Gbogbo àwa I.Y.P yóò ma dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) fún òmìnira orílẹ̀ èdè wa D.R.Y. 

Àyípadà ọ̀tun ti de bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa MOA lọ́wọ́.

Ètò Ẹ̀yáwó tí kò ní èlé lórí yóò wà fún èyíkéyìí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí ó bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti ṣòwò, dá iṣẹ́ sílẹ̀, àti bẹẹ bẹẹ lọ. 

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wa nípasẹ̀ wọn yí, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé. Àfi èyí tó bá fi ara pẹ́ẹ, ó kàn fi ara pẹ́ẹ ni, kò jọọ́ rárá.

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí oníkálukú wa máa ronú ohun tí a fẹ ṣe ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèje tó wà ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.

Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí, gbogbo ìgbà náà ni màmá wa MOA máa ń sọ wípé a ò ní rìn, bẹ́ẹ̀ sì ni a ò sí ní sáré, a máa fò ni, nítorí kò sí nkankan nílẹ̀ mọ́. Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn àwọn àlàkalẹ̀ ètò loríṣìíríṣìí tí Olódùmarè ní fún wa.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.

A kì í s’òótọ́ inú, kí ọ̀rọ̀ ẹni má d’ayọ̀, b’áyé ẹni bá dojúrú ìwà èèyàn ló yẹ ká wò