Ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ọ̀kan-ò-j’ọ̀kan ni àwọn ètò ìgb’áyé gbádùn tó wà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin), fún ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìgbé ayé ìrọ̀rùn àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá tí orílẹ̀-èdè D.R.Y.
Lára wọn ni ètò fún àwọn òṣìṣẹ́, gbogbo òṣìṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y ni yóò jẹ àǹfààní ètò tó ti wà nílẹ̀ lorísìírísìí.
Kìí tún wá ṣe fún àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá nìkan, àwọn àjòjì pàápàá yóò jẹ́ nínú àwọn àǹfààní yí, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ kan, tí o sì ń gbé ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ fún wa, inú àwọn òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ máa dùn ni, kìí ṣe pé kí wọ́n máa fi Ìbànújẹ́ ṣe iṣẹ́, nítorí náà, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni wọn yóò máa gba owó ọ̀yà wọn, ilé iṣẹ́ kankan kò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lówó.
Àwọn agba’ṣẹ́ṣe sì gbọ́dọ̀ pèsè ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ yóò ti máa simi ní ẹnu iṣẹ́, nítorí pé kò sí iṣẹ́ àṣekú ní D.R.Y.
Gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, o gbọ́dọ̀ máa ní àkókò ìsinmi ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀kan sí ẹ̀ẹ̀méjì láàárín ọdún kan láti sinmi pẹ̀lú àwọn ẹbí wa, àti láti tún ara wa se.
Èyí yóò tún fún wa ní àǹfààní láti rin ìrìn àjò lọ sí ibi tí ó bá wù wá láàárín orílẹ̀ èdè D.R.Y. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àṣeyọrí iṣẹ́ náà tó rán màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin).
Àkókò ọpẹ́ ni a wà yí, kí a máa dúpẹ́ lójoojúmọ́ fún àánú tí a rí gbà, Olódùmarè ti bá wa ṣé, kò sí ohunkóhun tó leè yí padà.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Lẹ́hìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ á tàn