

AKÍ GBOGBO I.Y.P TI D.R.Y NÍ ÌLÚ AMẸ́RÍKÀ 

WÍPÉ Ẹ KÚ ỌDÚN ỌPẸ́ TẸ́ NṢE LÓNI!