• Oríkò Ilé-Iṣẹ́ Alákóso, Agodi, Ìpínlè Ìbàdàn (Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ látijọ), D.R.Y

Ọ̀dọ́ àti Eré-Ìdá’rayá

Ọ̀dọ́ àti Eré-Ìdá'rayá

Àwọn ọ̀dọ́ ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá. Ìjọba Yorùbá, ìjọba tí ó jẹ́ wípé àwọn ọ̀dọ́ ni Aṣ’ojú Ìjọba ni. Àwọn ọ̀dọ́ wa gb’ọdọ̀ gbé ìgbé ayé tí ogo wọn máa fi bú’yọ ní ìgbà gbogbo títí láí ni.

Ètò eré ìdá’rayá ni Orílẹ̀-Edè Yorùbá sì gbé l’arugẹ́, nít’orí àwọn ọ̀dọ́ wa ní pàtàkì níl’ati wà ní ìlera ara àti ọkàn ní ìgbà gbogbo.

Ètò eré ìdá'rayá
l'oríṣiríṣi

Ìmúrasílẹ̀ fun gbígba ìfé ẹyẹ àgbáyé

Awọn eto ìdàgbàsókè ere-ìdárayá fun àwọn ọdọ ti yio ma mu ìdàgbàsókè ba gbogbo orílẹ̀ èdè Yoruba. Àwọn eto wọnyi le ni ipa rere lori awọn eniyan kọọkan ati agbegbe nipasẹ igbega ìlera, àlàáfíà, ati ìdàgbàsókè eto-ọrọ ajé. Awọn eto wọnyi pẹlu eto-ẹkọ, ikẹkọ, idamọran fun àwọn ọdọ ti wọn ni’fẹ si ere ìdárayá.

Ìjọba ti ṣe ètò lorisirisi silẹ fun gbogbo ọdọ ilẹ Yorùbá ti wọn nifẹ si ere ìdárayá.

Àgbékalẹ̀ ẹtọ ìṣejọba ti Olómìnira tiwantiwa tí a mọ sí Blueprint ti Olódùmarè fúnra rẹ gbe fun mama wa Modupeola Onitiri-Abiola, ni ko yọ ọmọdé tàbí àgbà silẹ nipapajulọ, eyi to niṣe lori ọrọ ìdárayá.

Erońgba wa ni láti múra sílẹ̀ fun àwọn ere ìdárayá ti o ma n wáyé lọdọọdún káàkiri àgbáyé láti ja’we olubori, láti gba ife ẹyẹ, ati láti fihàn fún gbogbo àgbáyé pé Ọmọ-Aládé ni awa ọmọ orílẹ èdè Yorùbá. Orí ni wa, así gbọdọ je ki àgbáyé mọ!

Ìwọ ti o ba ni’fẹ si ere ìdárayá, f’ọkàn balẹ, ko sí oju ìṣáájú ni orílẹ èdè ti Yorùbá, bẹẹni kò sì pe mi o mọ eniyàn lókè.

Bẹrẹ si ńṣe àwárí ogo rẹ nítorí pé láìpẹ́ yi, ìjọba ma bẹrẹ ìṣe.

Ere Bọọlu Afẹsẹgba

Kí kópa nínù ere ìdárayá ti bọọlu afẹsẹgba ni orílẹ̀ èdè wa - ọlọrẹ sọrẹ, ìfé ti ilẹ̀ adúláwò, àti ìfé ti àgbáyé.

Bọọlu Afọwọgba

Kí kópa nínù ere ìdárayá ti Bọọlu Afọwọgba ni orílẹ̀ èdè wa - ọlọrẹ sọrẹ, ìfé ti ilẹ̀ adúláwò, àti ìfé ti àgbáyé.

Tẹnisi Orí Tabili

Kí kópa nínù ere ìdárayá ti Tẹnisi Orí Tabili ni orílẹ̀ èdè wa - ọlọrẹ sọrẹ, ìfé ti ilẹ̀ adúláwò, àti ìfé ti àgbáyé.