À ò ní ṣe aláìdúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún oore ńlá tó ṣe fún àwa ìran Yorùbá, nítorí ìfẹ́ Tó ní sí wa,ìdí nìyí Tó fi rán ẹni bí ọkàn Rẹ̀ sí wa, màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) láti dá gbogbo ìkólọ wa padà,àti láti mú ìgbé ayé ìrọ̀rùn bá

 gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ni yóò rí ògo wọn lò, nítorí pé ògo pọ̀ lára wọn gidigidi.

Màmá sọ pé àwọn ọ̀dọ́ ní àtìlẹ́yìn láti ṣe àkóso ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlòmíràn lè gbìyànjú láti gbé’gbá ìbò.

Modupeola Onitiri-Abiola Blueprint for Yoruba

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò rí iṣẹ́ tó dára lẹ́yìn tí wọ́n bá kà’wé tán, gbogbo wọn ni yóò ní oore ọ̀fẹ́ sí ètò ẹ̀kọ́ tó kún ojú òṣùwọ̀n, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ti di jàǹdùkú sí ìgbòro nípasẹ̀ àìríṣẹ́ ṣe ni D.R.Y ní ètò fún tí ayé wọn yóò sì gba àyípadà ọ̀tun.

Lára rẹ̀ náà ni ilẹ̀ ọ̀fẹ́ fún gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ní kété tí wọ́n bá ti pé ọdún mọ́kànlélógún, tí D.R.Y yóò sì tún ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn láti ríi pé kíkọ́ ilé sí orí ilẹ̀ náà kò mú ìnira dání fún wọn.

Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa, ẹ jẹ́ kí a fọwọ́sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alákòóso wa, kí a leè bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ìgbádùn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wá MOA lọ́wọ́ fún àwa Ìran Yorùbá.

Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y)

Orúkọ tí a bá sọ ajá ẹni lọmọ aráyé ńbá ni í pèé