A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àánú rẹ̀ lórí ayé ìran Yorùbá, Tó dá ìgbà ọ̀tun padà fún àwa ọmọ Aládé nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla Tó fi iṣẹ́ náà rán sí àwa ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ètò tó fi ti Yorùbá ṣe àkọ́kọ́ lẹ́yìn Olódùmarè tó sì kún fún ìgbá’yé gbá’dùn lorísìírísìí.

Ṣé láìpẹ́ yí tí màmá wa MOA bá àwa ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀ ni wọ́n tún sọ fún wa wípé, ètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti wà nílẹ̀ fún àwọn arúgbó wa bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin, ṣùgbọ́n fún ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) nìkan ni ò. 

Kí gbogbo ẹ̀yin arúgbó wa máa jẹ ìgbádùn lọ lókù, kò sí ogun àìríjẹ mọ́ fún àwọn arúgbó wa, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò máa gba ìtọ́jú tó péyé ní ẹ̀ka ti ètò ìlera lọ́fẹ̀ẹ́. 

Níwọ̀n ìgbà tí o bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí o sì ti pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin a kí wa kú oríire. Ṣé a ò gbàgbé wípé, kò sí ojú ṣáájú ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ìlú tí oníkálukú bá wà ní yóò ti máa gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nítorí pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa. 

Ẹ ò nílò láti mọ ẹnikẹ́ni kí ẹ̀tọ́ yín tó tẹ̀ yín lọ́wọ́. 

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú wa, kí a sì ríi dájú pé a ò ṣe ohunkóhun tó lòdì sí òfin Orílẹ̀ èdè D.R.Y kí a má bàa pàdánù àwọn ẹ̀tọ́ tí a ní gẹ́gẹ́ bíi ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), kí a sì máa ṣe òtítọ́ nínú ohun gbogbo nítorí pé òtítọ́ níí gbé orílẹ̀ èdè lékè.