Títí láé, ìran Yorùbá kò ní gbàgbé oore tí Olódùmarè ṣe fún wa, nípasẹ̀ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin). Gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ màmá wa MOA fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe fún ìran Yorùbá.
Nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún MOA, ìgbádùn lorísìírísìí ló wà fún gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (IYP), àti pé àlàkalẹ̀ náà yóò dá wa padà sí orírun wa ni. Bí ìran Yorùbá ṣe ń ṣe láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni a ó padà sí, nínú ìwà àti nínú ìṣe, èyí tí èdè wa jẹ́ ọ̀kan gbòógì.
Gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ fún wa, èdè Yorùbá nìkan ni a óò máa sọ ní ilé-ẹ̀kọ́, a ò ní lo èdè míràn láti kọ́ àwọn ọmọ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ wa, èyí yóò mú kí ẹ̀kọ́ náà ó yé wọn dáadáa, nítorí pé èdè àwọn babańlá wa ni èdè Yorùbá, ìdánimọ̀ wa sì nìyẹn, tí a kò sì gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú.
Kòsí ààyè fún àmúlùmálà èdè ní D.R.Y, Yorùbá pọ́ńbélé ni, ìdí nìyí tí MOA fi sọ fún ẹ̀yin òbí tí ẹ ti yọ ọmọ yín kúrò ní ilé ìwé wípé, kí ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ náà lọ máa kọ́ Yorùbá, nítorí tí ètò ẹ̀kọ́ D.R.Y bá bẹ̀rẹ̀, èdè Yorùbá pọ́ńbélé ni wọn yóò máa fi kọ́ ẹ̀kọ́ ní ilé ìwé.
Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí àwa òbí máa fi yé àwọn ọmọ wa, ìdí tí sísọ èdè Yorùbá fi jẹ́ dandan, tí wọn kò sì gbọ́dọ̀ fi ojú rénà rẹ̀ ní àkókò yí.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Ẹni tí a ńwò kì í wò’ran