Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) kò sí àyè fún ìwà ìbàjẹ́, nítorí àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè fún màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla kò fi àyè sílẹ̀ fún ìwà ìbàjẹ́ kankan.
Àwọn ará ìlú yóò mọ kíni òfin sọ, èyí yóò mú kí oníkálukú mọ ẹ̀tọ́ àti ojúṣe rẹ̀ sí ìjọba àti sí ọmọnìkejì,bẹ́ẹ̀ sì ni ìjọba náà yóò b’ọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ará ìlú.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń ṣọ wípé, àparò kan kò ní ga jù’kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá,àti pé, ẹnikẹ́ni nínú ètò ìsèjọba tó bá da ọwọ́ rú, aó da ẹsẹ̀ rẹ̀ rú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Èyí yóò mú kí oníkálukú mọ̀ pé àrà ọ̀tọ̀ ni ìsèjọba orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Ẹnìkan kò ṣe pàtàkì ju ẹlòmíràn lọ, kò sí ojú sàájú, kò sí àyè fún rìbá,àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.