• Oríkò Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba, Agodi, Ìpínlè Ìbàdàn (Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ látijọ), D.R.Y

Àṣà àti Ìgbáfẹ́

Àṣà àti Ìgbáfẹ́

Àṣà wa ni ìṣẹ̀dá’lẹ̀ wa. Ẹnik’ẹni kò lè wà ní ilẹ̀ Yorùbá láì mọ̀ wípé àṣà wa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ìgbé ayé ọmọ Yorùbá.

Èyí tú’mọ̀ sí wípé kò sí ẹnik’ẹni tí ó lè dí àṣà wa l’ọwọ́. Àṣà ilẹ̀ wa ni ó jẹ́ atọ́nà fún ohun gbogbo tí a bá nṣe.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, èdè wa pẹ̀lú àṣa wa. Nít’orí eléyi, ohun gbogbo tí a bá nṣe, yálà ní ilé iṣẹ́ ìjọba ni, tàbí ilé-iṣẹ́ àdáni, àti ohun gbogbo tí ó ní’ṣe pẹ̀lú ará ìlú, ní èdè Yorùbá ni a ti nṣe é.

Ẹnik’ẹni tí kò bá le ṣe ìdú’nádú’rà ní èdè Yorùbá, kí ó mú ògbufọ̀ rẹ̀ dání. Títí dé gbogbo ilé-ìwé, àti ti ìjọba àti ti aládáni, èdè Yorùbá ni èdè ìbá’nisọ̀rọ̀ àti ìkọ́ni.

Àwọn ọpọ̀l’ọpọ̀ ibi ìgbafẹ́ àti eré ṣíṣe, l’ọkan-ò-j’ọ̀kan, yálà fún àwọn ọmọdé àti àgbàlágbà, bákannáà, ni orílẹ̀-èdè Yorùbá ní ètò fún.

Àṣà Yorùbá 

Gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀; Ìyá Ìran Yorùbá, ẹni tí Olódùmarè ti rán sí wa gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà, ti máa nsọ fún wa, pé, a máa padà sí Orísun wa ni – àṣẹ Ẹlẹ́da wa ni èyí.

Kíni orísun wa? Ibi tí a ti ṣàn wá; ìṣèjọba-ara-ẹni wa, gẹ́gẹ́bí Yorùbá, láìsí lábẹ́ ẹnikẹ́ni!

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti fi yé wa pé nṣe ni a máa padà sínú àṣà abínibí wa nínú ohun gbogbo – títí kan bí a ṣé nwá onjẹ nínú ilé-iṣẹ-ọ́lónjẹ gbogbo.

Àṣà wa nìkan ni ó bá ìṣẹ̀dá wa mu; ìdí nìyẹn tí a níláti padà sí àṣà wa! Láìṣe bẹ́ẹ̀, kí Ọlọ́run máṣe jẹ́ kí ẹ̀dá wa kí ó takò wá o! A ò ní gba àbọ̀dè fún ara wa.

Àṣà wa ni ohun ìbílẹ̀ wa; ohun tí ó bá ẹ̀jẹ̀ tí Olódùmarè fi dá Yorùbá, tí ó ba mu – ohun tí ó jẹ́ pé láti ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá ní a ti nṣe é, tí ó dẹ̀ ngbè wá; ohun tí ó fún wa ni ẹ̀mí “ilé-ni-mo-wa” kì nṣe ohun tí ó jẹ́ àjèjì sí ẹ̀mí ọmọ Yorùbá, ẹ̀mí Ìran Yorùbá.

Gẹ́gẹ́bí ewé àti egbò, fún àpẹrẹ – àwọn ohun tí Olódùmarè ti fi sí Àyíká wa, pé kí wọ́n le jẹ́ ààbò àti ìwòsàn fún ara wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa nní ọgbọ́n kún ọgbọ́n ni, síbẹ̀, èyí tí Ọlọ́run ti fún wa, tí ó jẹ́ Àbáláyé, a máa padà sínú rẹ̀, kí ilẹ̀ àbáláyé wa yí, kí ó le gbè wá.

Màmá ti máa nsọ fún wa pé ó ní bí àwọn Bàbá wa ṣe ní ìgbé ayé rere níjọ́ láíláí, kí amúnisìn ó tó gòkè odò; a máa ṣe àwárí àwọn ohun tó mú kí wọ́n ní irúfẹ́ ìgbé-ayé-rere bẹ́ẹ̀.

A ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lílo èdè wa; láti inú lílo èdè yí ni oríṣiríṣi nkan míì tí ó jẹ́ ti àbáláyé ti máa búyọ.

Ṣebí ó ní àwọn ọgbọ́n tí àwọn Baba wa ní, tí wọ́n fi nṣe àgbéjáde oríṣiríṣi iṣẹ́, bíi gbígbé nkan àgbẹ̀dẹ jáde; oríṣiríṣi Ìmọ̀ nípa ilẹ̀ tí a fi ndá’ko, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan, tí ó jẹ́ ti Ìbílẹ́, ló máa búyọ; bí àwọn ìyá wa ní ayé àtijọ́ tí máa nṣe àwọn iṣẹ́-ọwọ́ kan, èyí tí ó jẹ́ pé, títí di òní, a ò tíì rí ìran míràn tí ó ríi ṣe tó Ìran Yorùbá.

Ẹ jẹ́ kí a rántí bí àwọn òyìnbó amúnisìn, ṣe gbà pé ẹ̀kọ́, àṣà àti ìjọ́mọ-lúàbí wa ga ju tiwọn lọ, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá gbe tiwọn yẹn lé wa lọ́wọ́! Ṣùgbọ́n tí ìyá ìran Yorùbá sọ pé èyí tí a sọnù yẹn, a máa padà sínú rẹ̀.

Yorùbá ni wá; àṣà Yorùbá nìkan ló le pé wa.

Àṣà wa ni ìṣẹ̀dá'lẹ̀ wa

ọpọ̀l'ọpọ̀ ibi ìgbafẹ́ àti eré ṣíṣe