Ṣé a ò kúkú lè sọ̀rọ̀ ètò ìwòsàn kí á má f’ẹnu ba àwọn òṣìṣẹ́ ìwòsàn. Èyí ni ó máa jẹ́ kí á m’ẹnu lé ètò ẹ̀kọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìwòsan! Kò ní dàbí ibi tí a ti mbọ̀ o! Rárá! L’akọ́kọ́, kìí ṣe ọ̀rọ̀ mo kàwé t’oyìnbó, tàbí mi o kàwé tòyínbó!
A ti ní ètò ìwòsàn ní ilẹ̀ Yorùbá kí òyìnbó ó tó dé; ètò ìwòsàn tiwa kò dẹ̀ gb’ẹhìn l’ẹbá t’òyìnbó, ṣùgbọ́n ohunkóhun tí á bá rí múlò láti ibòmíràn káàkiri àgbáyé ni a máa lò, tí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ti ìbílẹ̀ wa nípa ìwòsàn á sì jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti àṣepé ohun gbogbo ní ètò ìwòsàn wa.
Èyí túmọ̀ sí pé kò sí ètò ìwòsàn kan, ní dídára, káàkiri àgbáyé (yàtọ̀ sí àwọn tó jẹ́ àkóbá ni wọ́n fi nṣe) tí kò ní sí irúfẹ́ rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí kò sí ní ibi kankan ní àgbáyé, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ni ẹ ti máa ri.
L’atàrí ìtọ́jú tó péye (èyí tí ètò ìwòsàn tó yanrantí wà nínú rẹ̀), Màmá wa ti sọ pé ọmọ ọgọ́run ọdún tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, máa dàbí pé ọ̀dọ́ ni.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá wa ti fi dá wa lójú pé, àwọn ọmọdé wa, láti inú oyún, máa ní ètò ìwòsàn àti ìtọ́jú àrà-me-rí-rí, nítorí ohun tí Olódùmarè fi jínkí wa ní ilẹ̀ Yorùbá, ó tó bẹ́ẹ̀, ó ju bẹ́ẹ̀ lọ, láti lè ṣe ètò ìwòsàn tó péye fún wọn.
Nínú ètò ìwòsàn àti ìlera D.R.Y, kò sí àyè fún ayédèrú tàbí àdàmọ̀dì óògùn ní Orílẹ̀-Èdè wa, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìwà kí á máa sọ̀rọ̀ sí aláìsàn bíi pé kìí ṣe ènìyàn!