Ìròyìn àti Ìgb’ohùns’afẹ́fẹ́

Ètò Ìgbóhún’sáfẹ́fẹ́

Nígbà gbogbo ni a máa ń sọ wípé, Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) yóò di àpéwò nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè fún màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla. Gẹ́gẹ́bí màmá wa ṣe máa ń ṣọ pé, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé.

Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ìjọba orílẹ̀ èdè D.R.Y yóò bójútó gidi ni ètò ìgbóhùns’áfẹ́fẹ́, nítorí pé, ọ̀pọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìgbóhùns’áfẹ́fẹ́ ni wọn kàn máa ń sọ ohun tí ojú wọn ò tó, láìṣe ìwádìí bó ti tọ́, àti bó ti yẹ.

Ṣùgbọ́n, ìjọba D.R.Y kò ní fàyè gba ilé iṣẹ́ ìgbóhùns’áfẹ́fẹ́ tó bá ń sọ̀rọ̀ tí kò rí bẹ́ẹ̀ fún ará ìlú. Nítòótọ́, oníkálukú ló ní ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, kò gbọ́dọ̀ fi irọ́ bo òtítọ́ mọ́lẹ̀ láti sọ, bẹ́ẹ̀ sì ni o níláti ṣe ìwádìí fínnífínní kí o tó sọ̀rọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ìjọba tó nífẹ̀ẹ́ ará ìlú ni ìjọba D.R.Y, lórí òtítọ́ ni a dúró lè, nítorí náà, gbogbo ilé iṣẹ́ ìgbóhùns’áfẹ́fẹ́ ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá gbọ́dọ̀ máa ṣe òtítọ́ nínú ohun gbogbo.