Ní gbogbo ìgbà ni àwa ìran Yorùbá yóò máa fi ọkàn ìmoore wa hàn sí Ọlọ́run Olódùmarè fún ìyanu ńlá tó ṣe fún wa nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè fi iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Aládé rán.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè fún wọn yóò dá wa padà sí orísun wa, àti wípé àlàkalẹ̀ ètò náà kún fún oríṣiríṣi ìgbádùn fún àgbà àti èwe.
Lára àwọn àyípadà ọ̀tun tí yóò dé bá awa ìran Yorùbá ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa ní ìpínlẹ̀ Méjèèje orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ni pé, a ó ò gbé àṣà aṣọ ìbílẹ̀ wa lárugẹ. Ìró, bùbá, gèlè, ìpèlé, agbádá, ṣọ́ọ́rọ́, kẹ̀mbẹ̀, fìlà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, bí t’ọkùnrin ṣe wa náa ni t’obìnrin wà.
Ọ̀kan lára ọ̀nà tí a máa fi ń dá ọmọ Yorùbà mọ̀ ni nípa ìmúra-Yorùbá rẹ̀, nítorí náà, ìdánimọ̀ ni aṣọ wíwọ̀ jẹ́ a kò sì gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú u.
Aṣọ ìbílẹ̀ Yorùbá ní ẹwà púpọ̀, nígbàkúùgbà tí a bá wọ̀ ọ́, ó máa ń gbé ẹwà àti ògo Olódùmarè jáde lára wa.
Ìṣọwọ́ wọṣọ wa gẹ́gẹ́bí Yorùbá máa nbu Iyì kún wa púpọ̀, bí ó ṣe wà ní ti àwọn ọkùnrin náà ló wà ní àwọn obìnrin.
Nítorí náà gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìgbà ọ̀tun ti dé tí a ó máa rí ògo àti ẹ̀wà aṣọ ìbílẹ̀ wa.