Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fún ìran Yorùbá láti gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni.
Lára àwọn àlàkalẹ̀ ètò yí ni ààbò fún ẹ̀mí àti dúkìá wà, nítorí ètò ààbò ṣe pàtàkì púpọ̀ láwùjọ. Àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò sì ní fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ ètò ààbò yí rárá.
Agbésùnmọ̀mí kò lè rí ààyè ní orílẹ̀ èdè wa, nítorí gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe sọ fún wa, a máa mọ odi yí t’ìbú t’òró ilẹ̀ Yorùbá ká ní.
Kò sí ìfòyà fún gbogbo olùgbé orílẹ̀ èdè D.R.Y, ètò ààbò tó péyé ti wà nílẹ̀ fún wa àti fún àwọn ohun ìní wa gbogbo. Kò ní sí olè tàbí jàǹdùkú nítorí pé, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ló máa ní iṣẹ́ lọ́wọ́.
Ìgbà tó bá wu ẹnikẹ́ni ló lè rìn ní ojú pópó láìsí ìbẹ̀rù àwọn ajínigbé tàbí agbébọn, àwọn igbó tó bá wà láàárín ìlú kan sí òmíràn, àwọn aṣojú D.R.Y yóò ríi dájú pé kìí ṣe ibi tí àwọn amòkùnṣèkà lè fi ara pamọ́ sí.
Kò sí ìbẹ̀rù fún wa, Olódùmarè ti bá wa ṣe. Ẹ jẹ́ kí a máa múrasílẹ̀ fún àjọyọ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà, ayọ̀ ni ti gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y.