Láti ìgbà ìwásẹ̀ ni Olódùmarè ti fi ewé àti egbò kẹ́ àwa ìran Yorùbá. Lóríṣiríṣi ọ̀nà ni ewé àti egbò ń gbà ṣe àǹfààní fún ara àti àyíká wa.
Ní jíjẹ, àǹfààní ńlá-nlà ni óún ṣe fún ara, ó ṣe iyebíye fún ìwòsàn, ó mú àyíká rẹwà, óún fẹ́ afẹ́fẹ́ àlááfíà sí ara. Bẹ́ẹ̀ni ẹgbò rẹ̀ pẹ̀lú ní iṣẹ́ pàtàkì tó ńṣe ní àgọ́ ara.
Adẹ́da dá ewé àti egbò sí àyíká wa lati ṣe wá lóore.
Gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ní ẹsẹsẹ, ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá ṣàlàyé rẹ̀ fún wa ní ìgbà-dé-ìgbà, wípé a ma bẹ̀rẹ̀ sí ńlo ewé àti egbò fún ìwúlò rẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe sọ fún wa, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ní àgbáyé ló jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwa ìran Yorùbá ni wọ́n ti máa ní ìwòsàn sí ń kan tí wọn kò rí ojútu rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá! A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Elédùmarè tí ó fi Ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe atọ́nà fún wa.
Tó bá kù díẹ̀ kí ọmọ olóore jìn sí kòtò, mànàmáná á ṣiṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún un