Ààbò ṣe kókó ó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ ohun tí a kò gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nítorí wípé, kò sì ohunkóhun tí ènìyàn leè ṣe nínú ìbẹ̀rù àti àìbalẹ̀ ọkàn. Èyí jẹ́ ohun gbòógì fún ìṣàkóso tó bá fẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè rẹ̀, kí ó rí ọ̀rọ̀ ààbò gẹ́gẹ́ bíi ohun àkọ́kọ́ nínú ètò ìṣàkóso rẹ̀ tí ó sì gba àmójútó gidigidi.
Ẹ̀tò ààbò tó dájú jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wá, ìyá ààfin modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá lọ́wọ́, èyí tí yóò mú ọkàn gbogbo wa bálẹ̀ lórí ilẹ̀ àjogúnbá wa.
Àwọn àgbẹ̀ wa yóò leè máa lọ sí oko wọ́n pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, tí kò ní sí ìbẹ̀rù àwọn ajínigbé, àwọn arìnrìn-àjò yóò leè lọ síbi tó bá wù wọ́n ní àkókò tí wọ́n fẹ́, láìsí ìfòyà àwọn alọnilọ́wọ́gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìbẹ̀rù lórí àwọn dúkìá wa gbogbo.
Bákan náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí yóò máa wo ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn yóò wà tọ̀sán-tòru, àti wípé, káàkiri orilẹ́ èdè wa ni yóò ní ohun èlò ìyàwòrán, dé bi pé, abẹ́rẹ́ tó kéré jù kò leè jábọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò kò ní mọ̀ ní orí ilẹ̀ wa.
Ààbò tó péye yóò wà ní orílẹ̀ èdè wa D.R.Y.