Ọlọ́run Olódùmarè ti bá wa gba ìjẹ́ orílẹ̀-èdè wa padà ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún nípasẹ̀ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) tí Olódùmarè lò láti gba ìran Yorùbá kúrò nínú ìparun.
Ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni kí ìran Yorùbá padà sílé, tó wá gbé olùrànlọ́wọ́ dìde fún wa pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ètò tó kún fún oríṣiríṣi ìgbádùn àti láti dá wa padà sí orírun wa
Ìgbà ọ̀tun ti wọlé dé fún àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ní kété tí àwọn ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń f’ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa bá ti kúrò pẹ̀lú ìtìjú àti àbùkù,ní ohun gbogbo yóò gba àyípadà ọ̀tun, bẹ̀rẹ̀ láti ìwa wa, ìjẹ́un wa, àti ìgbésí ayé wa lápapọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wá Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ fún Ìran Yorùbá yóò dá wa padà sí bí àwa ìran Yorùbá ṣe jẹ́ gan-an láìsí àmúlùmálà rárá. MOA sọ nípa ètò ìwòsàn wípé, a ó máa ṣe ìgbélárugẹ ìlànà àwọn babańlá wa láti ṣe ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn.
Èdè Yorùbá ni a ó máa sọ ní ilé- ẹ̀kọ́, ní ilé – iṣẹ́ àti níbi gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, àwọn oúnjẹ wa tí ó ti di ohun ìgbàgbé a ó padà sí bí a tií ṣeé tẹ́lẹ̀, a óò padà sí ìwà ọmọlúwàbí wa bakanna èyí tí gbogbo àgbáyé mọ ìran Yorùbá mọ́ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè gbà ìwà tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ́ àti ìyà yóò di àfìsẹ́yìn tí eégún ńf’iṣọ.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y)