Àwòkọ́ṣe gidi ní ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) yíó jẹ́, nítorí àrà ọ̀to tí kò fara jọ t’ẹnìkan ni àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla (Olóye Ìyá-Ààfin) lọ́wọ́ fún ìgbáyé-gbádùn àwa ọmọ Aládé.
Màmá wa, òrìṣà òmìnira ilẹ̀ Yorùbá, ti sọ pé àlàkalẹ̀ wa fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé gẹ́gẹ́bí òwò ṣíṣe ni ìṣàkóso D.R.Y máa jẹ́.
Nítorínáà àyè ìkówójẹ kò sí, yálà láti ọwọ́ òṣìṣẹ́ ìlú tàbí àwọn aṣàkóso. Oníkálukú ló máa jábọ̀ iṣẹ́ ìríjú wọn fún àwa ará ìlú.
A sì tún ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún àlàyé lórí àbọ̀ tí wọ́n bá jẹ́ fún wa. Ànfàní nlá rèé fún wa ní orílẹ̀ èdè wa.
Màmá wa, MOA, tẹ̀síwájú pé orílẹ̀ èdè wa níláti máa ṣe àṣejèrè ni, a kò gbọdọ̀ pàdánù, nítorípé a kò ní yá owó rárá, a kò ní lọ sí oko-ẹrú gbèsè.
Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ni yíó ma wa yá owó lọ́wọ́ ilẹ̀ Yorùbá nítorí a ó ní àjẹṣẹ́kù lọ́pọ̀lọpọ̀.
Ní àfikún, kò ní sí ohun tó njẹ́ olóṣèlú ní D.R.Y, gbogbo ẹnití ó bá máa wà nínú ìṣàkóso ilẹ̀ wa gbọ́dọ̀ ní iṣẹ́ ti ara wọn. Kò sì ní sí owó oṣù fún àwọn aṣojú. Owó ìjóko ni wọn á gbà.
Ètò sì tún wà fún yíyan ni sí ipò. Kò sí àyè akọ̀wé fún akọ̀wé, tàbí olùdámọ̀ràn fún àwọn akòwé àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Bàkannáà, baba ìsàlẹ̀ kò sí fún ẹnití ó bá fẹ́ díje fún ipò. Kò sì gbọdọ̀ pín tàbí ná owó ní ọ̀nà àìtọ́; àìjẹ́bẹ́ẹ̀, idà òfin máa ba òndíje náà. Gbogbo èyí á bẹ́’gi dínà ìkówójẹ àti níná owó ìlú lọ́nà àìtọ́.
Gbogbo àwọn ètò yí á dè’nà àìṣòótọ́ ní ìnáwó, yíó sì jẹ́ kí ìdàgbàsókè tó péye bá orílẹ̀ èdè wa ní kíákíá; àwa ará ìlú náà yíó sì lè jẹ ìgbádùn ilẹ̀ wa.
Ọpẹ́ ni fún Olódùmarè tó rán ìránṣẹ́ Rẹ̀, màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá Ààfin), fún ìgbàlà àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti D.R.Y.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).