Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, àgbàlagbà tó bá fàárọ̀ ṣeré, yóò fi ọjọ́ alẹ́ gbàárù, àti pé ìgúnpá nì’ye kan ẹni, àwọn náà ni wọ́n tún máa ń p’òwe wípé ìdí iṣẹ́ ẹni la tií mọ’ni lọ́lẹ.
Ìdí tí àwọn òwe wọ̀nyí fi wáyé ni wípé, ìran Yorùbá fẹ́ràn láti máa tẹpá mọ́’ṣẹ́ púpọ̀, Yorùbá kò fẹ́ràn ìmẹ́lẹ́ àti ọ̀lẹ.
Ní ayé àtijọ́, kété tí a bá ti bí ọmọ tuntun sílé ayé ni àwọn òbí rẹ̀ yóò ti lọ wo àkọsẹ̀jayé ọmọ náà lọ́dọ̀ ifá, ìdí ni láti mọ iṣẹ́ tí Ẹlẹ́dàá yàn mọ́ọ láti ọ̀run wá.
Yorùbá gbàgbọ́ pé tí ọmọ bá ṣe iṣẹ́ míràn yàtọ̀ sí èyí, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò leè ṣe rere nídìí iṣẹ́ náà, ìdí nìyí tí Yorùbá fi máa ń wúre wípé, Ọlọ́run má jẹ̀ẹ́ kí a ṣiṣẹ́ oníṣẹ́.
Emi la ò ní yọ̀sí àwa ọmọ Yorùbá? Tí a bá wo àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa lọ́wọ́ ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá tí Olódùmarè lò fún ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá ní àkókò yí, a óò ríi wípé láti dá wa padà sí irú ẹni tí ìran Yorùbá jẹ́ ni.
Ṣé a ò gbàgbé wípé màmá ti sọ fún wa pé, iṣẹ́ yóò pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ àti pé, gbogbo wa ni a máa ṣiṣẹ́ nítorí pé kò ní sí owó ọ̀fẹ́ rárá, àti pé ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó ọ̀yà wọn.
A tún fẹ́ fi àkókò yí sọ fún wa wípé,nínú ètò ìgbaniṣíṣẹ́ ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò ní sí ojúsàájú tàbí gbígba rìbá, ẹ̀ka tí oníkálukú bá sì ti kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò ti máa ṣiṣẹ́, àti wípé, ẹnìkan kò ní fi ojú tẹ́ńbẹ́lú iṣẹ́ ẹnìkejì, tàbí kí a máa sọ pé, iṣẹ́ ti ẹnìkan ni ó dára jù lọ nítorí pé, bákannáà ni gbogbo wa lábẹ́ òfin Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, àparò kan kò sì ní gaju ìkan lọ.