Díẹ̀ Lára Àwọn Àǹfààní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa Tí Yorùbá
1. Ìwé Òfin D.R.Y
Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ní ànfààní àti ẹ̀tọ́ láti fún’ra wa kọ Ìwé Òfin Orílẹ̀-Èdè wa.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe ṣe àlàyé fún wa, òfin tí ó dára jùlọ fún Orílẹ̀-Èdè wa ni èyí tí ó jẹ́ pé àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) gan-an-gan ló kọọ́: láti inú ìrírí wa, gẹ́gẹ́bí àṣà àti ìṣe wa, ohun tí ó bá ìṣẹ̀dá wa mu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nípasẹ̀ ètò yí, òfin Orílẹ̀-Èdè D.R.Y yóò jẹ́ èyí tí ó ti ọwọ́ ara wa jáde, gẹ́gẹ́bí ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).
Àkókò ṣì ńbọ̀ tí àwọn aṣojú wa máa jóko láti gbé àwọn àbá wa gbogbo yẹ̀wò, láti mọ̀ èyí tí apapọ̀ ọmọ Yorubá fọwọ́ sí gẹ́gẹ́bí òfin.
2. ILÉ-Ẹ̀KỌ́ Ọ̀FẸ́
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Adániwáyé tó sọ ohun gbogbo di ọ̀tun fún wa Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), tí a bá wo orílẹ̀ èdè agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí a ti kúrò, a ó ríi bí ètò ẹ̀kọ́ wọn ṣe mẹ́hẹ, púpọ̀ ọmọ tó yẹ kó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ ló ń rìn káàkiri ìgboro nígbà tí àwọn òbí wọn kò rí owó ilé-ìwé san, àwọn ìjọba tó jẹ́ àǹfààní ilé-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ṣe ni wọ́n gun àkàbà tán tí wọ́n gbé e kúrò kí ọmọ ẹlòmíràn má bàa ní oore ọ̀fẹ́ síi.
Àwọn tò sì tún wà nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ńkọ́, ṣèbí ẹ̀kọ́ àdàmọ̀dì náà ni wọ́n ń kọ́ wọn, ẹ̀kọ́ tí kò wúlò lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá kàwé tán, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń san owó gegere.
A ò róhun fáyọ̀ bí ò s’ọpẹ́ àwa ọmọ Yorùbá? Olódùmarè ti mú ìgbà ọtún dé fún wa. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ọ̀fẹ́ ni ilé ìwé láti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ipele ìgboyè kíní ní Fáṣítì,ẹ̀kọ́ tó yè kooro ni àwọn ọmọ wa yóò gbà, pẹ̀lú àwọn olùkọ́ tó yanrantí, kò sí ẹ̀fọ́rí owó ilé ìwé fún àwọn òbí mọ́,ohun gbogbo ti dì’rọ̀rùn.
3. GBÍGBÉ ÀṢÀ YORÙBÁ LÁRUGẸ
Ìgbà ọ̀tun ti wọlé dé o gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y),gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ní kété tí àwọn ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tó ń f’ipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa bá ti kúrò pẹ̀lú ìtìjú àti ìpayínkeke,ní ohun gbogbo yóò gba àyípadà ọ̀tun, bẹ̀rẹ̀ láti ìwa wa, ìjẹ́un wa, ìwọ’ṣọ wa, àti ìgbésí ayé wa lápapọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wá Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, tí Olódùmarè lò fún òmìnira àwa ìran Yorùbá ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí bí àwa ìran Yorùbá ṣe jẹ́ gan-an láì sí àmúlùmálà rárá. Màmá sọ fún wa nípa ètò ìwòsàn wípé, a ó máa ló ìlànà àwọn babańlá wa láti ṣe ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn,ìmúra àti ìw’ọṣọ wa yóò jẹ́ ti ìlànà ìbílẹ̀ Yorùbá.
Èdè Yorùbá ni a ó máa sọ ní ilé- ẹ̀kọ́, ní ilé – iṣẹ́ àti níbi gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, àwọn oúnjẹ wa tí ó ti di ohun ìgbàgbé a ó padà sí bí a tií ṣeé tẹ́lẹ̀, a óò padà sí ìwà ọmọlúwàbí wa bakanna, nítorí pé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè gbà ìwà tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣẹ́ àti ìyà yóò di àfìsẹ́yìn tí eégún ńf’iṣọ.
4. ÈTÒ FÚN ÀKÀNDÁ
Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) jẹ́ èyí tí ó kún fún ànfààní tó yanrantí fún oríṣiríṣi àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P). Bí ètò ti wà fún ọmọ-ilé-ìwé, bẹ́ẹ̀ ló wà fún ọmọ-oyún-inú; ètò fún arúgbó náà kò gbẹ́hìn; bákannáà ni ètò fún gbogbo àkàndá tí wọ́n jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.
L’akọ́kọ́ ná, gbogbo ohun tí ó wà fún ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá t’ó jẹ́ akẹ́kọ, tàbí oníṣòwò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, òun náà ló wà fún àkàndá tí ó jẹ́ ojúlówó ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá.
L’ẹhìn pé ó njẹ gbogbo ànfààní àti ẹ̀tọ́ I.Y.P, àkàndá I.Y.P tún wá ní ètò tí yíò jẹ́ kó rọrùn fún-un láti má sí ìdojúkọ tí ọwọ́ ò ká, látàrí bí ó ṣe jẹ́ àkàndá. Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, àkàndá tí ó fẹ́ lọ sí ilé-ìwé máa ní ohun tí kò fi ní nira láti kàwé, ìbáà ṣe ìpèníjà ojú ni ó ní.
Àkàndá tí ó jẹ́ pé ìpèníjà ìrìn-ẹsẹ̀ ni ó ní, á rí ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ D.R.Y nípa bí ojú pópó kò ṣe ní l’ewu fun láti rìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìdùnnú àkọ́kọ́ ni pé, ó jẹ́ I.Y.P – ànfààní rẹpẹtẹ ló bá dé: wípé ó tún wá jẹ́ àkàndá túmọ̀ sí pé oríṣiríṣi amáyé-àkàndá-dẹrùn ní ó tún máa ní, tí kò fi ní máa ṣe ìnira tàbí ìpalára fún-un láti gbé ìgbé-ayé rẹ̀.
5. ÌWÁDI ÌJÌNLẸ̀ NÍ D.R.Y
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni a nílò ìwádi-ìjìnlẹ̀ lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyà-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, pé a máa ṣe ìwádi àti àgbéjáde Ìtàn wá; bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣe ìwádi àwọn ohun ìwòsàn abáláyé wa.
Màmá wa sọ bákannáà pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn fún òwò kan tàbí òmíràn tí ó jẹ́ pé àwọn kan jẹ gàbá lé lórí ní ilẹ̀ Yorùbá, kí á lọ wádi nípa rẹ̀, láti máà ṣé, nítorí ẹnikan-kan kò ní gàba lé ọmọ Yorùbá nínú òwò kankan.
A tún ti mọ̀, tẹ́lẹ̀, pé, ìwádi tó pọ̀ ni ó máa wáyé nípa iṣẹ́-ẹ̀rọ ní oríṣiríṣi.Kíni ìwọ̀nyí nsọ fún wa?
Wọ́n nsọ fún wa pé iṣẹ́ wà gidi fún wa, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) láti gbé oríṣiríṣi ìmọ̀ jáde, fún iṣẹ́ tí ìwádi wọ̀nyí máa já sí, tí èyí á wá jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún oríṣiríṣi àbáyọrí-sí-rere ní iṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa.
A ò gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀lẹ o. Ó túmọ̀ sí pé iṣẹ́-ọpọlọ, ìwádi-ìrònú-jinlẹ̀ àti ṣíṣe àwárí oríṣiríṣi Ìmọ̀, Ọgbọ́n àti Òye, máa kó ipa tó lágbára gidi ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
6. ÌṢÀKÓSO ÀLÙMỌ́NÌ ILẸ̀
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí òye kò yé, ni wọ́n ti béèrè pé “kí la máa jẹ,” “kí la máà mu,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ní Orílẹ̀-Èdè wa.
Ọ̀rọ̀ yí kò rújú rárá; Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nsọọ́, láti ìgbà dé ìgbà, pé nísiìyí tí a ti polongo ìṣèjọba-ara-ẹni wa, tí a dẹ̀ ti ṣe ìbúra wọlé fún Alákóso Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ohun tí ó túmọ̀ sí ni pé a ti ní ÀṢẸ báyi láti máa wa kùsà wà, ní ilẹ̀ Yorùbá, lábẹ́ àkóso wa, Ìṣàkóso D.R.Y, fún ànfààní ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá.
Ìwọ ni Góòlù, lithium, bitumen, epo rọ̀bì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo rẹ̀ ti wà ní ìkáwọ́ ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá báyi, láìsí ẹni tí ó nbá wa pín nkan tí Olódùmarè fún wa. A ò tíì sọ erè oko, ẹja inú omi, àwọn ìgbó wa, ibi ìgbafẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́bí màmá wa ti ń sọ fún wa, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ni Olódùmarè túbọ̀ nfihan’ni oríṣiríṣi àlùmọ́nì tí ó wà nínú ilẹ̀ wa.
Láyé, ẹnikẹ́ni kò ní wá máa kó nkan wa mọ́: àwa ni a ni ohun tí Èdùmàrè fún wa; kò ń ṣe fún ẹlòmíran Àti má yé dẹrùn- ilé ìwòsàn, ilé-ẹ̀kọ́, títì tó dára, pẹ̀lú omi tó mọ́ gaara, kò ní ni wá lára; níbo ni a ti máa rí owó ṣe ohun wọ̀nyí? Owó wà nínú ilẹ̀ wa! ÀLÙMỌ́NÌ ló njẹ́ bẹ́ẹ̀! Ìdí nìyẹn tí Màmá tí máa nsọ pé ìṣèjọba-ara-ẹni, èyí tí ó fún wa ní àṣẹ láti ṣe àkóso gbogbo ohun tí Ọlọ́run jogún fún wa, ìyẹn gan-an ni a npè ní ÒMÌNIRA.
Ọmọ ìbílẹ̀-Yorùbá ti bọ́ sí Òmìnira báyi: Ohun kan tó kù ni kí á lé àwọn wèrè tó wà lórí ilẹ̀ wa; ìṣàkóso àlùmọ́nì ilẹ̀ wa túmọ̀ sí pé a ò lọ kọ́kọ́ gba àṣẹ níbikíbi kí á tó fọwọ́ kan ohun tó jẹ́ tiwa; láarín ara wa, ní abẹ́ àkóso D.R.Y, ni a ti máa sọ pé ohun rere báyi la fẹ́ ṣe; àlùmọ́nì ilẹ̀ wa á dẹ̀ sọ pé a ríi sọ, torí òun wà níbẹ̀ fún wa: àgàgà, a tún wá ní Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti gbé lé Màmá wa lọ́wọ́, tí ó máa fi ọ̀nà hàn wá, bí a ṣe máa ṣé, tí gbogbo rẹ̀ á yẹ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).
Kò sí ìfòyà fún wa o! Agbára àlùmọ́nì ilẹ̀ jẹ́ ìkan gbòógì nínú nkan tí orílẹ̀-èdè fi nṣe orí-ire, Olódùmarè dẹ̀ ti ṣe ọmọ Yorùbá ní olórí-ire. Gbogbo àlùmọ́nì wọ̀nyí ni wọ́n ti wà ní inú ilẹ̀ wa láti àtètèkọ́ṣe; ohun tí ó wá jẹ́ ayọ̀ wa báyi ni pé a ti wá ní ÀṢẸ lórí ohun tó jẹ́ tiwa.
Kìí ṣe èyí nìkan; Èdùmàrè tún wá jogún ọpọlọ fún àwa ọmọ Yorùbá láti ṣe ìwádi, ṣe iṣẹ́, àti gbé iṣẹ́ lóríṣiríṣi jáde nípasẹ̀ àwọn àlùmọ́nì wọ̀nyí, fún ògo, ìdùnnú àti ayọ̀ ọmọ Yorùbá – kí á lè máa yin Ọlọ́run, títí ayé, gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa nsọ.
7. ÀǸFÀÀNÍ ÈTÒ ILÉ GBÍGBÉ
Láìpẹ́, láìjìnnà, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) yóò di àpéwò káàkiri àgbáyé látàrí àwọn ohun àrà-meèrírí tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan ní orílẹ̀ èdè wa nípasẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tí Olódùmarè fún màmá wá, iya ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, lára àwọn ohun tí màmá wa ti máa ń bá wa sọ náà ni wípé, gbogbo àwa tó jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, IYP) ni yóò ní ilé lórí nítorí pé, Alákóso orílẹ̀ èdè DRY yóò fún ẹni kọ̀ọ̀kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún mọ́kànlélógún ní ilẹ̀, wọ́n yóò sì tún ṣe àtìlẹyìn fún wọn láti kọ́ ilé náà.
Bẹ́ẹ̀ sì ni ètò yóò wà fún àwọn àgbègbè tí ó bá yẹ fún ilé gbígbé, ilé iṣẹ́ tàbí fún iṣẹ́ ọ̀gbìn. Ẹnikẹ́ni kò ní leè kọ́ ilé láìgba àṣẹ lọ́dọ̀ Alákóso DRY bẹ́ẹ̀ni, ìjọba ní láti lọ ṣe àbẹ̀wọ̀ sí irú àgbègbè bẹ́ẹ̀ kí wọn leè ríi dájú pé kò ní sí ìjàǹbá kankan fún àwọn olùgbé ilé náà nígbà tí wọ́n bá kọ́ọ tán, tàbí fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń kọ́ ilé ọ̀hún,nítorí pé àwọn akọ́sẹ́mọṣẹ́ tó kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò máa kọ́ àwọn ilé wa ní orílẹ̀ èdè DRY.
Fún ìdí èyí, gbogbo àwa ọmọ IYP ti DRY ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé fún wa, Ìṣàkóso tí yóò fi àwọn ará ìlú ṣe àkọ́kọ́ ní ìjọba Democratic Republic of the Yorùbá, DRY, nítorí pé lẹ́yìn Ọlọ́run, Yorùbá ni!
8. OWÓ ORÍLẸ̀-ÈDÈ WA
Ọrọ̀-Ajé orílẹ̀-èdè dúró lórí àwọn ìpìlẹ̀ àti àwọn òpó kan. Lára àwọn òpó wọ̀nyí ni ìdíyelé owó-ìná orílẹ̀-èdè.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìlọsíwájú, lónìí ni ó jẹ́ pe, ọ̀kan gbòógì lára ìṣòro wọn ni àìníye-lórí òwó-ìná wọn. Èyí ni ó máa ń fa ọ̀wọ́n-gógó, nìtorí pé, owó gọbọi ní’ye kò ra ń kan tó pọ̀ lọ títí.
Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá wá fi àṣírí kan hàn wá nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá wa sọ, nígbàtí wọ́n sọ̀rọ̀ dé’bi owó-ìná (currency) Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y). Wọ́n ní góòlù ni a máa fi ṣe ìdíwọ̀n owó-ìná D.R.Y
Góòlù jẹ́ ohun kan ní àgbáyé tí ìdíyelé rẹ̀ kìí sábà jás’okè-jásí’sàlẹ̀ bí ọkọ̀ tí ìjánu rẹ̀ ti bàjẹ́; iye tí ìwọ̀n góòlù kan bá jẹ́ lóni, kò níí fi tóbẹ́ẹ̀-jùbẹ́ẹ̀-lọ yàtọ̀ sí iye tí ó máa jẹ́ ní ọ̀la.
Orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ti gbé ìdíwọ̀n owó-ìná wọn lé àpáta tàbí ìpìlẹ̀ iye tí ó jẹ́ ní góòlù, sábà máa nń aní ètò ọ̀rọ̀-ajé tí kìí sí ọ̀wọ́n gógó tó kọjá ìfaradà, nítorí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí góòlù nìkan náà ló lè ṣẹlẹ̀ sí’rú owó-ìná orílẹ̀-èdè náà.
Èyí yàtọ̀ sí ìrírí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé owó-ìná orílẹ̀-èdè míràn ni owó-ìná orílẹ̀-èdè tiwọn gb’ara lé: tí aburú bá ti bá àwọn t’ọ̀ún, ó ti bá àwọn náà nìyẹn.
Èyí túmọ̀ sí pé, ní orílẹ̀-èdè wa, ìfọkàn-balẹ̀ wa pé, níwọ̀n ìgbàtí àwa gan-an kò bá ya ọ̀lẹ, ohun tí ó bá máa ṣẹlẹ̀ sí ìdíwọ̀n góòlù ní àgbáyé, tí èyí kò sì jẹ́ aburú láti àtẹ̀yìn wá, òun náà ni a le ní ìrètí rẹ̀ lórí ìdíyelé owó-ìná wa.
Màmá tún fi yé wa pé nígbà tí a bá bẹ̀rẹ̀ sí yí èyí tí ó wà lọ́wọ́ báyi, sí owó tiwa, kí á máṣe jẹ́ kí ó yà wá lẹ́nu pé, nínú òǹkà , ení, èjì, ẹ̀ta, òǹkà rẹ̀ kò ní tó ti tẹ́lẹ̀; ìdí èyí ni pé ìdíyelé owó wa ju ti èyí tí a gbé lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.
Wọ́n tilẹ̀ ṣe àpèjúwe kan fún’wa nígbà náà l’ọhún: wọ́n ní tí ohun tí a ní lọ́wọ́ báyi bá jẹ́ mílíọ̀nù kan, kí ó máṣe yà wá lẹ́nu pé pàṣípààrọ̀ rẹ̀ lè fún wa ní ẹgbẹ̀rún l’ọnà igba owó D.R.Y, tí ó túmọ̀ sí ìdámárun mílíọ̀nù èyí tí ó jẹ́ pé, ní òǹkà owó D.R.Y kan yóò ra ohun tí márùn-ún owó tí a gbé dání tẹ́lẹ̀ máa rà. Ó níye lórí ju ti tẹ́lẹ̀ ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ṣùgbọ́n, tí ó bá jẹ́ pé òǹkà mílíọ̀nù-mílíọ̀nù ní ó wu ẹni yẹn kí ó máa kà, bí mílíọ̀nù ọ̀ún kò tilẹ̀ leè ra’jà púpọ̀, ẹni náà lè lọ kó mílíọ̀nù rẹ̀ sí’bi tí àwọn tó ń ná owó yẹn nílu wọn ń ko sí, kí ó wá bẹ̀rẹ̀ síi ṣe iṣẹ́ tí áá fi lè kó owó D.R.Y tó níye lórí jọ, ní ilẹ̀ D.R.Y.
Gbogbo èyí túmọ̀ sí pé kò sí ìfòyà ní D.R.Y, lórí ìdíyelé tàbí ìwọ̀n owó-ìná orílẹ̀-èdè wa; àá mú ònkà kan lọ́wọ́ báyi, yóò sì jẹ́ owó gidi.
9. EWÉ ÀTI EGBÒ
Láti ìgbà ìwásẹ̀ ni Olódùmarè ti fún àwọn babańlá wa ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye, láti lè bá ewé sọ̀rọ̀, àti oríṣiríṣi ohun tí ó wà ní àyíká wa; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní ìmọ̀ àwọn ohun tí èwé, egbò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ le ṣe, pàápàá ní àgọ́-ara.
Èyí ló ṣe okùnfà oríṣiríṣi ìwòsàn tí àwọn babanlá wa ní fún àwọn àìsàn tàbí àrùn tí ó bá yọjú; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fi àwọn ń kan wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ láti ìran-dé-ìran.
Ara ń kan tí àwọn òyìnbó rí nìwọ̀nyí tí wọ́n fi sọ pé ètò ẹ̀kọ́ wa wà lókè ju ti àwọn lọ, àti pé ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ láti ayébáyé ni; ṣùgbọ́n nínú ìwà ìkà wọn, wọ́n pinu láti gbàá lọ́wọ́ wa, wọ́n wá gbé tiwọn fún wa.
Gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nípele nípele, ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá sì ń fi yé wa ní ìgbà-dé-ìgbà, tí wọ́n sì sọ fún wa pé ètò ìwòsàn ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) máa dá gbogbo ìmọ̀, agbára àti ẹkọ́ nípa èwé àti egbò tí a ti ní láti ìpinlẹ̀ṣẹ̀ padà fún wa.
Èyí túmọ̀ sí pé ètò ìwòsàn wa ní D.R.Y máa rinlẹ̀ gidi, àjínde ara á máa jẹ́ fún wa nípasẹ̀ èwé àti egbò tí Olódùmarè fi dá wa lọ́lá. Òpin ti dé sí àìrójú àìrayè tí àìsàn ń fà fún’ni.
Gẹ́gẹ́bí Màmá ṣe sọ fún wa, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ní àgbáyé yí ló jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwa Yorùbá ni wọ́n ti máa ní ìwòsàn sí ń kan tí wọn kò rí ojútu rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá! A dúpẹ́ lọ́dọ̀ Elédùmarè tí ó fi Ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe atọ́nà fún wa.
10. ÌWÁDI ÌJÌNLẸ̀ NÍ D.R.Y
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ohun ni a nílò ìwádi-ìjìnlẹ̀ lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyà-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, pé a máa ṣe ìwádi àti àgbéjáde Ìtàn wá; bẹ́ẹ̀ ni a máa ṣe ìwádi àwọn ohun ìwòsàn abáláyé wa.
Màmá wa sọ bákannáà pé gbogbo ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn fún òwò kan tàbí òmíràn tí ó jẹ́ pé àwọn kan jẹ gàbá lé lórí ní ilẹ̀ Yorùbá, kí á lọ wádi nípa rẹ̀, láti máà ṣé, nítorí ẹnikan-kan kò ní gàba lé ọmọ Yorùbá nínú òwò kankan.
A tún ti mọ̀, tẹ́lẹ̀, pé, ìwádi tó pọ̀ ni ó máa wáyé nípa iṣẹ́-ẹ̀rọ ní oríṣiríṣi.Kíni ìwọ̀nyí nsọ fún wa?
Wọ́n nsọ fún wa pé iṣẹ́ wà gidi fún wa, gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) láti gbé oríṣiríṣi ìmọ̀ jáde, fún iṣẹ́ tí ìwádi wọ̀nyí máa já sí, tí èyí á wá jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún oríṣiríṣi àbáyọrí-sí-rere ní iṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa.
A ò gbọ́dọ̀ ṣe ọ̀lẹ o. Ó túmọ̀ sí pé iṣẹ́-ọpọlọ, ìwádi-ìrònú-jinlẹ̀ àti ṣíṣe àwárí oríṣiríṣi Ìmọ̀, Ọgbọ́n àti Òye, máa kó ipa tó lágbára gidi ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
11. Ètò Ààbò Tó Péye
Ọ̀rọ̀ ètò ààbò jẹ́ ohun pàtàkì tí a kò sì gbúdọ̀ fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nítorí wípé, kò sì ohunkóhun tí ènìyàn leè ṣe nínú ìbẹ̀rù àti àìbalẹ̀ ọkàn. Ìjọba tó bá fẹ́ ìdàgbàsókè fún orílẹ̀ èdè rẹ̀, yóò rí ọ̀rọ̀ ààbò gẹ́gẹ́ bíi ohun àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèjọba rẹ̀ tí ó sì gba àbójútó gidigidi.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a sì ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Olódùmarè pè wọ́n sí èyí tí ètò ààbò tó dájú sì jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wá lọ́wọ́, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, èyí tí yóò mú ọkàn gbogbo wa bálẹ̀ lórí ilẹ̀ babańlá wa.
Àwọn àgbẹ̀ wa yóò leè máa lọ sí oko wọ́n pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀, tí kò ní sí ìbẹ̀rù àwọn ajínigbé, àwọn arìnrìn-àjò yóò leè lọ síbi tó bá wù wọ́n ní àkókò tí wọ́n fẹ́,láìsí ìfòyà àwọn alọnilọ́wọ́gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìbẹ̀rù lórí àwọn dúkìá wa gbogbo.
Bákan náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tí yóò máa wo ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn yóò wà tọ̀sán-tòru, àti wípé, káàkiri orilẹ́ èdè wa ni yóò ní ohun èlò ìyàwòrán, dé bi pé, abẹ́rẹ́ tó kéré jù kò leè jábọ́ tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò kò ní mọ̀ ní orí ilẹ̀ wa.
Iṣẹ́ ọwọ́ Olódùmarè ni eléyìí jẹ́, nítorí náà àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa títí láé.
12. ORÍKÌ ILẸ̀ YORÙBÁ
Oríkì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá fẹ́ràn oríkì púpọ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń mú inú ènìyàn dùn tàbí mú orí ẹni wú.
Kò sí ohun tí àwọn Yorùbá kò ní oríkì fún,bí oríkì se wà fún ènìyàn(ìyẹn ni oríkì ìdílé) bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà fún ẹranko, bẹ́ẹ̀ sì ni oúnjẹ náà ní oríkì tirẹ̀.
Yorùbá fẹ́ràn láti máa ki ènìyàn pàápàá ní àkókò ayẹyẹ, a sì tún máa ń fi pe àwọn míràn gẹ́gẹ́ bíi orúkọ oríkì, bí àpẹẹrẹ: Àjàní, Àlàó, Àlàbí, Àkànjí, ìyẹn ni fún orúkọ oríkì ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn obìnrin náà ní orúkọ oríkì bí àpẹẹrẹ: Àjọkẹ́, Àjíkẹ́, Àríkẹ́, Àbẹ̀bí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Yorùbá mélòó ni a tilẹ̀ mọ oríkì ìdílé tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti jáde mọ́ lónìí, bẹ́ẹ̀ sì ni a ò sọ àwọn ọmọ wa ní orúkọ oríkì mọ̀.
Nítorí náà a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó ra ìran Yorùbá padà lọ́wọ́ ìparun nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ìyá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, nítorí pé màmá wa ti sọ fún wa wípé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí ìpinlẹ̀ṣẹ̀ wa ni. Ayọ̀ ni ti wa!
13. ÀǸFÀÀNÍ FÚN ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé ìránṣẹ́ rẹ̀ ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde fún àwa ìran Yorùbá ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí láti gbà wá lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti ìyà.
Àwa ọmọ aládé ti jìyà púpọ̀ fún àìmọye ọdún, ṣé ti ebi ni ká sọ ni, àbí ti ọmọ tó kàwé tí kò rí iṣẹ́ tó wá di alárìnkiri láàárín ìlú, ètò ààbò tó mẹ́hẹ ńkọ́?
Bí wọ́n ṣe ń jíwa lọ́mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń jíwa láya tí wọ́n á sì tún máa béèrè òbítíbitì owó fún ìtúsílẹ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n Olódùmarè ti gbà wá, gbogbo rẹ̀ sì ti di àfìsẹ́yìn tí eégún ń fi’ṣọ,nítorí pé màmá wa ti sọ orísìírísìí àwọn ìgbádùn tí yóò wà fún wa ní orílẹ̀ èdè wa tuntun yí nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè ti gbé lé wọn lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu, oúnjẹ yóò wà lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ́ẹ̀ni gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni yóò nílé lórí. Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá Indigenous Yorùbá People IYP, a kú oríire!
14. ÀṢÀ YORÙBÁ
Gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀; Ìyá Ìran Yorùbá, ẹni tí Olódùmarè ti rán sí wa gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà, ti máa nsọ fún wa, pé, a máa padà sí Orísun wa ni – àṣẹ Ẹlẹ́da wa ni èyí.
Kíni orísun wa? Ibi tí a ti ṣàn wá; ìṣèjọba-ara-ẹni wa, gẹ́gẹ́bí Yorùbá, láìsí lábẹ́ ẹnikẹ́ni!
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti fi yé wa pé nṣe ni a máa padà sínú àṣà abínibí wa nínú ohun gbogbo – títí kan bí a ṣé nwá onjẹ nínú ilé-iṣẹ-ọ́lónjẹ gbogbo.
Àṣà wa nìkan ni ó bá ìṣẹ̀dá wa mu; ìdí nìyẹn tí a níláti padà sí àṣà wa! Láìṣe bẹ́ẹ̀, kí Ọlọ́run máṣe jẹ́ kí ẹ̀dá wa kí ó takò wá o! A ò ní gba àbọ̀dè fún ara wa.
Àṣà wa ni ohun ìbílẹ̀ wa; ohun tí ó bá ẹ̀jẹ̀ tí Olódùmarè fi dá Yorùbá, tí ó ba mu – ohun tí ó jẹ́ pé láti ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá ní a ti nṣe é, tí ó dẹ̀ ngbè wá; ohun tí ó fún wa ni ẹ̀mí “ilé-ni-mo-wa” kì nṣe ohun tí ó jẹ́ àjèjì sí ẹ̀mí ọmọ Yorùbá, ẹ̀mí Ìran Yorùbá.
Gẹ́gẹ́bí ewé àti egbò, fún àpẹrẹ – àwọn ohun tí Olódùmarè ti fi sí Àyíká wa, pé kí wọ́n le jẹ́ ààbò àti ìwòsàn fún ara wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa nní ọgbọ́n kún ọgbọ́n ni, síbẹ̀, èyí tí Ọlọ́run ti fún wa, tí ó jẹ́ Àbáláyé, a máa padà sínú rẹ̀, kí ilẹ̀ àbáláyé wa yí, kí ó le gbè wá.
Màmá ti máa nsọ fún wa pé ó ní bí àwọn Bàbá wa ṣe ní ìgbé ayé rere níjọ́ láíláí, kí amúnisìn ó tó gòkè odò; a máa ṣe àwárí àwọn ohun tó mú kí wọ́n ní irúfẹ́ ìgbé-ayé-rere bẹ́ẹ̀.
A ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lílo èdè wa; láti inú lílo èdè yí ni oríṣiríṣi nkan míì tí ó jẹ́ ti àbáláyé ti máa búyọ.
Ṣebí ó ní àwọn ọgbọ́n tí àwọn Baba wa ní, tí wọ́n fi nṣe àgbéjáde oríṣiríṣi iṣẹ́, bíi gbígbé nkan àgbẹ̀dẹ jáde; oríṣiríṣi Ìmọ̀ nípa ilẹ̀ tí a fi ndá’ko, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan, tí ó jẹ́ ti Ìbílẹ́, ló máa búyọ; bí àwọn ìyá wa ní ayé àtijọ́ tí máa nṣe àwọn iṣẹ́-ọwọ́ kan, èyí tí ó jẹ́ pé, títí di òní, a ò tíì rí ìran míràn tí ó ríi ṣe tó Ìran Yorùbá.
Ẹ jẹ́ kí a rántí bí àwọn òyìnbó amúnisìn, ṣe gbà pé ẹ̀kọ́, àṣà àti ìjọ́mọ-lúàbí wa ga ju tiwọn lọ, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá gbe tiwọn yẹn lé wa lọ́wọ́! Ṣùgbọ́n tí ìyá ìran Yorùbá sọ pé èyí tí a sọnù yẹn, a máa padà sínú rẹ̀.
Yorùbá ni wá; àṣà Yorùbá nìkan ló le pé wa.
15. Iṣẹ́ Ṣíṣe
Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, àgbàlagbà tó bá fàárọ̀ ṣeré, yóò fi ọjọ́ alẹ́ gbàárù, àti pé ìgúnpá nì’ye kan ẹni, àwọn náà ni wọ́n tún máa ń p’òwe wípé ìdí iṣẹ́ ẹni la tií mọ’ni lọ́lẹ.
Ìdí tí àwọn òwe wọ̀nyí fi wáyé ni wípé, ìran Yorùbá fẹ́ràn láti máa tẹpá mọ́’ṣẹ́ púpọ̀, Yorùbá kò fẹ́ràn ìmẹ́lẹ́ àti ọ̀lẹ.
Ní ayé àtijọ́, kété tí a bá ti bí ọmọ tuntun sílé ayé ni àwọn òbí rẹ̀ yóò ti lọ wo àkọsẹ̀jayé ọmọ náà lọ́dọ̀ ifá, ìdí ni láti mọ iṣẹ́ tí Ẹlẹ́dàá yàn mọ́ọ láti ọ̀run wá.
Yorùbá gbàgbọ́ pé tí ọmọ bá ṣe iṣẹ́ míràn yàtọ̀ sí èyí, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò leè ṣe rere nídìí iṣẹ́ náà, ìdí nìyí tí Yorùbá fi máa ń wúre wípé, Ọlọ́run má jẹ̀ẹ́ kí a ṣiṣẹ́ oníṣẹ́.
Emi la ò ní yọ̀sí àwa ọmọ Yorùbá? Tí a bá wo àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa lọ́wọ́ ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá tí Olódùmarè lò fún ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá ní àkókò yí, a óò ríi wípé láti dá wa padà sí irú ẹni tí ìran Yorùbá jẹ́ ni.
Ṣé a ò gbàgbé wípé màmá ti sọ fún wa pé, iṣẹ́ yóò pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ àti pé, gbogbo wa ni a máa ṣiṣẹ́ nítorí pé kò ní sí owó ọ̀fẹ́ rárá, àti pé ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó ọ̀yà wọn.
A tún fẹ́ fi àkókò yí sọ fún wa wípé,nínú ètò ìgbaniṣíṣẹ́ ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, kò ní sí ojúsàájú tàbí gbígba rìbá, ẹ̀ka tí oníkálukú bá sì ti kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò ti máa ṣiṣẹ́, àti wípé, ẹnìkan kò ní fi ojú tẹ́ńbẹ́lú iṣẹ́ ẹnìkejì, tàbí kí a máa sọ pé, iṣẹ́ ti ẹnìkan ni ó dára jù lọ nítorí pé, bákannáà ni gbogbo wa lábẹ́ òfin Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, àparò kan kò sì ní gaju ìkan lọ.
16. Ojú Ọ̀nà Tó Já Geere
Láìsí àní-àní, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ti dá dúró gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè, òun sì ni orílẹ̀ èdè tuntun jùlọ ní àgbáyé.
Olórí adelé wa àti àwọn adelé tó kù sì ti ń ṣe ètò lórí ẹ̀ka lorísìírísìí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Lára rẹ̀ náà ni ọ̀nà tó já geere, gbogbo àwọn ojú pópó àti kọ̀rọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Yorùbá ní yóò ní ọ̀nà tó dára,bakanna ni àwọn ọ̀nà tó wọ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan káàkiri orí ilẹ̀ D.R.Y. kò ní gbẹ́yìn.
Ìṣàkóso D.R.Y yóò ríi dájú pé, àwọn agba’ṣẹ́ṣe tó kún ojú òṣùwọ̀n tó sì jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.YP.) ní yóò máa ṣe àwọn ọ̀nà wa, nítorí pé ọmọ ẹni ò ní sè’dí bẹ̀bẹ̀rẹ̀ ká f’ìlẹ̀kẹ̀ sí ìdí ọmọ ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìyá ìran Yorùbá ṣe máa ń sọ fún wa wípé lẹ́yìn Ọlọ́run, ọmọ Yorùbá ni àkọ́kọ́, fún ìdí èyí, àwọn ọmọ I.Y.P náà ni yóò máa ṣe àwọn iṣẹ́ lorísìírísìí láti tún orílẹ̀ èdè wa ṣe.
17. Ìpèsè Omi-Ẹ̀rọ
Omi-Ẹ̀rọ ṣe pàtàkì fún ìmọ́tótó, onjẹ àti láti dènà àrùn ní ilé àti àwùjọ.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa nsọ, L’ẹyìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni Àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni a mọ̀ pé àwa ni Ògo Adúláwọ̀. Ànfààní ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni ó jẹ
Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) lógún; ìrọ̀rùn dẹ̀ ni D.R.Y pinnu fún Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P). Kíni ìrọ̀rùn tí kò bá sí omi tó mọ́ gaara ní àrọ́wọ́tó?
Orilẹ̀-Èdè D.R.Y ní ìpèsè omi tó mọ́ gaara, tí ó wà ní àrọ́wọ́tó, nígbàkúgba àti níbi gbogbo ní ilẹ̀ D.R.Y, nínú ètò fún àwa ọmọ Aládé.
Ní kété tí a bá ti r’ẹyìn àwọn ọ̀tá, tí Alákóso orílẹ̀-èdè wa wọ’nú oríkò-ilé-iṣẹ́-Ìṣàkóso Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, ìpèsè omi ẹ̀rọ, fún àláfíà àti ìrọ̀rùn ọmọ Yorùbá, jẹ́ ìkan gbòógì nínú iṣẹ́ àmúṣe.
Eléyi yíò sì tún mú ìrọ̀rùn dé bá iṣẹ́ ṣíṣe gbogbo ní orílẹ̀-èdè wa, torí kò sí ilé-iṣẹ́, ìbáà ṣe ti Ìṣàkóso D.R.Y tàbí ti aládani, tí kò nílò omi-ẹ̀rọ tó mọ́ gaara, tó sì wà ní àrọ́wọ́tó.
Ẹ jẹ́ kí á fi àdúrà ran bàbá wa, Olórí-Adelé, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, àti gbogbo adelé, lọ́wọ́, kí Olódùmarè máa fún wọn ní Okun, Agbára, Ọgbọ́n àti Ìmọ̀ fún iṣẹ́ ribiribi tí Ó gbé lé wọn lọ́wọ́, kí àwa náà fi ọwọ́ so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn láti tẹ̀lé Òfin Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).
18. Iná Mọ̀nà-Mọ́ná
Lọ́kan-ò-jọ̀kan ni àwọn àǹfààní tí yóò wà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) nítorí pé màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti gba ìran Yorùbá lóko ẹrú fẹ́ràn ìran wọn tọkàntọkàn tí wọ́n kò sì fẹ́ kí ìyà jẹ ọmọ Yorùbá kankan, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè sì gbé lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé, lára àwọn ohun am’áyédẹrùn tí a óò jẹ ìgbádùn rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y náà ni iná mọ̀nà-mọ́ná.
Láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ náà ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí gbogbo rẹ̀ sì ń lọ létò-letò nítorí pé pàtàkì ni iná mọ̀nà-mọ́ná láwùjọ, gbogbo àwọn onílé iṣẹ́ ńlá-ńlá àti olóko òwò kéékèèké yóò máa rí iná lò lóòrè-kóòrè láti ṣe iṣẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ní gbogbo ìlú àti ìgbèríko káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni iná mọ̀nà-mọ́ná yóò wà tí kò ní sí ààyè fún àwọn amòkùns’èkà láti fi ojú pamọ́ sí.
Nítorí náà gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé fún wa, ẹ jẹ́ kí a máa jó ká sì máa yọ̀.
19. ÌTỌ́JÚ OYÚN INÚ
Ìran Yorùbá fẹ́ràn ọmọ lọ́pọ̀lọ́pọ̀; láti inú oyún ni a ti ń nífẹ̀ẹ́ ọmọ wa: a tilẹ̀ máa ń pè wọ́n ní “atinúkẹ́,” yálà wọ́n jẹ́ orúkọ náà nígbá tí wọ́n dé’lé ayé tán tàbí wọn ò jẹ.
Ìran Yorùbá wá ní Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí Ó sì gbé Àlakalẹ̀ ètò ìsèjọba am’áyédẹrùn fún wọ́n láti lò fún àwa ìran Yorùbá.
Láti inú oyún ni ìtọ́jú ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀, torí Ìṣàkóso Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú Orílẹ̀-Èdè Yorùbá kò ní fi aláboyún sílẹ̀ fún ìgbé-ayé rádaràda èyí tí ó leè fa àkóbá fún oyún inú rẹ̀.
Ìtọ́jú oyún-inú ti bẹ̀rẹ̀ kí a tó lóyún rẹ̀ pàápàá, nípasẹ̀ ìgbé ayé rere tó wà fún ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá tí kò ya ọ̀lẹ, tí kò sì gbàbọ̀de.
Nípa èyí, nínú àgọ́-ara tí ó ní àláfíà ni ìlóyún-ọmọ ti máa wáyé !
Ìjọ́ tí ìyá-ọmọ bá sì ti fẹ́’ra kù ni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti ní Ètò àbojútó aláboyún àti ọmọ-oyún-inú, nípasẹ̀ ìmọ̀ràn, ìbojútóni,oríṣiríṣi àyẹ̀wò tí ìyá àti oyún-inú máa nílò !
Kí a tún wá rántí pé ọ̀dá owó kò ní dènà àyẹ̀wò wọ̀nyí, t’orí ètò ìwòsàn ọ̀fẹ́ wà fún aláboyún àti oyún-inú tí wọ́n jẹ́ ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P).
20. ỌJÀ ÌGBÀLÓDÉ
Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán ìyá aláàánú sí wa, màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wá kúrò nínú ìyà àti òṣì. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń fi dá’wa lójú wípé, ọmọ Yorùbá kankan kò tún j’ìyà mọ́, nítorí pé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè gbé lé màmá lọ́wọ́, kún fún ìgbá’yé gbá’dùn lorísìírísìí,lára wọn náà ni ọjà ìgbàlódé.
Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), gbogbo àwọn ọjà wa ni a óò sọ di ti ìgbàlódé, iná mọ̀nàmọ́ná tí kò ní sẹ́’jú, omi ẹ̀rọ tí kò ní lọ,ààbò tó péyé fún àwọn olùra’jà àti olùta’jà, bẹ́ẹ̀ ni àyíká tó mọ́ tó sì dùn- ún wò.
Ìṣàkóso Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y yóò ríi dájú pé, gbogbo àwọn ohun tí ẹnu ń jẹ ní wọ́n ń pèsè ní àyíká tó mọ́ láti dènà àìsàn tó leè sẹ́yọ nípasẹ̀ ìdọ̀tí, nítorí pé, ìjọba tó fẹ́ràn ará ìlú tó sì fi tiwọn ṣe àkọ́kọ́ ni ìjọba D.R.Y
Nítorí náà, a kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) pé a kú oríire, bẹ́ẹ̀ ni a kí màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ẹ seun lọ́pọ̀lọpọ̀,ìran Yorùbá mọ̀ọ́ lóore.
21. ÌTỌ́JÚ ÀWỌN ỌMỌ OLÓGO
Màmá wa, Olùgbàlà Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ pé gbogbo ọmọ Yorùbá tí aburú ti dé bá ìgbésí ayé wọn látàrí ìwàk’iwà, ni yíò rí kádàrá wọn gbà padà gẹ́gẹ́bí ọmọ ológo tí Olódùmarè fẹ́ kí wọ́n jẹ́.
Ìyá wa sọ pé inkan tó bá máa gbà ni a máa fun, kí ògo wọn lè búyọ.
L’ọnà kíní, ìtọ́jú tí ó péye máa wà fún wọn, láti mú ọkàn àti ìrònú wọn kúrò nínú ìgbé-ayé òṣì, kí wọ́n le mọ̀ pé ayé míràn tún wà, yàtọ̀ sí ayé rádaràda tí wọ́n ti ngbé tẹ́lẹ̀, kí iyè wọn lè ṣí láti ní ìfẹ́ sí àwọn ìgbé-ayé rere!
Ọ̀nà kéjì, ìtọ́jú-ìwòsàn máa wà fún wọn, láti lè mú gbogbo àgọ́-ara wọn padà bọ́ s’ipò, kúrò nínú oríṣiríṣi àìṣedéédé tí ìgbé-ayé búburú ti tẹ́lẹ̀ ti kó sí wọn l’ara.
Ẹ̀kẹ́ta, ìrànlọ́wọ́ nípa ohun-ti-ẹ̀mí, gẹ́gẹ́bí ìgbẹ́kẹ̀lé oníkálùkù wọn máa wà, títí tí wọ́n á fi di ènìyàn gidi padà, tí ògo wọn á búyọ
22. ÌBÁṢEPỌ̀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà, pé a ò níí ti oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn! Wọ́n sọ èyí nítorí pé, Olódùmarè ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àṣìrí ní àgbáyé han wọ́n, èyí tí ó wá wúlò nínú iṣẹ́ ìgbàlà tí Ẹlẹ́da rán wọ́n, fún ìṣerere Ìran Yorùbá.
Òtítọ́ pàtàkì ni pé, orílẹ̀-èdè tí ó bá dá Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) mọ̀, ni àwa náà máa dá-mọ̀ gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè.Orílẹ̀-èdè tí ó bá pọ́n wa lé, ni àwa náà máa pọ́n-lé.
Orílẹ̀-èdè tí ó bá bu ọ̀wọ̀ fún wa ni àwa náà máà bu ọ̀wọ̀ fún.Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́bí MOA ti sọ, D.R.Y kò ní ṣe ẹrú fún orílẹ̀-èdè kankan ní àgbáyé!
Ojú tí orílẹ̀-èdè k’orílẹ̀-èdè bá fi wò wá, ni àwa náà máa fi wò ó!Bẹ́ẹ̀ náà ni a ò ní bá orílẹ̀-èdè kankan pàdípọ̀ máa b’ẹnu àtẹ́ lu orílẹ̀-èdè míràn!
A ò ní bá wọn gbè s’ẹyìn orílẹ̀-èdè kan ṣe lòdì sí òmíran, àbí kó ọ̀wọ́-àbòsí pẹ̀lú orílẹ̀-èdè kan tako orílẹ̀-èdè míràn.Paríparì gbogbo rẹ̀, ohun tí ó jẹ́ atọ́kùn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tí ìbáà-wù kó jẹ́, ni pé, L’ẹyìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá Ni Àkọ́kọ́!
A ò ní ta ohunk’ohun ní rọ̀bì fún orílẹ̀-èdè míràn. Ohun tí a bá ma tà jáde, jẹ́ ohun tí a ti sọ di oníye-lórí, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní fi orílẹ̀-èdè wa sílẹ̀ máa wá ohun-ìmúlò fún àwọn ilé-iṣẹ́ wa ní’bi tí kò tọ́.
Irúfẹ́ ìgbésẹ̀-akin wọ̀nyí, kò ní fi àyè gba orílẹ̀-èdè kankan láti fi ìwọ̀sí lọ D.R.Y abí Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), bẹ́ẹ̀ ni a ò ní kó ara wa sí àfọwọ́-fà burúkú kankan!
23. OÚNJẸ TÓ DÁRA
Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìgbádùn tí yóò wà fún wa kò lóǹkà, àìríjẹ ti di ohun ìgbàgbé ní ilẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ tó dára ní a óò máa jẹ́, nítorí pé Ìṣàkóso Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y kò ní fàyè gba ayédèrú oúnjẹ GMO tàbí lílo èròjà tó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn.
Gbogbo àwọn ẹnu ibodè wa ni wọ́n yóò ti máa ṣe àyẹ̀wò fínnífínní lórí ohunkóhun tí wọ́n bá ń kó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa èyí ni láti ríi dájú pé wọn ò kò oúnjẹ tó leè ṣe ìpalára wá fún wa.
24. Ojúse Alákóso Fún Àwọn Ara Ìlú
Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), gbogbo ojúṣe tó yẹ kí àwọn ìjọba ṣe ni wọ́n yóò máa ṣe, tí wọ́n kò sì ní yọ ọ̀kan sílẹ̀ nítorí pé, Alákóso wa yóò nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ìlú bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní jẹ́ kí ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tàbí tẹ ẹ̀tọ́ wọ́n lójú mọ́lẹ̀.
Ojúse Alákóso ni láti dáàbò bo ara ìlú, láti pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, iṣẹ́, iná mọ̀nàmọ́ná, ètò ìwòsàn, ètò ẹ̀kọ́ tó yanranntí, omi, àti àwọn ohun am’áyédẹrùn lorísìírísìí.
Gbogbo ìwọ̀nyí ni a óò fi ojú wa rí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, ètò sì ti ń lọ lọ́kàn-ò-jọ̀kan, ọmọ Yorùbá kankan kò tún j’ìyà mọ́, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ni yóò rí ògo wọn lò, nítorí náà ayọ̀ ni ti wa.
25. Orílẹ̀-Èdè Wà Kò Ní Jẹ Gbèsè
Màmá Ìran Yorúbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti máa nfi yé wa pé ìkan nínú àwọn ọ̀nà tí àwọn amúnisìn fi máa nmú àwọn orílẹ̀-èdè ní ẹrú, ni nípa gbèsè jíjẹ. Àwọn ni wọ́n á fa orílẹ̀-èdè náà pé kó wá yáwo; àwọn ni wọ́n a sọ fun bí ó ṣe máa ná owó náà, àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ! Títí tí gbèsè á máa gun orí gbèsè!
Màmá wá fi yé wa pé, láyé, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kò ní yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Ohun tí a bá nílò, àwa ni a máa ṣé fún’ra wa; ohun tí a bá sì ṣe ni a máa lò.
Ànfààní t’ó wà nínú pé a ò ní jẹ gbèsè, ni pé, kò sí ẹnikẹ́ni tàbí àjọkájọ tí á le fi ipá tì wá sí ohun tí a kò fẹ́ ṣe! Àbùrọ̀ jẹ gbèsè ni àbùrọ̀ di ẹni tí kò lè kọ nkan tí ó yẹ kí ó kọ̀: èyí á wá di oko-ẹrú míràn; bẹ́ẹ̀ a ò tún ní lọ sí oko-ẹrú míràn láyé!
Àìjẹ-gbèsè á fún wa ní ìbàlẹ̀-ọkàn: kò ní sí pé tí a ò bá wá lè san gbèsè, oní-gbèsè á wá máa béèrè ohun t’ó máa pa wá l’ara!
Ìrọ̀rùn fún ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), pẹ̀lú ìbàlẹ̀-ọkàn fún D.R.Y, bákan-náà, òun ni aìjẹ-gbèsè máa jẹ́ fún wa. Ìtẹ́lọ́rùn ni a máa fi ṣe ìgbé-ayé wa gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè.
26. ÌTỌ́JÚ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́
Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá(Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ni yóò jẹ àǹfààní ìsèjọba tó kún ojú òṣùwọ̀n tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ìlú.
Ìtọ́jú tó péyé yóò wà fún àwọn òṣìṣẹ́, Alákóso D.R.Y kò sì ní fi ẹ̀tọ́ wọn dùn wọn. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó ọ̀yà wọn.
Fún ìdí èyí, awa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) fi àkókò yí dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá wa MOA fún gbogbo akitiyan wọ́n lórí ìran Yorùbá láti lè jẹ́ kí a bọ́ nínú ìnira, kò ní súu yín, kò ní rẹ̀ yín láṣẹ Èdùmàrè.
27. ÌDÀGBÀSÓKÈ ÌGBÈRÍKO
Ìdàgbàsókè gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni ó jẹ Alákóso Ètò Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) lógún, lábẹ́ ìṣàkóso Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa ti sọ, gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni ó máa ní ìdàgbàsókè àti ìgbá’yé gbádùn. Èyí tó jẹ́ pé ibi yóò wù kí a wà, ojúlówó ohun amáyédẹrùn àti ìgbé-ayé àláfíà ni ó máa wà ní àrọ́wọ́to.
Láti mú èyí wá sí ìmúṣẹ, ipele mẹ́rin ni yóò wà nínú ètò ìdàgbàsókè káàkiri ilẹ̀ Yorùbá – ipele “Ìlú-Nlá” (Urban); “Ìlú Kékèké” (Sub-Urban); “Ìgbèríko” (Rural) àti “Ẹsẹ̀kùkú” (Sub-Rural). Bẹ́ẹ̀ ni ipele kọ̀ọ̀kan sì ní ojúṣe tirẹ̀ ní orílẹ̀-èdè D.R.Y. Èyí túmọ̀ sí pé ipele tí àgbègbè kan bá wà ni ó máa ṣe àpèjúwe irú ohun amáyédẹrùn tí yóò wà níbẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn bí omi, títì t’ó dára, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó máa wà ní’bi gbogbo.
Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, agbègbè t’ó jẹ́ pé àwọn ní wọ́n npèsè oúnjẹ fún orílẹ̀-èdè wa, ó ní àwọn ohun ìdàgbàsókè tí ó gbọ́dọ̀ wà ní’bẹ̀; agbègbè tí ó jẹ́ pé ibẹ̀ ni àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ gbogbonìṣe pọ̀ sí, ó ní bí a ṣe máa ṣe ètò ìdàgbàsókè ibẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nípasẹ̀ èyí, Ìgbèríko ní iṣẹ́ tirẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè tí ìlú-nlá kò lè ṣe: irú ìdàgbàsókè tí ó máa mú iṣẹ́ ìgbèríko dùn-ún ṣe, nínú ìrọ̀rùn, ni ó máa wà ní’bẹ̀, yàtọ̀ sí àwọn ohun amáyédẹrùn tí ó jẹ́ kòseémá nìí gbogbo D.R.Y.
Ohun tí a ń sọ ni pé Ìgbèríko ní D.R.Y kìí ṣe oko lásán tí ènìyàn máa p’ẹ̀gàn, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ibi àmúyangàn tí ipò rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè kò ní ṣeé fi ọwọ́ rọ́ s’ẹ́yìn.
28. ÌTỌ́JÚ ÀWỌN ỌMỌDÉ
Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), kò sí ẹni tí kò ní gbádùn àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí Olódùmarè fún màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdé.
Ètò ti wà nílẹ̀ lorísìírísìí fún ìgbá’yé gbádùn àwọn ọmọdé. Bí wọ́n bá ti ń gbà ìtọ́jú ni ẹ̀ka ti ìlera, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò máa gbádùn àwọn ohun am’áyédẹrùn ti ìgbàlódé lọ́kan-ò-jọ̀kan.
Kò sí òbí tí kò ní rí oúnjẹ tó dára fún àwọn ọmọ, nítorí oúnjẹ yóò wà lọ́pọ̀ yanturu ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Àwọn oúnjẹ tó dára, tí yóò mú ọpọlọ ọmọdé jí pépé ni wọn yóò máa jẹ.
Ní ìgbà dé ìgbà ni wọn yóò máa ṣe ayẹwo ni ilé ìwòsàn láti mọ bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí àti láti ríi dájú pé àìsàn kankan kò rí ààyè ní àgọ́ ara wọn.
Nítorí náà, a kí àwa ọmọ Aládé pé, a kú oríire, a sì kú ìmúrasílẹ̀ fún àjọyọ̀ Orílẹ̀ èdè wa tó tuntun jùlọ ní àgbáyé.
29. ÈTÒ Ẹ̀YÁWÓ FÚN ÀWỌN ONÍṢÒWÒ
Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó rántí wa sí rere, tó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn amúnisìn nípasẹ̀ màmá onínúure, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó rán sí wa.
Àyípadà ọ̀tun ti de bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa MOA lọ́wọ́.
Ètò Ẹ̀yáwó tí kò ní èlé lórí yóò wà fún èyíkéyìí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá tó bá fẹ́ ṣòwò, níwọ̀n ìgbà tí o bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P, o ní ẹ̀tọ́ sí ètò ẹ̀yáwó tí a ń sọ yí, tó bá ṣáà ti jẹ́ wí pé fún okòwò ni. Iye tí ẹnìkọ́ọ̀kan bá gbà ni yóò sì san padà láìsí èlé kankan.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wọn yí, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí oníkálukú wa máa ronú ohun tí a fẹ ṣe ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ Ìṣàkóso Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèje tó wà ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí, gbogbo ìgbà náà ni màmá wa MOA máa ń sọ wípé a ò ní rìn rárá, a máa fò ni, nítorí kò sí nǹkankan nílẹ̀ mọ́. Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn àwọn àlàkalẹ̀ ètò loríṣìíríṣìí tí Olódùmarè ní fún wa.
30. YORÙBÁ KÍKỌ SÍLẸ̀
Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), à ò ní sọ èdè ẹrú, èdè Yorùbá pọ́ńbélé ni a óò máa sọ bẹ́ẹ̀ sì ni kíkọsílẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ni àwọn àmì tó yẹ lórí tàbí nìdí álífábẹ́ẹ́tì kọ̀ọ̀kan èyí yóò mú kó rọrùn fún òǹkàwé láti pe ọ̀rọ̀ náà bí ó ti yẹ.
Ìdí ni pé, àwọn ọ̀rọ̀ kan wà nínú èdè Yorùbá tó jẹ́ pé bákan náà ni kíkọsílẹ̀ wọn ṣùgbọ́n ìtumọ̀ wọn yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ odó, odò. Odó ni ohun èlò nínú ilé tí a fi ń gún iyán. Omi tó ń ṣàn ni odò.
Ọkọ́, oko, ọkọ̀. Ọkọ́ ni ọkàn lára ohun èlò fún iṣẹ́ ọ̀gbìn, oko ni ibi tí àwọn àgbẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ láti rí oúnjẹ, ohun ìrìnnà ni ọkọ̀.
Tí a bá wo àwọn ọ̀rọ̀ yí, a óò ríi wípé bákan náà ni kíkọsílẹ̀ wọn ṣùgbọ́n àmì tí a fi sórí àti ìdí wọn ló gbé ìyàtọ̀ wọn jáde, ìdí nìyí tí a fi gbọdọ ri dájú pé a ò fi ojú pa àwọn àmì wọ̀nyí rẹ̀ nítorí ó ṣe pàtàkì púpọ̀ nínú èdè Yorùbá.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí láti dá ògo ìran Yorùbá tó ti sọnù padà, nítorí màmá wa MOA ti sọ fún wa pé àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè fún wọn yóò dá wa padà sí orírun wa ni. A kí gbogbo àwa ọmọ Aládé pé a kú oríire!
31. ÈTÒ Ẹ̀KỌ́
Ètò Ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì ní Orílẹ̀-Èdè. Ṣebí kò sí ohunkóhun tí a lè fẹ́ẹ́ ṣe, tí kò ní síí pé, yálà a fi kọ́ ni, gẹ́gẹ́bí ẹ̀bùn àti’nú wá, tàbí a tún fi kọ́’ni náà, ní ojú ayé mbí.
Ní ayé àtijọ́, ó ní bí àwọn babanlá baba wa ṣe máa nṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ tí ẹyẹ a sì máa ké bí ẹyẹ, eku a máa ké bí eku, ọmọ ènìyàn a sì máa fọ’hùn bí ọmọ ènìyàn – àwọn iṣẹ́ bíi àgbẹ̀dẹ, ààgbẹ̀, iṣẹ́ aṣọ híhun, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa, pẹ̀lú ẹ̀rí, bí àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe yí nkan wọ̀nyí padà mọ́ wa lọ́wọ́, tí wọ́n sì pinnu pé àwọn máa mú wa ju ti ọwọ́ wa dànù, kí á sì wá gba tiwọn, èyí tí kò dára tó tiwa!
Ohun àkọ́kọ́ tí ìyá wa, Màmá Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fi yé wa, nípa ètò ẹ̀kọ́, ni pé, èyí tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wa yẹn, tí ó sì jẹ́ pé òun ló dara jù, a máa padà sínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé ìrònú ti ẹ̀kọ́-òyìnbó wá sí ìṣètò ẹ̀kọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá o! Ẹ jọ̀wọ́, àrà ọ̀tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè ni ó mbọ̀ fún wa, ní kété tí Alákóso wa bá ti wọlé sí gbogbo oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Ṣùgbọ́n, ohun kan tí a mọ̀, ni pé, kò sí owó sísan fún akẹ́kọ ní gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ D.R.Y, láti ilé-ẹ̀kọ́ ti alákọbẹ̀rẹ̀, títí dé gbígboyè àkọ́kọ́ ní fásitì. Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ẹ̀kọ́-ìwádi, kọjá ipele gbígboyè àkọ́kọ́, pàápàá, ní ànfààní ẹ̀yáwó tí kò ni’ra láti san rárárá, níwọ̀n ìgbàtí ó bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, tí kì dẹ̀ nṣe pé bóyá ó ní ohun ibi kan tí ìdílé rẹ̀ ti ṣe sí Ìran Yorùbá, èyí ti wọ́n ti fi pàdánù ànfààní tí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá yẹ kí ó jẹ.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa pé gbogbo àwọn akẹ́kọ tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ni yíò ní gbogbo ìwé tí wọ́n ní’lò fún ẹ̀kọ́ wọn, tí á ti wà lórí ẹ̀rọ ayélujára ti alágbéká ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.
Màmá wa ti sọ fún wa, wọ́n ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí tí-n-tí tí ó fẹ́ f’ara jọ èyí tí a lè rí ní ibi míràn, ṣùgbọ́n ó fẹ́ f’ara jọ́ ni; ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun tí ó wà nínú àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé Màmà wa lọ́wọ́ fún ìran Yorùbá, àti pàáppàá ní ètò ẹ̀kọ́, kò sí irúfẹ́ rẹ̀ ní’bi kankan ní àgbáyé.
32. OÚNJẸ ÀSÌKÒ
Láti ìgbà tí Olódùmarè ti dá ìran Yorùbá ló ti fún wa ní oríṣiríṣi oúnjẹ tó jẹ́ wípé ilẹ̀ Yorùbá nìkan ni a ti leè rí irú rẹ̀. Àwọn oúnjẹ mìíràn wà tó jẹ́ pé,tí a bá sèé tán, à rí má leè lọ ni pẹ̀lú àwọn èròjà amáradán àti af’áralókun, ṣe oúnjẹ ni ọ̀rẹ́ àwọ̀.
Ní báyìí tí ìgbà ọ̀tun ti wá dé fún wa yìí, gbogbo àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ wa tí a ti patì ni a óò padà sí nítorí pé, gbogbo wọn ni yóò wà ní àrọ́wọ́tó, oúnjẹ àsìkò ni a óò máa jẹ́, ebi ò tún pa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) kankan mọ́.
Oúnjẹ tó dára lásìkò tí kìí ṣe oúnjẹ ayédèrú tàbi èyí tí wọ́n fi èròjà olóró sí pẹ̀lú owó tí ò gunpá,bẹ́ẹ̀ ni ewébẹ̀ lorísìírísìí náà kò ní gbẹ́yìn. Ìwọ̀n yí àti àwọn mìíràn ni a óò jẹ́ ìgbádùn rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Olódùmarè ló ṣe èyí fún wa nípasẹ̀ ìyá ìrọ̀rùn lóbádé, màmá wa, Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó rán sí ìran Yorùbá láti mú wa kúrò nínú ìnira, bọ́ sínú ìgbádùn àti ìfọ̀kànbalẹ̀.
33. IṢẸ́ ỌNÀ
Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ ọ̀rọ̀ kan fún wa, nípa bí a ṣè wà kí òyìnbó-amúnisìn ó tó dé. Wọ́n ní wọ́n bá wa nínú oríṣiríṣi ohun tí ọwọ́ nṣe, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, wọ́n rí ògiri tí ó jẹ́ ọgọ́run ibùsọ̀ máìlì (èyí tí ó jú ọgọ́run ibùsọ̀ kìlómítà lọ), tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú ògiri tí ó lékenkà jù ní àgbáyé. Iṣẹ́-ọnà ni eléyi.
Àwọn ilé tí àwọn baba wa nkọ́ ní ayé àtijọ́, jẹ́ ilé tí ó ní ọnà púpọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ère àjogún-bá wa, gẹ́gẹ́bí Orí-Olókún jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣì nwòye, títí di òní yí, pé irú ọgbọ́n wo ni àwọn baba wá lò, tí wọ́n le dá oríṣiríṣi nkan wọ̀nyí ṣe!
Títí dí òní, àwọn iṣẹ́ kan wà tí ó jẹ́ pé ọ̀nà àrà tí Ẹlẹ́da ngbà láti tipasẹ̀ ọmọ Yorùbá ṣe nkan wọ̀nyí, jẹ́ ìyàlẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣé ti iyùn ni kí á sọ ni, tàbí oríṣiríṣi ọnà-àrà tí ọmọ Yorùbá ndá sí aṣọ-òkè. Tàbí ọnà ti irun-dídì ni ká sọ; bó ti lẹ̀ jẹ́ bí a ṣe ngbálẹ̀ pàápàá. Obìnrin Yorùbá á gbá àyíká àti agbègbè rẹ̀, lórí ilẹ̀ eruku, á sì ya ọnà si!
Ṣé bí a ṣe nwọ àwọn aṣọ wa ni, àtọkùnrin àtobìrin wa ni a ní oríṣiríṣi ọnà tí a nṣe pẹ̀lú aṣọ tí a bá wọ̀.
Ànfààní iṣẹ́ ọnà-ṣíṣe wà lára ànfààní tí a máa máa rí ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
Nísiìyí tí a ti padà sí Orísun wa, Èdè wa àti àṣà wa, oríṣiríṣi ìmísí láti inú wá ni Ọmọ Yorùbá yíò máa ní, èyí tí iṣẹ́-ọnà àti ìṣe-ọnà yíò fi gbòòrò si ní àwùjọ orílẹ̀-èdè Yorùbá.
34. ÌMỌ́TÓTÓ AGBÈGBÈ
Láìsí ìmọ́tótó agbègbè àti àyíká wa, nílé, lóko, lọ́nà ìrìn-àjò, kò sí bí a ṣe máa káwọ́ àrùn tàbí àìsàn.
Èyí ló fi dá’ni lójú pé, orílẹ̀-èdè D.R.Y kò ní fi àyè gba ẹnikẹ́ni láti hu ìwà ọ̀bùn tàbí aláìbìkítà fún agbègbè àti àyíká wa ní orílẹ̀-èdè wa yí.
Ìṣàkóso Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y ní ètò tí ó jẹ́ pé ìdọ̀tí, bí ó ti wù kó kéré mọ, kò ní rí ibi fi ṣe ibùjóko ni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).
Ẹ jẹ́ kí ìdọ̀tí jìnà sí wà, kí ó sì jìnà sí gbogbo àwùjọ wa káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. Orílẹ̀-Èdè D.R.Y kò fi àyè sílẹ̀ fún ìdọ̀tí kankan – fún ààbò ara wa ni.
Yàtọ̀ sí èyí, àyíká tí ó dùn-ún-wò, tí ó sì mọ́ tónítóní, máa njẹ́ ìwúrí fún èèyàn láti ro èrò rere fún ìgbélékè ara wa àti ti orílẹ̀-èdè wa. Ìmọ̀tótó borí àrùn.
35. YORÙBÁ SÍSỌ
Títí láé ni àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó rán ẹni bí ọkàn Rẹ̀ sí wa, màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gbà wa lọ́wọ́ amúnisìn àti láti dá wa padà sí orírun wa.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń ṣọ wípé, ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), èdè Yorùbá ni a óò máa sọ ní ilé iṣẹ́, ilé ẹ̀kọ́ àti gbogbo ibi ní ilẹ̀ Yorùbá.
Èyí yóò mú ẹwà èdè Yorùbá búyọ nítorí pé kò ní sí àmúlùmúlà rárá, bí a bá ṣe ń sọ̀rọ̀ ní èdè Yorùbá pẹ̀lú òwe àti àkànlò èdè, èyí yóò mú kí gbólóhùn náà lóòrìn kó sì ní ìtumọ̀ kíkún.
Láti kékeré ni a óò tí máa kọ àwọn ọmọ wa ní èdè Yorùbá, yàtọ̀ sí òfegè Yorùbá tí a ń sọ láyé òde òní. Èdè Yorùbá ni a óò fi máa kọ́ wọn ní ilé ìwé, yóò sì jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà yé wọn dáadáa.
Nítorí náà, a rọ gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) láti fi ọwọ́ so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kí ẹwà àti ògo tí Olódùmarè fún ìran Yorùbá leè búyọ.
36. IPÒ YÍYÀN
Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), gẹ́gẹ́ bí a ti mọ́ wípé lórí òtítọ́ àti òdodo ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé, nítorí náà, kò ní sí ojúsàájú nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe, pàápàá ní àkókò yíyan adarí tàbí aṣojú, yálà ní ilé iṣẹ́ tàbí nínú ètò ìsèjọba.
Àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) nìkan ni yóò máa wà ní ipò asíwájú ní orílẹ̀ èdè wa. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ wípé, lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.
Fún ìdí èyí, aò ní gba àjòjì kankan láàyè láti wà ní ipò adarí, aṣojú tàbí aṣíwájú ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí àyè fún àgàbàgebè, gbígba owó ẹ̀yìn tàbí ojúsàájú nínú ètò ipò yíyan, ẹni tí ipò náà bá tọ́ sì tó sì ní àtìlẹ́yìn àwọn ará ìlú jùlọ ni yóò jáwé olúborí, nítorí pé bákannáà ni gbogbo wa, àparò kan kò ní ga jù’kan lọ ní ilẹ̀ Yorùbá.
37. ÒMÌNIRA TÍTÍ AYÉ
Ní gbogbo ìgbà ni àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa fún oore ńlá tó ṣe fún wa, fún òmìnira àìlópin èyí tó ti ọwọ́ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe fún àwa ọmọ Aládé.
Bẹ̀rẹ̀ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a kéde òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ni ìran Yorùbá ti kúrò nínú àjàgà àwọn amúnisìn.
Kò sí ohun tí a leè fi òmìnira wé, nítorí ìdàkejì òmìnira náà ni ìgbèkùn. Bí ẹ̀dá bá sì wà nínú ìgbèkùn kò sì ohun tó lè dá ṣe fúnra rẹ̀. Kò ní leè dá’nú rò, kò ní leè ṣe bó ti fẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí ìdàgbàsókè kankan fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.
Irú ipò yí ni ìran Yorùbá wà fún àìmọye ọdún kí Olódùmarè tó tú wa sílẹ̀ nípasẹ̀ màmá wa MOA, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì máa ń sọ fún wa wípé, títí láé ni oore tí Olódùmarè ṣe yí, nítorí pé àlàkalẹ̀ ètò ìmójútó ará ìlú tí Olódùmarè gbé fún wọn, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fi kún-un tàbí yọ kúrò níbẹ̀. Bí yóò ṣe wà nìyí títí òpin ayé.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa nígbà gbogbo, gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe sọ láìpẹ́ yí wípé lójoojúmọ́ ni kí a máa fi ọkàn ìmoore wa hàn sí Ọlọ́run fún oore ńlá tó ṣe fún wa.
Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti di orílẹ̀ èdè Olómìnira títí láé, kò sí ẹnikẹ́ni tó leè yí padà.
38. ÌMÓJÚTÓ ARÁ-ÌLÚ
Ìṣètò Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) wà fún ìmójútó ará-ìlú. Èyí ni pé kò sí ìjìyà mọ́ fún ọmọ Yorùbá. Orílẹ̀-Èdè wa yíò mójútó gbogbo ohun tí a máa fi ní ìgbáyé-gbádùn, a ò sì ní máa sun ẹkún àìríjẹ, àìrímu, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́bí Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, lọ́wọ́, òun ni ó jẹ orílẹ̀-èdè D.R.Y lógún! Ìmójútó ìrọ̀rùn-ará-ìlú jẹ́ Gbòógì Ànfààní orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Nítorí èyí, láti àárọ̀-ṣú’lẹ̀, àṣáálẹ́ mọ́’jú òwúrọ̀, ní ìgbà-gbogbo, àti wákàtí gbogbo, ọmọ Yorùbá, Ìran Yorùbá àti Ilẹ̀ Yorùbá ti bọ́ sí Ìgbáyé-Gbádùn, nítorí ojúṣe Orílẹ̀-Èdè D.R.Y ni Mímójú-tó Ìṣe-rere, Ìrọ̀rùn, Àláfíà, Ààbo ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá ní orí-ilẹ̀ àwọn babanlá wa – tí eku yíò máa ké bí eku, ẹyẹ yíò máa ké bí ẹyẹ, ọmọ ènìyàn yíò máa fọ’hùn bí ọmọ-ènìyàn; aboyún yíò máa bí wẹ́rẹ́; ògo Olódùmarè yíò tàn-‘mọ́lẹ̀ káakiri Ilẹ̀-Àjogúnbá Yorùbá, ọkàn wa yíò sì balẹ̀; ẹnikẹ́ni kò níí leè dẹ́rùba Ọmọ Yorùbá, lórí ilẹ̀ Baba wa, tí a ó sì máa yọ̀, a óò sì máa dun’nú, gẹ́gẹ́bí Ìyá wa, MOA, Ìránṣẹ́-Olódùmarè ṣe máa nsọ, pé, kí a máṣe gbàgbé o, ohun rere Ńlá Ńlá tí Ọlọ́run Olódùmarè ti ṣe fún’wa yí, kí á sì máa yìn títí ayé, nítorí ìṣètò D.R.Y, ìṣètò tí ó nmójútó ìṣe-rere ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá ni.
39. OÚNJẸ TÓ DÁRA
Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ìgbádùn tí yóò wà fún wa kò lóǹkà, àìríjẹ ti di ohun ìgbàgbé ní ilẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ tó dára ní a óò máa jẹ́, nítorí pé Alákóso D.R.Y kò ní fàyè gba ayédèrú oúnjẹ GMO tàbí lílo èròjà tó leè ṣe àkóbá fún àgọ́ ara nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn.
Gbogbo àwọn ẹnu ibodè wa ni wọ́n yóò ti máa ṣe àyẹ̀wò fínnífínní lórí ohunkóhun tí wọ́n bá ń kó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa èyí ni láti ríi dájú pé wọn ò kò oúnjẹ tó leè ṣe ìpalára wá fún wa.
Ètò ìrànwọ́ yóò wà fún àwọn àgbẹ̀ láti leè máa pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, nítorí pé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni Olódùmarè fún wa, aò nílò láti bá orílẹ̀ èdè kankan d’òwòpọ̀ kí a tó leè jẹun, gẹ́gẹ́ bí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àwa ni yóò máa pèsè ohun tí a nílò, ohun tí a bá sì ń pèsè náà ni a óò máa lò.
40. ÈTÒ FÚN ÀWỌN ARÚGBÓ
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àánú rẹ̀ lórí ayé ìran Yorùbá, Tó dá ìgbà ọ̀tun padà fún àwa ọmọ Aládé nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla Tó fi iṣẹ́ náà rán sí àwa ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ètò tó fi ti Yorùbá ṣe àkọ́kọ́ lẹ́yìn Olódùmarè tó sì kún fún ìgbá’yé gbá’dùn lorísìírísìí.
Ṣé láìpẹ́ yí tí màmá wa MOA bá àwa ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀ ni wọ́n tún sọ fún wa wípé, ètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti wà nílẹ̀ fún àwọn arúgbó wa bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin, ṣùgbọ́n fún ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) nìkan ni ò.
Kí gbogbo ẹ̀yin arúgbó wa máa jẹ ìgbádùn lọ lókù, kò sí ogun àìríjẹ mọ́ fún àwọn arúgbó wa, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò máa gba ìtọ́jú tó péyé ní ẹ̀ka ti ètò ìlera lọ́fẹ̀ẹ́.
Níwọ̀n ìgbà tí o bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí o sì ti pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin a kí wa kú oríire. Ṣé a ò gbàgbé wípé, kò sí ojú ṣáájú ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ìlú tí oníkálukú bá wà ní yóò ti máa gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nítorí pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa.
Ẹ ò nílò láti mọ ẹnikẹ́ni kí ẹ̀tọ́ yín tó tẹ̀ yín lọ́wọ́.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú wa, kí a sì ríi dájú pé a ò ṣe ohunkóhun tó lòdì sí òfin Orílẹ̀ èdè D.R.Y kí a má bàa pàdánù àwọn ẹ̀tọ́ tí a ní gẹ́gẹ́ bíi ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), kí a sì máa ṣe òtítọ́ nínú ohun gbogbo nítorí pé òtítọ́ níí gbé orílẹ̀ èdè lékè.
41. ÌGBÁDÙN ỌRỌ̀ LỌ́PỌ̀LỌPỌ̀
Olódùmarè fi ọrọ̀ rẹpẹtẹ dá ilẹ̀ Yorùbá lọ́lá, Ó fún wa ní ilẹ̀ ọlọ́ràá tó nṣe àtìlẹyìn fún oríṣìíríṣìí ohùn ọ̀gbīn láti so dáradára àti lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ìgbà ojo, ẹ̀rùn, ooru, òtútù ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀, nítorínáà, a ó ní ànító oúnjẹ àti àjẹṣẹ́kù. Ní àfikùn, Olódùmarè fún wa ní àwọn ènìyàn tó pọ̀, tó sì ní agbára àti ọgbọ̀n pẹ̀lù akínkanjú láti ṣiṣẹ́ di ọlọ́rọ̀.
Yàtọ̀ sí gbogbo èyí, àwọn ohun àlùmọ́nì àmúṣọrọ̀ oríṣiríṣi bí i wúrà, fàdákà, epo rọ̀bì àti àwọn òkúta iyebíye lóríṣiríṣi ni Ọlọ́run fi sí abẹ̀ ilẹ̀ wa. A tún ní omi òkun àti ọ̀sà pẹ̀lú àwọn odò nlánlá àti kékèké tí ó kún fún ohun àlùmọ́nì pẹ̀lú nkan abẹ̀mí lóríṣiríṣi, àwọn igbó kìjikìji ti ó kún fún àwọn igi àti ẹranko igbó lọ́pọ̀lọpọ̀ tí yíó mú owó wọlé nípa ohun àmúṣọrọ̀, ìrìn àjò afẹ́ pẹ̀lú àwọn ewé àti egbò fún iṣẹ́ ìtọjú aláìsàn pẹ̀lú ìwòsàn fún ọ̀pọ̀ àìsàn àti àrùn.
Àwọn ẹ̀bùn àdámọ́ Ọlọ́run Olódùmarè wọ̀nyi fún àwa ọmọ Aládé mú kí ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ láti ìgbà ìwáṣẹ̀.
Àwọn ẹ̀bùn, iṣẹ́ ọwọ́, tálẹ́ntì àti ọgbọ́n àtinúdá tí Olódùmarè fún oníkálukú láti lò fún ìṣe rere, ni Àwọn Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹni náà láti tayọ nípa ètò ẹ̀yáwó láì sí èlé lórí rẹ̀, láti dá iṣẹ́ sílẹ̀, yálà ilé iṣẹ́ nlá tàbí ní kéréje-kéréje. Àwọn Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ara-Ìlú Democratic Republic of the Yoruba yíó tún ṣe ìrànlọ́wọ́ nípa ìpèsè àmójútó, ètò ọrọ̀ ajé tó dára àti ààbò tó dájú ní orílẹ̀ èdè wa.
Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá fi yé wa pé àrà ọtọ ni ètò ẹ̀kọ́ wa yíó jẹ́, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gboyè á lè dáwọ́ lé iṣẹ́ ti wọn kà’wé fún tàbí láti fi dá iṣé sílẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Àwọn Aṣojú Ètò Ìmòjútó Ará-Ìlú D.R.Y. Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ìkàwé gboyé àkọ́kọ́ ní Fásitì. Gbogbo ẹnití ó bá sì yan iṣẹ́ oṣù láàyò, owó oṣù tó dára ní yíó máa gbà, ẹ̀ẹ̀méjì ní wọn á ma gba owó lóṣù.
Àwọn ètò àlàkalẹ fún ìdàgbàsókè yii kò lè jẹ́ ohun ìnira fún orílẹ̀ èdè wa nítorí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí Ọlọ́run fí ta wá lọ́rẹ, àti pé a ò ní kó owó àti ọrọ̀ wa lọ sí ibòmíràn, Aó ma lò fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè wa ati ìtọ́jú ará ìlú. Gbogbo àwọn ohun rere wọ́nyí kò ní jẹ́ kí ìṣẹ́ àti òṣì rí àyè nínú ayé I.Y.P kankan.
42. D.R.Y KÒ NÍ TỌRỌ
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè tí Olódùmarè kẹ́ pẹ̀lú àlùmọ́ọ́nì lorísìírísìí ní àgbáyé, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) jẹ́ ọ̀kan gbòógì. Bí a ṣe ní àlùmọ́ọ́nì ti ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn omi lorísìírísìí tó leè máa mú owó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa.
Ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Olódùmarè fi kẹ́wa ńkọ́? Kò sí ohun tí a gbìn sínú rẹ̀ tí kò ní mú èso jáde. Iṣẹ́ ọ̀gbìn nìkan tó fún orílẹ̀ èdè D.R.Y láti sọ wá di ọlọ́rọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe sọ láìpẹ́ yí wípé, Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) yóò máa wín ni, aò ní tọrọ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni yóò máa wá wo àwòkọ́ọ̀ṣe wa. Gbogbo àwọn ibùdó àwòyanu tí Olódùmarè dá sí ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí irú rẹ̀ ní ibikíbi lórí ilẹ̀ ayé yìí, gbogbo wọn ni Alákóso D.R.Y yóò mójú tó tí yóò sì di orísun ìbùkún àgbọ́n-ọ̀n-gbẹ fún orílẹ̀ èdè wa.
Gẹ́gẹ́ bí ìran Yorùbá tún ṣe jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, a óò lo ọpọlọ tí Olódùmarè fún wa, àwọn àlùmọ́ọ́nì àti ohun rere gbogbo tí a ní láti ríi dájú pé orílẹ̀ èdè D.R.Y kò tún tòṣì mọ́.
43. KÒ SÍ ÀYÈ FÚN AMÚNISÌN MỌ́
Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti dúró, yálà ọ̀tá fẹ́ tàbí wọ́n kọ̀.
Ó ti pẹ́ tí ìran Yorùbá ti ń j’ìyà lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, ṣé ti àwọn ọba ni ká sọ ni, àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní olóṣèlú tàbí àwọn amúnisìn láti ìta. Ẹni gb’épo lájà kò jalè bí kò ṣe ẹni tó gbàá sílẹ̀.
Ṣèbí àwọn amúnisìn tí inú ilé tí wọ́n pe’ra wọn ní ọba, aṣíwájú tàbí olóṣèlú ilẹ̀ Yorùbá gan-an ni wọ́n ń gbàbọ̀dè fún ìran Yorùbá. Àwọn amúnisìn ló ń yan ẹni tí wọ́n fẹ́ sípò. Wọn ò tẹ̀lé ìlànà tí àwọn babańlá wa ń gbà yan ọba mọ́.
Ẹnikẹ́ni tó bá ní àníyàn láti gba àwọn ènìyàn kúrò nínú òṣì, wọ́n á ní kí wọ́n lọ gba ẹ̀mí rẹ̀ lójijì. Ọmọ Aládé wá di ẹni tó ń ṣe ẹrú ní ilẹ̀ àjèjì nítorí àti rí ọwọ́ mú lọ s’ẹ́nu.
Wọ́n sọ àwọn ọmọ ológo di ìdàkudà, ìwà ọmọlúwàbí wá s’ọ̀wọ́n ní àwùjọ ọmọ Yorùbá. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó gbà wá lọ́wọ́ àwọn amúnisìn wọ̀nyí nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó fi iṣẹ́ ìtúsílẹ̀ ìran Yorùbá rán.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ẹ má jẹ̀ẹ́ kí a gba ẹnikẹ́ni tó lè dúró gẹ́gẹ́ bíi amúnisìn láàyè láàárín wa, lẹ́yìn tí a ti ṣe ìkéde òmìnira wa ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún. Tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ń gbé ìgbésẹ̀ tó leè ṣe àkóbá fún ìran Yorùbá, ẹ má ṣe dágunlá sí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ fi tó Alákóso (Adelé) orìlẹ̀ èdè Yorùbá létí lórí:
Gbogbo ìwà ìmúnisìn ti parun ní ilẹ̀ Yorùbá,àwa ọmọ Aládé sì ti wọ inú ògo wa lọ.
44. Ẹ̀KỌ́ TÓ YÀTỌ̀ SÍ TI ẸRÚ
Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá máa ń bá wa sọ, wọ́n ti fi yé wa pé gbogbo ńkan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọ́ ní ẹ̀kọ́ ti òyìnbó, tí wọ́n sì ń tìtorí èyí pe’ra wọn ní ‘elite,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí a bá ko jọ, kò kúkú ju ìdajì ojú-ewé kan ní kíkọ̀-sílẹ̀ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá máa ń rán wa létí, láti ìgbà dé ìgbà, ohun tí òyìnbó-amúnisìn, Lord Macaulay sọ, ní òjì-lé-lẹ́gbẹ̀sán-ọdún, ó dín márun, nígbàtí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ètò-ẹ̀kọ́ ti aláwọ̀dúdú, èyí tí a sì mọ̀ pé ti Yorùbá jẹ́ gbòógì, jẹ́ èyí tí ó rinlẹ̀ ju ti àwọn òyìnbó lọ, ṣùgbọ́n tí ọkùnrin náà sọ pé kí àwọn ó tàn wá jẹ, kí a máa rí ti àwọn t’òyìnbó pé òun ló dára ju ti’wa lọ; èyí túmọ̀ sí pé ẹ̀kọ́ tiwa dára ju tiwọn lọ, ẹ̀tàn ni pé ti òyìnbó ló dára jù.
Nígbàtí a ti wá mọ eléyi, tí Màmá wa, ẹni tí Ọlọ́run sì fi iṣẹ́ ìràpadà ìran Yorùbá rán, tún ti wá sọ fún wa pé, Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, láti máa lò, títí ayé, jẹ́ èyí tí yóò dá wa padà sí ìṣẹ̀dálẹ̀ wa; èyí wá túmọ̀ sí pé, ètò-ẹ̀kọ́ wa ní ilẹ̀ Yorùbá kò ní jẹ́ ti ẹrú – ìyẹn ni pé, kò ní dá lórí ètò tí àwọn òyìnbó-amúnisìn gbé lé wa lọ́wọ́, ṣùgbọ́n á jẹ́ ohun tí ó tún rinlẹ̀ ju ti àwọn òyìnbó lọ.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa ńsọ, wọ́n ní àrà-ọ̀tọ̀ ni; pé bí a tilẹ̀ rí àwọn ẹyọ nkan kọ̀ọ̀kan nínú nkan tiwa tó fẹ́ f’ara jọ ti àwọn míràn, ó kàn f’ara jọ́ náà ni!
A ò ní kọ́ ẹ̀kọ́ tó ńfi yé wa bí wọ́n ṣe nka ìwé nìkan, a gbọ́dọ̀ lè fi ṣe ohun pàtàkì tí á mú orílẹ̀ èdè wa dàgbàsókè.
Ẹnikẹ́ni kò ní da orí wa sí ọ̀nà àìtọ́; a máa fi làákàyè kọ́ ẹ̀kọ́, kìí ṣe kí á kàn máa ka nkan tí kò yé wa, kí á tún máa dàá sílẹ̀ l’at’ẹnu wa gẹ́gẹ́bí ẹyẹ ayékòótọ́, láì mọ ohun tí a ńsọ lẹ́nu.
Ẹ̀kọ́ tí kò ní ìtànjẹ ni ẹ̀kọ́ tí a máa ní: àwọn ọmọ wa á lè ronú dára-dára, kìí ṣe àgbérù-gbésọ̀ tí kò mú ìlọsíwájú bá’ni.
Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè fún ẹ̀kọ́ tí ó ńfi ẹ̀mí àti ìrònú-ẹrú sí’ni lórí. Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni Àkọ́kọ́; èyí sì máa f’ara hàn nínú gbogbo ètò ẹ̀kọ́ wa.